Nígbà tí wọ́n yan Qatar gẹ́gẹ́ bíi orílẹ̀èdè tí yóò gbàlejò ìdíjé ife ẹ̀yẹ àgbáyé, àwọn ọ̀rọ̀ kan jẹyọ nípa ìtàn ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn orílẹ-èdè náà àti àwọn ìdojúkọ nípa bí àwọn agbábọ́ọ̀lù àti àwọn tó ń wo ìran yóò ṣe ṣe oru ìorílẹ̀èdè náà tó máa ń kọjá 40C.
Ọ̀nà-àbáyọ kan ni kí wọ́n sún ìdíje náà sí ìgbà òtútù. Ṣùgbọ́n orílẹ-èdè aṣálẹ̀ ọ̀hún tó ní owó lọ́wọ́ ṣe àdéhùn pé òun yóò fi ìtàn ohun tí kò ṣẹlẹ̀ rí lélẹ̀: ìmọ̀ ẹ̀rọ tuntun tó lè jẹ́ kí ó ṣeéṣe láti gbàlejò ìdíje ńlá nígbà gbogbo, kódà kọ́ jẹ́ ní àwọn orílẹ̀-èdè tó gbóná jù. Hajar Saleh tó ń gbá bọ́ọ̀lù ní Qatar so pé bí ojú ọjọ́ ṣe gbóná àti ọ̀gìnìǹtìn sọ eré bọ́ọ̀lù di ohun tó ní ìdojúkọ ńlá.
Nítorí náà, báwo ni wọn yóò sọ ayẹ́ dẹ̀rùn fún àwọn agbábọ́ọ̀lù àti àwọn tó wá wò wọ́n láì ná ilé ayé ní nǹkan?
Tẹ̀ẹ́ lọ ilẹ̀ kí o tẹ̀lé afẹ́fẹ́ bó ṣe ń fẹ́ káàkiri pápá ìṣeré Al Janoub, ọ̀kan lára pápá ìṣeré mẹ́jọ tí wọn yóò lò ní Qatar 2022.
Qatar jẹ́ ìlú tó gbóná tó ní ọ̀gìnìǹtìn. Atẹ́gun gbigbóná ń fẹ́ káàkiri orílẹ̀-èdè kékeré náà.
Ìdójǔkọ àkọ́kọ́ ni láti sé atẹ́gùn gbígbóná ọ̀hún mọ́ ìta. Ní pápá ìṣeré Al Janouon, wọ́n ṣe òkè rẹ̀ bí yóò ṣe máa darí afẹ́fẹ́ sí òkè ọ̀nà ọ̀hún. Àwọ̀ iná rẹ̀ ń darí oru láti Òòrùn.
Sísọ oríi pápá àti ibùdó èrò tó wò'ran di tútù nílò àwọn ọ̀nà-àbáyọ tuntun. Ẹ jẹ́ ka wo inú rẹ̀.
Lọ́jọ́ ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ èrò ẹgbẹ̀rún lọ́nà ogójì (40,000) ni yóò wà ní ibùdó èrò tó ń wò'ran tí oru àti omi yóò máa jáde lára wọn.
Oru tó ń mú ní Qatar àti oru tó ń jáde níbi ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ yóò níló ètò amú-àyíká-tutù tó péye.
Atẹ́gùn tútù yóò máa fẹ́ sí àwọn èrò tó nífẹ̀ẹ́ eré bọ́ọ̀lù láti abẹ́ ìjókòó wọn ní ibùdó èrò.
Àwọn nọ́zù kéékèèké tó ń ṣe bíi ẹnu omi iléèwẹ̀ ìgbàlódé yóò jẹ́ kí afẹ́fẹ́ bo àwọn èrò tó ń wò'ran.
Afẹ́fẹ́ ọ̀hún yóò máa fẹ́ lẹ́sọ̀ ni yàtọ̀ sí fífẹ́ lójú kan náà gẹ́gẹ́ bíi ọyẹ́ inú bàálù.
Èyí yóò ṣe àwọn èrò lóore, ṣùgbọ́n àwọn agbábọ́ọ̀lù tó wà lóríi pápá ńkọ́?
Àwọn agbábọ́ọ̀lù ìgbàlódé lè sáré tó ju kilómità mẹ́wàá lọ nínú ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ kan ti wọn yóò sì láàgùn tó tó lítà mẹ́ta nítorí náà wọn nílò láti mú ara tutù àti láti ní omi nínú ara.
Nínú àyíká Qatar tó ní ọ̀gìnìǹtìn yóò nira fun oógùn láti gbẹ, ara sì lè gbònà jù èyí tó lè mú kí ó oru jẹ́ kó rẹ ènìyàn.
Fún ìdíje ife ẹ̀yẹ bọ́ọ̀lù àgbáyé Qatar wọn yóò máa gbé afẹ́fẹ́ tó tutù wọ inúu pápá ìṣeré lọ́nà nọ́zù ńlá nítorí kí orí pápá lè tutù.
Onímọ̀ nípa ẹ̀rọ ọlọ́yẹ́ tó ṣe ètò ọ̀hún, Ọ̀mọ̀wé Said Abdul Ghani, sọ pé ọ̀nà tí àwọn ihò afẹ́fẹ́ ń bá jade kọjú sí àti ibi tí afẹ́fẹ́ tútù náà ń wọlẹ̀ sí kò ní jẹ́ kí àwọn agbábọ́ọ̀lù gbọ́ pé atẹ́gùn ń fẹ́.
Èyí yóò ṣe òkùnfà afẹ́fẹ́ tó tutù níwọ̀nba nínú pápá ìṣeré, tí kò ní ga ju mítà méjì lọ láti ilẹ̀ àbí ibùdó èrò,yàtọ̀ sí kí wọ́n fẹ́ ọyẹ́ sí òkè aṣálẹ̀. Kí ló wá máa wá sẹlẹ̀ lẹ́yìn náà?
Bí afẹ́fẹ́ tútù ọ̀hún bá ṣe ń gbóná, ni àwọn fáánù kan yóò máa fàá jáde.
Lẹ́yìn náà ni wọn yóò ṣẹ́ afẹ́fẹ́ náà tí wọ́n yóò sì tún sọọ́ di tútù tí wọ́n yóò sì dáa padà sí inú pápá ìṣeré.
Báwo ni wọ́n ṣe ń sọ afẹ́fẹ́ náà di tútù kí ará lè dẹ àwọn èèyàn nínú pápá ìṣeré náà. Ẹ jẹ́ ká fi ojú sùnùkùn wòó.
Ọ̀nà tí wọ́n ń gbà láti sọ afẹ́fẹ́ gbígbóná náà di tútú ni gbígbé afẹ́fẹ́ ọ̀hún gba inú páìpù tó ní omi tútù ní gbogbo igun pápá ìṣeré ọ̀hún.
Tí omi tútù náà bá ti fa oru, wọn yóò tarí rẹ̀ sínú táńkì kan tó lè gba lítà ẹgbẹ̀rún lọ́nà ogójì (40,000). Ibi tí tánkì ọ̀hún wà jìnà tó kìlómità mẹ́ta. Ibẹ̀ ni wọ́n yóò ti tún sọọ́ di tútù fún ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ ọjọ́ kejì.
Ohun tó ń fún ètò amú-àyíká-tutù ọ̀ún ní iná ni ẹ̀rọ iná Òòrùn (solar plant) kan tó tó ọgọ́rin (80) kilómità sí olú ìlú Qatar, Doha.
Sísọ oríi pápá àti ibùdó èrò tó wò'ran di tútù nílò àwọn ọ̀nà-àbáyọ tuntun. Ẹ jẹ́ ka wo inú rẹ̀.
Lọ́jọ́ ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ èrò ẹgbẹ̀rún lọ́nà ogójì (40,000) ni yóò wà ní ibùdó èrò tó ń wò'ran tí oru àti omi yóò máa jáde lára wọn.
Oru tó ń mú ní Qatar àti oru tó ń jáde níbi ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ yóò níló ètò amú-àyíká-tutù tó péye.
Atẹ́gùn tútù yóò máa fẹ́ sí àwọn èrò tó nífẹ̀ẹ́ eré bọ́ọ̀lù láti abẹ́ ìjókòó wọn ní ibùdó èrò.
Àwọn nọ́zù kéékèèké tó ń ṣe bíi ẹnu omi iléèwẹ̀ ìgbàlódé yóò jẹ́ kí afẹ́fẹ́ bo àwọn èrò tó ń wò'ran.
Afẹ́fẹ́ ọ̀hún yóò máa fẹ́ lẹ́sọ̀ ni yàtọ̀ sí fífẹ́ lójú kan náà gẹ́gẹ́ bíi ọyẹ́ inú bàálù.
Èyí yóò ṣe àwọn èrò lóore, ṣùgbọ́n àwọn agbábọ́ọ̀lù tó wà lóríi pápá ńkọ́?
Àwọn agbábọ́ọ̀lù ìgbàlódé lè sáré tó ju kilómità mẹ́wàá lọ nínú ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ kan ti wọn yóò sì láàgùn tó tó lítà mẹ́ta nítorí náà wọn nílò láti mú ara tutù àti láti ní omi nínú ara.
Nínú àyíká Qatar tó ní ọ̀gìnìǹtìn yóò nira fun oógùn láti gbẹ, ara sì lè gbònà jù èyí tó lè mú kí ó oru jẹ́ kó rẹ ènìyàn.
Fún ìdíje ife ẹ̀yẹ bọ́ọ̀lù àgbáyé Qatar wọn yóò máa gbé afẹ́fẹ́ tó tutù wọ inúu pápá ìṣeré lọ́nà nọ́zù ńlá nítorí kí orí pápá lè tutù.
Onímọ̀ nípa ẹ̀rọ ọlọ́yẹ́ tó ṣe ètò ọ̀hún, Ọ̀mọ̀wé Said Abdul Ghani, sọ pé ọ̀nà tí àwọn ihò afẹ́fẹ́ ń bá jade kọjú sí àti ibi tí afẹ́fẹ́ tútù náà ń wọlẹ̀ sí kò ní jẹ́ kí àwọn agbábọ́ọ̀lù gbọ́ pé atẹ́gùn ń fẹ́.
Èyí yóò ṣe òkùnfà afẹ́fẹ́ tó tutù níwọ̀nba nínú pápá ìṣeré, tí kò ní ga ju mítà méjì lọ láti ilẹ̀ àbí ibùdó èrò,yàtọ̀ sí kí wọ́n fẹ́ ọyẹ́ sí òkè aṣálẹ̀. Kí ló wá máa wá sẹlẹ̀ lẹ́yìn náà?
Bí afẹ́fẹ́ tútù ọ̀hún bá ṣe ń gbóná, ni àwọn fáánù kan yóò máa fàá jáde.
Lẹ́yìn náà ni wọn yóò ṣẹ́ afẹ́fẹ́ náà tí wọ́n yóò sì tún sọọ́ di tútù tí wọ́n yóò sì dáa padà sí inú pápá ìṣeré.
Tí omi tútù náà bá ti fa oru, wọn yóò tarí rẹ̀ sínú táńkì kan tó lè gba lítà ẹgbẹ̀rún lọ́nà ogójì (40,000). Ibi tí tánkì ọ̀hún wà jìnà tó kìlómità mẹ́ta. Ibẹ̀ ni wọ́n yóò ti tún sọọ́ di tútù fún ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ ọjọ́ kejì.
Ohun tó ń fún ètò amú-àyíká-tutù ọ̀ún ní iná ni ẹ̀rọ iná Òòrùn (solar plant) kan tó tó ọgọ́rin (80) kilómità sí olú ìlú Qatar, Doha.
Dr Cool
Ọkùnrin tó ṣe ètò ọ̀hún, Dr Saud Abdul Ghani, sọ fún BBC pé Qatar fẹ́ ṣe ohun mánigbàgbé tí yóò máa ṣe àǹfàání fún orílẹ̀èdè náà lẹ́yìn tí àwọn agbábọ́ọ̀lù bá lọ sí ilé tán.
Èrò agbábọ́ọ̀lù
BBC kàn sí Hajar Saleh, tó ń gbá ẹ̀yìn fún ikọ̀ agbábọ́ọ̀lù obìnrin orílẹ̀èdè Qatar tó sì ti ń gbá bọ́ọ̀lù láti ìgbà tó ti di ọmọ ọdún mọ́kànlá (11). Ó mọ̀ nípa ìdojúkọ tó wà nínú gbígbá bọ́ọ̀lù ní àyíká tó le. Ó sọ pé ọ̀gìnìǹtìn ni ìdọjúkọ tó lágbára jù.
Oru ti mọ́ wa lára, ṣùgbọ́n tí o bá da oru pọ̀ mọ́ ọ̀gìnìǹtìn, nǹkan yóò ṣòro síi.Hajar Saleh
Hajar ti ní ìrírí gbígbá bọ́ọ̀lù nínúu méjì lára àwọn pápá ìṣeré tuntun ọ̀hún tó ní ètò amú-àyíká-tutù, pápá iṣeré Khalifa àti pápá ìṣeré Educationa City.
Ó ní ìyàtọ̀ tó wà níbẹ̀ pọ̀, pàá-pàá tí èèyàn bá ń gbá bọ́ọ̀lù nínú oṣù kẹfà, ọ̀kan lára àwọn oṣù tó gbóná jù ní Qatar.
Ṣé ètò ọ̀hún ní àlòpẹ́?
Àwọn tó ń ṣètò Qatar 2022 ṣe ìlérí pé ètò amú-àyíká-tutù ọ̀hún kó ní ṣe okùnfà àlékún afẹ́fẹ́ tó léwu fún àyíká (greenhouse gass emmission) nítorí pé iná tó ń lò ń wá láti ẹ̀rọ iná Òòrùn tuntun orílẹ̀èdè náà.
Àwọn tó ṣe iṣẹ́ yìí
Johannes Dell, Leoni Robertson Sara Fayyad , Mohammad Hamdar àti Dominic Bailey lọ kọọ́ tó ṣì ṣeé Maryam Nikan àti Gerry Fletcher ló tòó Kaveri Biswass àti Adam Allen ló ṣe àgbékalẹ̀ rẹ̀ Sally Morales ni alákóso Ọ̀jọ̀gbọ́n Gareme Maidment ti fásitì London Southbank ni oluùdámọ̀rọ̀n orísun àwòrán: Getty Images, Hum3d, Hajar Saleh