BBC News, Yorùbá - Ìròyìn
Ìròyìn tó ṣe kókó
Wo bí ìgbẹ́jọ́ àwọn afurasí méje tó dáná sun ilé Asabi Olórìṣà n'Ilọrin ṣe lọ
Asabi Olorisa ni olujẹjọ keji ti sọ fun oun tẹlẹ pe awọn ti fẹ le oun ni Ilọrin tẹlẹ ṣugbọn tori pe oun ti kọle ni lawọn o ti fii ṣe bẹẹ.
Àwọn jàndùkú agbébọn ṣekúpa sọ́jà mọ́kànlá, ọlọ́pàá kan, Gómìnà ṣàtìlẹ́yìn ìrànwọ́ fáwọn ẹ́bí olóògbé
Lalẹ ọjọ Iṣẹgun ọsẹ yii ni iṣẹlẹ ọhun ṣẹlẹ ni Giro Masa ni ijọba ibilẹ Shanga ni ipinlẹ Kebbi.
Àjọ Ìṣọ̀kan Àgbáyé, orílẹ̀èdè 123, bẹ̀rẹ̀ ìgbésẹ̀ tí yóò sọ òwò ẹrú di ìjìyà tó burú jù lọ fún ọmọnìyàn
Igbesẹ ti awọn orilẹede 123 ti fọwọ si yii, awọn ilu bii America, Israel ati Argentina sọ pe awọn ko fara mọ ọn ni tawọn.
Fídíò, Àwọn ọ̀dọ̀ ilẹ̀ Africa ni ìlera ọpọlọ wọn pé jù lọ láàgbáyé-Ìwádìí, Duration 1,03
Iwadii ti fi han bayii pe awọn ọdọ ilẹ Africa ni ilera ọpọlọ wọn pe ju lọ lagbaaye, ti a ba fi we ti awọn orilẹede agbaye yooku.
Orin, Kò ṣe é má gbọ̀ ọ́, Duration 0,58
Kò ṣeé má gbọ̀ọ́
Àlàyé lórí ọ̀nà tuntun tí Amẹrika fẹ́ gbà láti fìyà jẹ orílẹ́èdè Iran
Awọn onwoye sọ pe Amẹrika n gbero lati gbẹsẹ le erekusu Kharg Island nibi ti Iran n ko epo rọbi ti wọn n ta silẹ okeere pamọ si.
Àwọn agbésùnmọ̀mí tó jí ọmọ ìjọ ECWA mẹ́jọ gbé ní Kwara ń bèèrè bílíọ̀nù kan náírà fún ìtúsílẹ̀ wọn
Eniọwọ Timothy Omole ijọ ECWA salaye pe ẹrọ ibanisọrọ ọkan lara awọn ti wọn ji gbe ni wọn lo lati fi pe
Àwọn jàndùkú ya wọ ọ́fíìsì Amotekun l'Osun, jí ìbọn wọn gbé sálọ
Abiodun Ojelabi to jẹ alukoro fun awọn ọlọpaa ipinlẹ Osun ṣalaye pe iroyin naa ti de eti awọn, awọn si ti bẹrẹ iwadi lori ọrọ naa.
'Biola Bayo, mo fà ẹ́ sí kóòtù Ọlọ́run'-Princess bú sígbe torí Baba Ijesa tí Biola Bayo gbé wá sóri ètò
Lori ifọrọwerọ naa ni Princess fi tun sọ pe Ọlọrun yoo ṣedajọ fun Biola ati Ijesa, to ba jẹ pe bi eeyan ṣe n ṣe ni wọn ṣe yẹn.
NBA,Ẹgbẹ́ Amòfin Naijiria bínú sí Sowore tó pàtẹ ìpàdé akọ̀ròyìn nínú kóòtù
Ilu Abuja ni iṣẹlẹ naa ti waye lanaa ọjọ Iṣẹgun, nile ẹjọ giga kan.
Èmi ṣì ni alága NURTW- MC Oluomo
Ṣáájú ni ìròyìn tí kọ́kọ́ gbòde pé Baruwa àti àwọn èèyàn rẹ̀ yawọ ilé ẹgbẹ́ NURTW tó wà ní Abuja tí wọ́n sì fẹ́ àkóso ilé ẹgbẹ́ náà pé òun ni ilé ẹjọ́ dájọ́ pé òun ó jẹ́ ojúlówó alága ẹgbẹ́ náà.
Móríwú
BBC News Yorùbá ti wà lórí ìkànnì WhatsApp
Má jẹ́ kí etí rẹ ó di sí gbogbo ìròyìn ohun tó ń lọ ní Naijiria àti káàkiri àgbáyé. Mọ̀ nípa wọn lórí ìkànnì Whatsapp rẹ
Ìròyìn Àkàgbádùn
Fídíò, Mo ti bí ọmọ márùn-ún tẹ́lẹ̀ kí n tó bí ibẹ́rin báyìí, ìbejì ni scan sọ fún mi- Ìyá Ìbẹ́rin, Duration 4,35
Nigba ti mo gbọ pe iyawo mi bi ọmọ mẹrin, ẹ ru ba mi, mo si fẹ ṣalọ- Baba Ibẹrin
El-Rufai lóun ò jẹ̀bi ẹ̀sùn ṣíṣe owó ìlú kúmọkùmọ tí wọ́n fi kan òun
Iroyin fidi rẹ mulẹ pe agbẹjọro gomina ipinlẹ Kaduna tẹlẹ ri ọhun, Ukpom Akpan, rọ ile ẹjọ lati gba beeli rẹ ko le raye gbaradi fun igbẹjọ rẹ.
À n ṣiṣẹ́ kárakára láti dáàbò bò àwọn èèyàn Kwara- Kọmiṣọnna ọlọ́pàá Kwara
Olori ọdọ ilu naa, Baloude Najeem ti BBC Yoruba ba sọrọ lori ago sọ pe nnkan bi aago mẹjọ aarọ ni iṣẹlẹ naa waye.
Ìdí rèé tí àpapọ̀ ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ NLC, TUC, NULGE àti JNC fi fagilé ìfẹ̀họ́núhàn tí wọ́n fẹ́ ṣe tako bánkì UBA l'Osun
Lọsẹ to kọja ni awọn agbarijọpọ ẹgbẹ oṣiṣẹ ipinlẹ Osun ti kede pe ifẹhonuhan naa yoo waye ni ọjọ kẹrinlelogun osu yii lori bi ile ifowopamọ UBA ṣe kọ lati gbẹsẹ kuro lori owo ijọba ibilẹ to wa ni akata wọn.
Kò tí ì sí obìnrin kankan tó jáde síta pé wọ́n fipá bá òun lòpọ̀ lásìkò ọ̀dun Ozoro - Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá
Ọpọ fidio lo ti kun ori ayelujara, eyi to ṣafihan bi awọn ọdọ ọkunrin ṣe n kọlu awọn obinrin ti wọn da wa.
Àwọn agbébọn kọlu ìjọ ECWA ní Kwara, wọ́n jí èèyàn mẹ́jọ gbé.
Iṣẹlẹ naa waye lanaa ọjọ Aiku ọjọ kejilelogun Oṣu kẹta ọdun 2026 ni ile ijọsin ECWA to wa ni ilu naa ni nnkan bi ago mẹwa owurọ.
Ọ̀dọ́kùnrin ẹni ọdún 21 fipá bá obìnrin lopọ̀, fún un lọ́rùn pa l'Ondo
Awọn olugbe ilu naa ko mọ ọjọ ori oloogbe naa, sugbọn wọn salaye pe obinrin agbalagba ni obinrin ti Alabi Anthony fi ipa ba lopọ.
Fídíò, Inú abala àríwísí làwọn olólùfẹ́ mi ti tẹ orúkọ 'Arike Pre order' mọ́ mi – Arike Pre order, Duration 3,07
Ọgbẹni Samuel Banks ti ọpọ mọ si Arikẹ Pre Order lori ayelujara naa sọ pe, Fídíò àwàdà mi wà láti jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé bí wọ́n bí èèyàn nínú ẹrọ̀fọ̀ kò ní kó máà jéèyàn láyé.
Makinde kéde ₦10,000 owó ìrànwọ́ fáwọn òṣìṣẹ́ ìpínlẹ̀ Oyo torí ọ̀wọ́ngógó epo bẹntiróòlù
Makinde ṣalaye pe awọn oṣiṣẹ yoo ri owo yii gba fun oṣu mẹta na lati maa fi wọ ọkọ lọ sibi iṣẹ wọn.
Ìdí rèé táwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa fi lè gba ẹ̀jẹ̀ ará wọn pamọ́ báyìí láti lò fún ìtọ́jú tó bá nílò kí wọ́n gbẹ̀jẹ̀
Fun ọpọlọpọ ọdun, alaisan to ba jẹ ẹlẹrii Jehofa tawọn dokita ba sọ fun un wi pe o nilo ki wọn fa ẹjẹ si i lara nile iwosan ko ni gba ki wọn ṣe bẹẹ tori o tako igbagbọ wọn.
Ìdí rèé tí mo fi so àpò ilé ọmọ mi - Shaffy Bello
Bello sọ èyí níbi ètò rẹ̀ kan tó máa ń ṣe lórí Youtube, Shaffy Bello TV níbi tó ti ṣàlàyé ìrìnàjò rẹ̀ lásìkò tó ń bímọ lọ́wọ́ àti àwọn ìpinnu tó ṣe láti fètò sí ọmọ bíbí.
Kí ló n fa ikọ́ọfe àti pé báwo lo ṣe le dènà rẹ̀?
Aarun ikọọfe jẹ ọkan gboogi ailera to maa n ṣakoba fun ẹdọforo lara awọn to ba lugbadi rẹ.
Ìròyìn Pàtàkì
Kọ́milẹ́kọ̀ọ́
Ẹ tẹ̀lé wa lórí ìkànnì ayélujára
Ìwádìí kíkún lóríi kókó ìròyìn
Àwọn tó ń f'owó ran Boko Haram lọ́wọ́ jẹ́ ẹni táwọn aláṣẹ mọ́, wọn ò kàn dárúkọ wọn ni- Buratai
O tẹnu mọ pe awọn eeyan jẹ mimọ, ti wọn si n gbe pẹlu wa lorilẹede Naijiria.
Kókó àdéhùn méjì tí ìjọba Nàíjíríà àti UK tọwọ́bọ rèé lásìkò àbẹ̀wò Tinubu
Fún ìgbà àkọ́kọ́, ìjọba Nàìjíríà yóò máa gbà láti ṣàmúlò lẹ́tà láti UK – èyí tó ṣe é ṣàmúlò fún àwọn tí kò bá ní ìwé ìrìnnà – tó túnmọ̀ sí pé àwọn tó bá fẹ́ ṣe ìrìnàjò kò ní ṣẹ̀ẹ̀ máa dúró de ìwé ìrìnnà fún ìgbà pípẹ́ kí wọ́n tó padà sí orílẹ̀ èdè wọn.
Mẹ́ta nínú èèyàn márùn-ún tó so àdó olóró mọ́ra wọ Maiduguri ló yin tiwọn, méji ṣì kù tí à ń wá báyìí- Gomina Zulum
Ninu ifọrọwerọ ti BBC ṣe pẹlu Gomina Zulum lo ti ni awọn marun-un lo wọ Maiduguri ti wọn so bọmbu mọra, amọ mẹta ninu wọn lo ṣi yin tiwọn ti ijamba fi waye laipẹ yii.
Mi ò ní í ṣe aláìní láyé mi, èmi àti Ọlọ́run nìkan la ní ọrọ̀ jù - Pásítọ̀ Chris Oyakhilome
Nigba to n fidi ọrọ naa mulẹ, pasitọ ijọ Christ Embassy naa sọ pe o maa n ya oun lẹnu bi awọn eeyan ba n fi owo ati ipo aye ṣe odiwọn ọrọ̀ oun.
Toyosi Adesanya, òṣèré tíátà Yoruba, di ọlọ́mọ láyé fún ìgbà àkọ́kọ́ nípasẹ̀ ìlànà abánigbóyún
Biola Bayo, oṣere tiata mii lo kede iroyin naa loju opo ayelujara Instagram rẹ, to si jẹ ko di mimọ pe tọkọtaya naa di ọlọmọ laye ni ilana abanigbe oyun.
"Bí gbogbo àgbáyé bá nílò epo rọ̀bì, Nàíjíríà wà níbẹ̀ láti pèsè rẹ̀ fún wọn"
Minisita feto iroyin, Mohammed Malagi fọwọ gbaya bẹẹ nilu London nigba to n ba ikọ iroyin BBC sọrọ lẹnu abẹwo rẹ si UK pẹlu aarẹ Bola Ahmed Tinubu.
Àṣìṣe ni ọ̀rọ̀ tí mo sọ lórí ètò ààbò Nàìjíríà, ẹ foríjìmí - Aremu Afolayan
Níbi ètò EKO57 ni Afolayan ti sọ pé òun buwọ́lu ìyànsípò Tinubu lọ́dún 2027, tó sì sọ pé òun ń ṣe dáadáa àti pé àìrajaja ètò ọrọ̀ ajé táwọn èèyàn ń pariwo kò dé ọ̀dọ̀ òun rárá.
Àlàyé rèé lórí ìdí tí Nàíjíríà fi bọ́ sí ipò kẹrin láti ipò kẹfà, nínú àwọn orílẹ̀èdè tí ìgbésùnmọ̀mí ti gbilẹ̀ ní àgbáyé
Igbelewo ọlọdọọdun nipa bawọn orilẹede lagbaye ti gbewọn si nidi iwa igbesunmọmi, global terrorism index (GTI) 2025 lo kede bẹẹ ninu atẹjade kan.
Ìdí rèé tí Femi Fani-Kayode àti Dele Momodu fi ń sọ̀kò ọ̀rọ̀ sí ara wọn
Awọn ọrọ naa le debi pe bi wọn ṣe n fi eebu ara bu ara wọn ni wọn tun n mẹnuba awọn to bi wọn.
Ṣé lóòótọ́ ni pé èpè Alaafin Aole sì ń ja Yorùbá títí di òní?
Itan sọ fun wa pe ọmọ Alaafin Abiodun ni Aole, o si jọba nilu Oyo laarin ọdun 1789 si 1796.












































































