You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
BBC News, Yorùbá - Ìròyìn
Ìròyìn tó ṣe kókó
Fídíò, Arọ́bafin ni Sẹ́nétọ̀ Adeseun ni mo fi ní kó gáfárà fún ipò Mayegun ìlú Ogbomoso – Soun Ghandi Laoye, Duration 3,55
Ọbalaye naa ni Sẹnetọ Adeṣeun ko fi arinfin rẹ fun Ṣọun bo rara, koda o tun sọrọ alufansa sii ni gbangba.
Àwọn agbébọn tún ya bo ìjọba ìbílẹ̀ Kaiama ní Kwara, ṣekúpa ẹ̀ṣọ́ asọ́gbó márùn ún, dáná sun ọkọ̀ àti alùpùpù
Eyi ko ṣẹyin bi awọn agbebọn ṣe kọlu ilu naa ni nnkan bii aago mẹta owurọ oni, ọjọ kẹwaa, oṣu Kẹrin, ọdun 2026 ti wọn si ṣekupa awọn ẹṣọ asọgbo marun-un.
Ìdílé oyè fún Gómìnà Adeleke ní gbèdéke ọjọ́ méje láti rọ Apetumodu tó ń ṣẹ̀wọ̀n l'Ámẹ́ríkà lóyè
Ile ẹjọ kan lorilẹede Amẹrika lo dajọ ẹwọn fun Ọba Apetumodu ti ilu Ipetumodu ti wọn ni o jẹbi ẹsun lilu jibiti pẹlu eto ẹyawo COVID-19 ti wọn gbe kalẹ lati ṣe iranwọ fun awọn okoowo kekeke to fara kaasa lasiko ajakalẹ arun naa.
Ìjọba àpapọ̀ ké gbàjarè lẹ́yìn tí àrùn tó ń gbẹ̀mí màlúù kọlu ìpínlẹ̀ 17
Ijọba ni arun naa n ṣakoba fun ọrọ aje ohun ọsin ati pe ti ijọba ko ba tete kapa rẹ, o le pa odidi agbo maluu kan run.
Orin, Kò ṣe é má gbọ̀ ọ́, Duration 1,01
Kò ṣeé má gbọ̀ọ́
Ta ni ọ̀gágun Braimah táwọn agbésùnmọ̀mí ṣekúpa pẹ̀láwọn ọmọogun míràn ní Borno, Tinubu kẹ́dùn pẹ̀lú ẹbí àwọn tó ṣubú lójú ìjà?
Ohun ti a gbọ ni pe lojiji lawọn agbesunmọmi naa ya wọ ibudo awọn ọmogun naa ti wọn si bẹrẹ si ni yinbọn.
Wo bí o ṣe lè wo, tàbí ṣe àtẹ̀jáde ìwé atọ́nà pélébé fún ìdánwò Jamb UTME
Ajọ Jamb ni idanwonaa yoo ṣi waye laarin ọjọ kẹrindinlogun si ikarundinlọgbọn oṣu kẹrin ọdun 2025 ti wọn kede tẹlẹ.
Ọkùnrin kan ṣekúpa èèyàn mẹ́ta nínú ìdílé kan náà, ariwo sọ
Àwọn kan ń sọ pé ọkùnrin tó ṣá àwọn èèyàn náà ní àìsàn ọpọlọ ń dà láàmú ṣùgbọ́n BBC New Yoruba kò le fìdí èyí múlẹ̀.
Iléeṣẹ́ ìfọpo Dangote dá owó epo bẹntiró padà sí ₦1,200
Ileeṣẹ ọhun sọ ninu atẹjade kan pe adinku owo epo yii lo n waye latari bii owo epo naa ṣe n lọ soke ati sodo lagbaye.
Wo ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa ikọ̀ aláàbò ilẹ̀ Ibadan tuntun, Ibadan Community Guard
Aafin Olubadan to wa ni Oke Aremo niluu Ibadan ni wọn ti ṣe eto naa.
Akẹ́kọ̀ọ́ Covenant University jáde láyé níbi tó ti ń gbá bọ́ọ̀lù, Ilé ẹ̀kọ́ ṣàlàyé ohun tó fa ikú rẹ̀
Ìròyìn tó gba orí ayélujára ni pé lásìkò tí akẹ́kọ̀ọ́ náà ń kópa nínú bọ́ọ̀lù àfẹsẹ̀gbá ló déédé ṣubú lulẹ̀, tí kò sì tètè rí ìtọ́jú tó fi gba ibẹ̀ jáde láyé.
BBC News Yorùbá ti wà lórí ìkànnì WhatsApp
Má jẹ́ kí etí rẹ ó di sí gbogbo ìròyìn ohun tó ń lọ ní Naijiria àti káàkiri àgbáyé. Mọ̀ nípa wọn lórí ìkànnì Whatsapp rẹ
Ìròyìn Àkàgbádùn
Wáyà iná ẹ̀lẹ́ńtíríkì já, iná ṣẹ́yọ, ṣekúpa èèyàn kan ní Ilọrin, ọ̀pọ̀ farapa, dúkìá olówó iyebíye jó mọ́lé
Àwọn èèyàn agbègbè náà ní ibi tí wọ́n ti ń gbìyànjú láti yọ ohun èlò kúrò lára iná ló ti gbé e.
Mi ò bá Makinde àti Olubadan jà, ìdí rèé táwọn èèyàn kò fi rí mi pọ̀ mọ́ Gómìnà àti Ọba Ladoja - Alaafin
Alaafin ni oun ni ibaṣepọ to dan mọran pẹlu Ọba Rashidi Ladoja ati Gomina ipinlẹ Oyo.
Wo àwọn ojú pópó tí yóò wà ní títì pa nílùú Eko lásìkò àbẹ̀wò Tinubu bẹ̀rẹ̀ láti òní
Kọmiṣọna fun igbokegbodo ọkọ nipinlẹ Eko, Oluwaseun Osiyemi, sọ ninu atẹjade kan to fi sita pe igbesẹ yii waye lati le jẹ ki eto ifilọlẹ awọn akanṣẹ iṣẹ ti Gomina Babajide Sanwo-Olu ti aarẹ fẹ ṣe lọ ni irọwọ rọsẹ.
Àwọn afurasí darandaran ṣá àgbẹ̀ sínú oko rẹ̀ l'Ogbomoso lẹ́yìn tó ní wọn kò gbọdọ̀ da ẹran níbẹ̀
Awọn afurasi darandaran naa ni wọn fẹ fi awọn maalu wọn jẹ oko oloogbe Kehinde lọjọ Isinmi, ọjọ karun un, oṣu Kẹrin ọdun 2026 yii, amọ o kọ jale ki wọn to gbẹmi rẹ.
Mílíọ́nù méjìdínlógójì tọ́ọ̀nù oúnjẹ ló ń ṣòfò ní Naijiria lọ́dọdún – Àjọ EU
Wọn ni ti ounjẹ ba n ṣofo, o n tumọ si pe omi, asiko ati okun ti wọn fi pese ounjẹ naa ti ṣofo niyẹn.
Àwọn dókítà ṣẹ́wélé ìyanṣẹ́lódì, fún ìjọba ní gbèdéke
Iwadii fi han wi pe awọn dokita nile iwosan ijọba ti daṣẹ silẹ fun ọjọ mọkanlelaadọta lati igba ti ijọba Aarẹ Bola Tinubu ti bẹrẹ.
Ṣé lóòótọ́ ni ìjà wà láàrin Tinubu àti Sanwo-Olu? Ìjọba ìpínlẹ̀ Eko sàlàyé
Ijọba ipinlẹ Eko ni ''baba ni Aarẹ Bola Tinubu jẹ fun Sanwo-Olu, ati pe ahesọ ọrọ lasan ni gbogbo nnkan tawọn eeyan n gbe kiri.''
Kí ni yóò ṣẹlẹ̀ tí gbèdéke tí Trump fún Iran lórí 'Strait of Hormuz' bá kọjá?
Ó ní láti dènà irúfẹ́ ìkọlù yìí, Iran gbọdọ̀ gbà àwọn nǹkan tí òun ń fẹ́, tó fi mọ́ fífi ààyè gba gbígbé epo láì sí ìdàmú gba Strait of Hormuz.
Wo àwọn ohun tó yẹ láti ṣe bí o bá jí ní òwúrọ̀
Onírúurú ìròyìn ni a ti máa ń gbọ́ nípa bí ẹ̀rù ṣe máa ń ba àwọn èèyàn nígbà tí wọ́n bá fẹ́ dìde lórí ibùsùn lẹ́yìn tí wọ́n bá jí, tí èyí sì máa ń fa ìṣòro míì fún wọn.
Wo orílẹ̀èdè márùn-ún tí inú àwọn èèyàn rẹ̀ dùn jùlọ lágbàáyé lọ́dún 2026
Ìjábọ̀ náà, tí àjọ Oxford Health Research Institute pẹ̀lú àjọṣepọ̀ United Nations Sustainable Development Goals máa ń gbé jáde ní ọdọọdún, máa ń ṣe àgbéyẹ̀wò ètò ọrọ̀ ajé, àtìlẹyìn àwùjọ, bí àwọn èèyàn ṣe ní àǹfàní láti lè jáde bó bá ṣe wù wọ́n sí, àti bí ẹ̀mí àwọn èèyàn ṣe le gùn sí ní orílẹ̀ èdè ogóje (140) káàkiri àgbáyé yẹ̀wò.
A ti dóòlà èèyàn 31 tí wọ́n jí gbé nílé ìjọsìn lọ́jọ́ ọdún Àjínde – Ilésṣẹ́ ọmọ ogun
Bo tilẹ jẹ pe ileeṣẹ ọmọ ogun sọ pe awọn ko fi akoko ṣofo ki awọn to ya bo ile ijọsin ti ikọlu naa ti waye, awọn to wa nibẹ sọ fun awọn akọroyin pe fun ọpọ wakati lawọn agbesunmọmi naa fi ṣọṣẹ lai si idwọ kankan.
Àṣìta ìbọn ṣekúpa ọ̀dọ́binrin ọmọ ọdún mẹ́rìnlá nínú ilé, ìwádìí bẹ̀rẹ̀
Ileeṣẹ ologun ni iwa aibikita ni awọn to yinbọn naa hu, ati pe ileeṣẹ ologun ti bẹrẹ iwadii lati mọ awọn to yinbọn to pa ọmọdebinrin naa.
Ìròyìn Pàtàkì
Kọ́milẹ́kọ̀ọ́
Ẹ tẹ̀lé wa lórí ìkànnì ayélujára
Ìwádìí kíkún lóríi kókó ìròyìn
Ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ sáyẹ́nsì ṣo ohun tó pa Jesu
Ẹya Jew ni Jesu, o dari awọn to tẹle e, ṣugbọn iṣesi rẹ ko tẹ awọn alaṣẹ ilẹ Rome lọrun.
Àwọn èèyàn Burkina Faso gbọdọ̀ gbàgbé nípa ìjọba awarawa – Ibrahim Traoré
Ṣaaju ni Traoré ti kọkọ ṣeleri lati da ijọba pada fun awọn oloṣelu ninu oṣu Keje ọdun 2024 amọ nigba to ku oṣu meji ki gbedeke to da pe, o kede pe awọn ologun ni yoo ṣi maa tukọ ilẹ naa lọ fun ọdun marun un mii.
Eré Àjíǹde di wàhálà! Akẹ́kọ̀ọ́ dèrò ilé ìwòsàn lẹ́yìn tí wọ́n lú ú bí bàrà lásìkò tó ṣe Jesu nínú eré Ajinde
Ìròyìn ní ọ̀rọ̀ bẹ́yìn yọ nígbà tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ní lu Dennis láti ṣàfihàn àwọn ìyà tí Jésù jẹ nígbà ayé rẹ̀ èyí tó mú kí wọ́n lù ú bí ẹni lu bàrà, tó sì tara bẹ́ẹ̀ farapa gidigidi.
"Blessing CEO, dá ₦20m ti mo fun ọ lórí àrùn jẹjẹrẹ tí o sọ pé ó ń ṣe ọ́ padà" Oil Money yarí, Blessing náà fèsì
Oil Money sọ pe ogun miliọnu loun fun Blessing, o si gbọdọ da a pada bayii laaarin ọjọ meje.
Àlàyé rèé lórí ohun tó ṣokùnfà ikú Destiny Boy
Lọjọ kẹtadinlogun oṣu Kinni ọdun 2026 yii ni ọdọmọde olorin naa ku lojiji lẹni ọdun mejilelogun.
Kókó ọ̀rọ̀ Tinubu níbi ìfilọ́lẹ̀ pápákọ̀ òfurufú Gateway ní ìpínlẹ̀ Ogun
Nigba to n sọrọ, Aarẹ Bola Tinubu sọ pe papakọ ofurufu naa ṣafihan wi pe Gomina Abiodun lo owo to n gba daradara.
Ẹ fura o! Eko ni àrùn HIV pọ̀ sí jù ní Naijiria, èèyàn 2,298 ló ti ní i láàrín oṣù mẹ́ta àkọ́kọ́ ọdún 2026 - Àjọ NDR
NDR kede pe ipinlẹ Eko ni onka awọn to ti lugbadi arun naa pọ si bayii, ti ipinlẹ Benue si se ipo keji.
Wo kókó ọ̀rọ̀ tí Tinubu sọ lásìkò àbẹ̀wò ìbánikẹ́dùn sí Jos, bó ṣe ní kí wọn ri ẹ̀rọ̀ ayàwòrán 5000 sáwọn ojú pópó yíká ìlú náà
Ní ọjọ́bọ̀ ni Tinubu ṣàbẹ̀wò sí ìlú Jos látàrí ìpànìyàn tó wáyé níbẹ̀ ní ọjọ́ Àìkú àti ọjọ́rú níbi tí ọ̀pọ̀ èèyàn ti pàdánù ẹ̀mí wọn.
Amẹrika àti Iran fẹnukò láti dáwọ́ ogun dúró fún ọ̀sẹ̀ méjì
Igbesẹ yii lo n waye lẹyin oṣu kan ti Amẹrika ati Israel bẹrẹ ogun Iran.