Ìjọba Kwara pe Bukola Saraki, Abdulfatah Ahmed àtàwọn mìí lẹ́jọ́ ẹ̀sùn ìpànìyàn

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ijọba ipinlẹ Kwara ti pe alaga ile igbimọ asofin tẹlẹri, Sẹnetọ Bukola Saraki ati Gomina ana ni ipinlẹ naa, Abdulfatah Ahmed ati awọn meje mii lẹjọ fun ẹsun ipaniyan ti wọn ko mọọmọ ṣe.

Ẹsun naa ni o nii ṣe pẹlu idigunjale awọn banki kan ni ilu Offa to waye lọjọ karun un, oṣu kẹrin, ọdun 2018, nibi ti awọn adigunjale naa ti ṣekupa ọlọpaa ati araalu ti iye wọn le ni ọgbọn.

Eyi di mimọ ninu iwe ipẹjọ ile ẹjọ to tẹ BBC Yoruba lọwọ lọjọ.

Ti ẹ ko ba gbagbe, gbogbo awọn ti ọwọ tẹ lori idigunjale naa ni ile ẹjọ giga ti dajọ iku fun pe ki wọn lọ yẹgi fun wọn.

Lẹyin naa, awọn ọdaran ọhun pe ẹjọ kotẹmilọrun ṣugbọn ti idajọ ile ẹjọ naa ri bakan pẹlu ti ile ẹjọ giga.

Wayi o, ijọba Kwara ti pe Bukola Saraki, Abdulfatah Ahmed, Olori oṣiṣẹ gomina Ahmed, Yusuf Abdulwahab ati Alabi Olalekan lẹjọ fun ẹsun pe wọn ko ohun ija fun awọn adigunjale naa ti wọn dajọ iku fun.

Nọmba ẹjọ naa to ti da họuhọu silẹ ni ipinlẹ Kwara bayii ni KWS/114C/26.

Iwaju adajọ agba, Haleemah Salman ti ile ẹjọ gíga ilu Ilorin ni wọn yoo wọ wọn lọ ni ọjọ kẹrin, osu Kẹfa, ọdun 2026 yii.

Saraki ati awọn yoku rẹ ni yoo wa jẹjọ lori ogun ẹsun ọtọọtọ ti wọn fi kan wọn.

Ibanilorukọjẹ lsan ni igb ẹjọ naa jẹ fun mi – Saraki

Sẹnetọ Bukola Saraki ti wa fesi si ẹsun yii wi pe iwa ọdaju gbaa ni lati fi ba orukọ oun jẹ.

Saraki lo sọ bẹẹ ninu atẹjade kan to fi lede lọjọ kẹtadinlogun oṣu Kẹrin, ọdun 2026 yii.

O sọ pe igbesẹ gomina ipinlẹ naa lati wọ oun lọ ile ẹjọ lori idigunjale banki Offa ti oun ko mọwọ-mẹsẹ nipa rẹ jẹ iwa ọdaju.

Saraki wa rọ gomina naa pe ko dẹkun fifi ọrọ idigunjale banki Offa ba oun ja.

O sọ pe ṣe lo yẹ ki oun dakẹ lori ọrọ naa ni, ki awọn si pade nile ẹjọ ṣugbọn nitori awọn eniyan, oun n sọ pe oun ko mọ nnkannkan nipa rẹ.

O ni "Labẹ iṣejọba Buhari ni wọn ti jo ọrọ yii pọ pẹlu ifọwọsowọpọ awọn kan ni Kwara lati gba ijọba lọwọ wa.

"Amọ, mo ni igbagbọ ninu ile ẹjọ wi pe wọn yoo se ohun to tọ, wọn yoo si gbe idajọ ododo kalẹ.

"Awọn agbẹjọro mi ti gbọ si wọn si ti gbaradi, mo mọ pe ẹjọ ti wọn fi kan mi yii, yoo poora bi afẹfẹ."