Seyi Makinde kò yẹ nípò gómìnà lórí ogun Wẹ́ẹ̀ti ẹ̀ tó sọ, ẹ̀yin agbófinró, ẹ má fi ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣeré - APC yarí

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 7

Ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC ti fesi si ẹsun ti gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde fi kan ẹgbẹ oṣelu naa nibi ipade apero tawọn ẹgbẹ oṣelu alatako ṣe ni ilu Ibadan lọjọ Abamẹta, ọjọ Kẹẹdọgbọn, oṣu Kẹrin, ọdun 2026.

Nibi ipade apero naa Seyi Makinde ti ṣekilọ pe ti iṣejọba to wa lode ba n tẹsiwaju pẹlu bi wọn ṣe n gbiyanju lati tẹ awọn ẹgbẹ awọn alatako ri ṣeeṣe ko fa ohun to waye nigba aye ogun "Wet e".

Atẹjade kan ti ẹgbẹ oṣelu APC fi lede latọwọ agbẹnusọ ẹgbẹ naa, Felux Morka lọjọ Aiku fẹsun kan pe Gomina Makinde n pe fun ogun lori ẹsun ti ko ni ẹsẹ nilẹ pe iṣejọba to wa lode n gbiyanju lati sọ orilẹ ede Naijiria di ẹlẹgbẹ oṣelu kan ṣoṣo.

Morka, ninu atẹjade naa ni APC bu ẹnu atẹ lu Makinde pe o n gbiyanju lati da wahala silẹ laaarin ilu, ati pe ọrọ to sọ jẹ idunkoko su alaafia ati aabo ilu.

O ni o jẹ ikọnilominu pe gomina to yẹ ko da aabo bo ilu lo n lo asiko to jẹ ipenija nla fun ilu lati fi maa dunkoko mọ awọn eeyan ati ijọba Naijiria.

O woye pe iwa Makinde naa ṣafihan pe ko yẹ ni ipo gomina to dimu rara, to si ni awọn ọrọ to sọ kii ṣe ohun ti wọn le foju parẹ gẹgẹ bi ọrọ oṣelu lasan.

Ẹgbẹ oṣelu APC wa kepe awọn ẹṣọ aabo lati dide si ọrọ naa lojuna ati le da aabo bo ẹmi ati dukia awọn eeyan to fi mọ eto uṣejọba awaarawa.

Bakan naa ni APC sọ pe awọn kọ igbiyanju awọn ẹgbẹ alatako lati di ẹbi ipenija abẹnu to n ba awọn ẹgbẹ oṣelu naa finra le awọn lori ati pe awọn kọ lo maa ba awọn ẹgbẹ oṣelu naa yanju aawọ to wa laaarin wọn.

Wọn ni ọpọ ipenija to n koju awọn ẹgbẹ oṣeku alatako lo jẹ afọwọfa wọn nipasẹ aibọwọ fun odin ati ilana ẹgbẹ wọn ati aifẹnuko wọn.

"APC kọ ni yóò báwọn alátakò yanjú aáwọ̀ abẹ́llé wọn gẹ́gẹ́ bí wọn ṣe ń retí"

Atẹjade naa fi kun pe ẹgbẹ oṣelu APC ni igboya pe awọn ọmọ Naijira ni ọgbọn ati oye lati ma ko akoso iṣejọba le ẹgbẹ ti ko le ṣe amojuto ipenija ti wọn ni labẹnu lọwọ.

Wọn ni awọn eekan ẹgbẹ alatako ati apapọ ẹgbẹ oṣelu alatako ko i tii figba kankan sọ nipa awọn ọna ti wọn fi fẹ mu ilọsiwaju ba Naijiria bikoṣe ki wọn maa gbe awọn ahesọ ọrọ nipa ẹgbẹ oṣelu APC.

"Ẹgbẹ oṣelu wa kọ lati tẹle ireti awọn ẹgbẹ alatako pe APC maa bawọn yanju aawọ to n waye laaarin wọn. Kii ṣe ojuṣe wa, a o si ni pese idari bẹẹ fun wọn."

APC fi kun pe, labẹ idari Aarẹ Bola Ahmed Tinubu, awọn ni ifarajin si mimu igbooro ba eto iṣejọba awaarawa, bibọwọ fun ofin to de ilu ati pipese alaafia, aabo ati ilọsiwaju fawọn araalu.

A máa panupọ̀ fa olùdíje kan kalẹ̀ láti tako Tinubu – Àwọn ẹgbẹ́ alátakò kéde

Saaju ni a mu iroyin wa pe awọn eekan lẹgbẹ oṣelu alatako ni Naijiria ti kede pe awọn yoo panupọ fa oludije kan kalẹ lati dupo aarẹ tako Aarẹ Bola Tinubu nibi eto idibo gbogbogbo ọdun 2027.

Ifẹnuko yii je ọkan gboogi lara ohun ti awọn eekan naa fẹnuko le lori nibi ipade apero ti wọn ṣe lọjọ Abamẹta ni ilu Ibdan, olu ilu ipinlẹ Oyo.

Wọn ni igbesẹ naa n waye lojuna ati wa ojutuu sawọn ipenija ti Naijiria n koju labẹ iṣejọba Aarẹ Bola Tinubu ati ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC.

Bakan naa ni wọn ṣekilọ pe iṣejọba awaarawa ti di ohun atẹmọlẹ labẹ iṣejọba to wa lode.

Apero ọhun ni awọn eekan lẹgbẹ oṣelu alatako parapọ korajọ sibẹ ti wọn si gbe awọn ipinnu kan jade.

Wọn ni idi ti awọn fi panupọ lati fẹnuko lati ṣe atilẹyin fun oludije kan ṣoṣo jẹ kati ri pe wọn ko pin ibo bii ti atẹyinwa.

Nigba to n sọrọ ikini kaabọ nibi apero naa, Gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde ni eto iṣejọba awaarawa ti n sọnu ni Naijiria diẹdiẹ.

Makinde ṣekilọ pe ijọba to wa lode ko gbọdọ faye gba ki ohun to ṣẹlẹ nigba "wet ẹ" ni Ibadan tun waye mọ lode oni.

"Iṣejọba awaarawa laisi ẹgbẹ oṣelu alatako kii ṣe ijọba tiwantiwa, o jẹ sisọ orilẹ ede di ẹlẹgbẹ oṣelu kan ṣoṣo ni."

'Aisi ifẹnuko latẹyinwa laaarin awọn ẹgbẹ iṣelu alatako maa n fa aisi iṣọkan'

Ninu ọrọ rẹ, alaga igun kan lẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP Taminu Turaki sọ pe igbesẹ yii jẹ ohun ti wọn fi ọgbọn inu ṣe ati pe o jẹ nnkan ti orilẹ ede Naijiria nilo lasiko yii.

O ṣekilọ pe aisi ifẹnuko latẹyinwa laaarin awọn ẹgbẹ iṣelu alatako maa n fa aisi iṣọkan.

Turaki woye pe o rọrun lati ṣẹ igi kan amọ to ṣoro lati kan oṣuṣu ọwọ to si rọ awọn ti ọrọ kan lati gbe ifẹ ilu wọn siwaju dipo ifẹ ara wọn.

O kọminu pe Naijiria n koju ipenija aabo, airajaja eto ọrọ aje ati aini igboya ninu eto iṣejọba mọ.

'A fe fi igbesẹ yii gba orilẹ ede Naijiria kalẹ lọwọ iṣejọba to wa lode'

Sẹnetọ David Mark ni tirẹ juwe apero naa bii igbesẹ lati gba orilẹ ede Naijiria kalẹ lọwọ awọn iṣejọba to wa lode.

O tẹmpẹlẹmọ pe ko si ẹgbẹ alatako kan to le da ijọba gba lọwọ iṣejọba to wa lode, to si ni asiko ti to lati ṣe atunkọ bi awọn ẹgbẹ oṣelu ṣe n darapọ mọ ara wọn ni Naijiria.

Ninu atẹjade ti wọn fi lede lẹyin ipade naa ni wọn ti fidi rẹ mulẹ pe awọn ẹgbẹ alatako maa dije si gbogbo ipo nibi eto idibo gbogbogbo ọdun to n bọ ati pe awọn ko ni gba ki ijọba fi ẹgbẹ oṣelu kan lelẹ.

Bakan naa ni wọn sọ pe awọn ko ni gba ko nẹ pe oludije kan ṣoṣo lo dije dupo aarẹ, bi wọn ṣe sọ pe awọn ọmọ Naijiria lẹtọọ lati ni anfaani si oludije to pọ, eyi ti wọn ti maa yan ẹni to ba wu wọn nini rẹ.

Yatọ si oludije, awọn eeyan naa tun kọminu lori bi eto idibo ṣe maa lọ ni irọwọrọsẹ laini ẹja nnbakan ninu.

Wọn ni awọn ko ni igboya ninu alaga ajọ to n ri si eto idibo Naijiria, INEC, Ọjọgbọn Joash Amupitan, ti wọb si ni ki ijọba yọ ọ nipo ko to di asiko ibo.

Wọn ni awọn ko ni igbagbọ pe o maa ṣeto ibo to mọyan lori lọdun 2027.

Apero naa tun rọ awọn aṣofin lati ṣe atungbeyẹwo ofin to de eto idibo lati fi aaye gba eto idibo abẹnu di ipari oṣu Keje.

Bakan naa ni wọn tun pe fun itusilẹ awọn oloṣelu to wa ni ahamọ ijọba fawọn ẹṣẹ ti wọn le maa jẹjọ lati ile le lori, bi wọn ṣe oe fun ibọwọ fun ẹtọ ọmọniyan wọn.

Apero naa pari pẹlu bi awọn ẹgbẹ oṣelu alatako lọkan-o-jọkan ṣe kede ifarajin wọn lati ṣiṣẹ pọ lojuna ati ri pe ifọwọsowọpọ wa laaarin wọn ṣaaju eto idibo 2027.

Ipade ọhun ni awọn eekan ninu ẹgbẹ oṣelu alatako bii PDP ati ADC kopa nibẹ.

Lara awọn to kopa nibẹ ni igbakeji aarẹ tẹlẹ ri, Atiku Abubakar, Peter Obi, Rabiu Kwankwaso, Rauf Aregbesola, Rotimi Amaechi, Pat Utomi, Jerry Gana ati bẹẹ bẹẹ lọ.