You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ààrẹ Omar Guelleh tún wọlé sáà kẹfà ní Djibouti, lẹ́yìn ọdún 27 tó ti wà nípò
Aarẹ orilẹede Djibouti, Ismail Omar Guelleh, ti wọle fun igba kẹfa gẹgẹ bii aarẹ orilẹede naa.
Eyi di mimọ lọjọ Abamẹta, lẹyin ti idibo waye lọjọ Ẹti, ọjọ kẹwaa, oṣu Kẹrin 2026.
Ibo ti ìdá rẹ jẹ 97.8% ni Guelleh ni, yoo si maa dari Djibouti lọ gẹgẹ bo ṣe ti n ba a bọ lati ọdun 1999.
Mohamed Farah Samatar ni oludije to ba Aarẹ Guelleh, ẹni ọdun mejidinlọgọrin (78) dupo. Oun ni ibo ida 2.19%.
Ọpọ awọn to yẹ ki wọn jọ dupo aarẹ naa ni ko ba wọn kopa, awijare wọn si ni pe ko si akoyawo ninu idibo orilẹede naa mọ.
Guelleh to ti loun ko ni I dije lọdun yii tẹlẹ, yi ipinnu rẹ pada lẹyin ti wọn ṣe atunṣe si ọjọ ori aarẹ kuro ni ọdun marundinlọgọrin (75) loṣu Kọkanla.
Ta a ni Aarẹ Omar Guelleh?
Ismail Omar Guelleh ni aarẹ keji ti orilẹede Djibouti ni.
Ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kọkanla ọdun 1947 ni wọn bi I.
Guelleh ni aarẹ adiboyan akọkọ ni Djibouti.
Ibatan rẹ, Hassan Gouled lo jẹ aarẹ akọkọ lẹyin ijijagbara lati gba ominira lọwọ France. Oun lo fa Guelleh kalẹ lẹyin toun naa ti lo ọdun mejilelogun nipo aarẹ.
Wọn tun Guelleh yan sipo pada ni 2005, 2011, 2016 , 2021 ati 2026 yii.
Ọpọ igba ni awọn alatako ti bu ẹnu atẹ lu Aarẹ Guelleh, wọn ni ijọba onikumọ apaṣẹwaa lo n ṣe.
Lati ọdun 2016 ni awọn olori ẹgbẹ alatako yoku ko ti ba a dupo naa mọ.
Wọn fi Omar Guelleh silẹ pẹlu alaye pe ko si otitọ ninu bawọn ṣe n ba a dije.
Ninu eyi to tun jawe olubori yii, ohun kan ti ipolongo rẹ da le lori ni pe alaafia wa ni Djibouti lasiko ti rogbodiyan n ṣẹlẹ lawọn ẹkùn miran, ati ni Middle East.
Awọn alaṣẹ sọ pe oludibo ti iye wọn to ida ọgọrin, (80%) ti wọn si fi orukọ silẹ lo dibo fun Guelleh.
Guelleh naa ṣajọyọ aṣeyọri rẹ tuntun yii, o ni aṣeyọri gbogbo eeyan Djibouti ni.
Ileeṣẹ to n ri si ọrọ abẹle ni Djibouti lo kede esi idibo tuntun yii, amọ o ṣi nilo ki awọn adajọ buwọ lu u ki wọn too bura fun Aarẹ Omar Guelleh sipo ti yoo ti maa tẹsiwaju naa.
Ọdun marun-un gbako ni yoo tun fi tukọ orilẹede naa labẹ ofin Djibouti, mẹfa tilẹ ni tẹlẹ, ọdun 2010 ni ile aṣofin ibẹ sọ ọ di marun-un.
Nibo ni Djibouti?
Ilu kekere kan ni Djibouti.
O wa ni Ariwa Ila Oorun, o paala pẹlu Eritrea lapa Ariwa, Ethiopia lapa Iwọ Oorun ati Guusu, Somalia ni Guusu Ila Oorun ati Okun pupa /Gulf of Adem.
Olu ilu Djibouti ni wọn n pe ni Djibouti City, ibẹ si jẹ ọna ti ọpọ ọkọ oju omi nla n gba kọja.
Ilẹ okuta ni Djibouti, aṣálẹ̀ diẹ si ni.
Ibẹ ni adagun odo Assal wa, nibi to lọ silẹ ju l'Afica.
Ohun pataki nipa Djibouti ni pe o jẹ oju ọna òkun fun awọn ọkọ, o si tun jẹ ibudo fun awọn ologun USA, France, China ati Japan, latari ibi ti ori da Djibouti si.
Djibouti gba Bab el-Mandeb Strait, o si jẹ ọna fun oju opo Suez Canal, ọkan lara awọn ọna ti awọn ọkọ nla nla maa n gba kọja lagbaaye.
Ẹya meji pataki to wa nibẹ ni Somali ati Afar.
Ida mẹsan-an ninu mẹwaa awọn eeyan Djibouti ni wọn jẹ Musulumi.
Djibouti ni nnkan alumọni diẹ, ọgbin ko si fi gbogbo ara waye nibẹ nitori iru ilẹ ti wọn ni.
Airiṣẹṣe pọ ni Djibouti, gbese ti wọn jẹ ilẹ okeere wa pẹlu, bẹẹ ni aito owo ti wọn la kalẹ fun iṣuna ọdun maa n waye nibẹ.
Ẹka ileeṣẹ ni wọn da oju kọ ju lati maa fi ṣe ọrọ̀.