Ẹni tó bá ní kò sí ayé, ayé wà o, ohun tó jẹ mọ́ ọ̀rọ̀ ẹ̀mí wà nínú iṣẹ́ tíátà - Tosin Olaniyan

Ẹni tó bá ní kò sí ayé, ayé wà o, ohun tó jẹ mọ́ ọ̀rọ̀ ẹ̀mí wà nínú iṣẹ́ tíátà - Tosin Olaniyan

Odu ni gbajumọ osere tiata, Oluwatosin Olaniyan jẹ lagbo ere tiata, kii se aimọ fawọn oloko.

Oluwatosin Olaniyan ti ọpọ eeyan tun mọ si 'Idaamu Industry' ni awọn eeyan mọ si alawada laarin awọn akẹẹgbẹ rẹ.

Se awọn awada ti Oluwatosin maa n bawọn agba osere se ni ka wo ni tabi awọn ipo to kanka ti wn maa n fun se ninu ere tiata.

BBC News Yoruba fọrọ wa Oluwatosin Olaniyan wo nipa igbe aye rẹ, ero rẹ nipa ipo ti ere tiata wa atawọn ọrọ miran.

"Ti eeyan ba n sọkun ninu sinima, ko tumọ si pe ẹlẹkun ni loju aye, Mide Martins, kii sọrọ loju aye, o jẹ oniwa tutu bii adaba"

Nigba to n ba BBC News Yoruba sọrọ, Idaamu Industry ni awọn eeyan to n wo ere tiata lo maa n ro pe bawọn osere se maa n se loju aye, naa ni wọn n se ninu ere itage.

Amọ o ni eyi ko ri bẹẹ tori pe ti eeyan ba n sọkun ninu sinima, ko tumọ si pe ẹlẹkun ni loju aye.

"Bakan naa, tori pe osere kan n se iwa daadaa ninu sinima ko tumọ si pe eeyan daadaa ni loju aye.

Ẹ wo iru Mide Martins, kii sọrọ loju aye, o jẹ oniwa tutu bii adaba.

Bi awọn eeyan miran ba si ni ki n wa se bi mo se maa n se ninu ere fun wọn loju aye, n ko le se bẹẹ.

Amọ ti eeyan kan ba ba mi pade lasiko ti mo n se ere tabi awada, ko tumọ si pe bi mo se n se ni ojoojumọ ree."

"Ohun to jẹ mọ ẹmi wa ninu isẹ wa, ẹni to ba ni ko si aye, haa, aye wa"

Tosin Olaniyan fikun pe kii se ere tiata lo maa n kọ awọn eeyan ni iwa ti wọn yoo hu, amọ abimọ iwa onikaluku ni yoo jẹ jade.

"Onikaluku lo ni iwa tinu rẹ tẹlẹ amọ ti wọn yoo maa lọ mọ ere tiata.

Igba miran ti adari ere maa sọ pe bayi ni mo se fẹ ko ri, ti o ko ba fẹ ri bẹẹ, o ni se ipa yẹn ni.

Nigba to n sọrọ lori ibeere pe se lootọ ni pe teeyan ba bu ajẹ ninu ere, o se e se ki wọn daamu rẹ loju aye, Tosin ni awọn ohun to jọ mọ ise ẹmi wa ninu isẹ tiata.

"Ohun to jẹ mọ ẹmi wa ninu isẹ wa, ẹni to ba ni ko si aye, haa, aye wa, eeyan ti ko ba wa fun ẹ, ma lọ tọ wọn."

"Obinrin miran to ba ya ọlẹ, ti ko le ra pata lai si iranwọ awọn ọkunrin, lo ma n ro pe owo ni gbogbo nnkan"

Nigba to n sọrọ nipa ọrọ ifẹ, Tosin Olaniyan ni oun fẹran ki oun ati ọjọ oun dijọ wa amọ lọjọ ọla, oun ko mọ nnkan to le sẹlẹ.

"Mo jẹ ajihinrere nipa ifẹ, mo si jẹ ẹni to jara mọ isẹ, ki Ọlọrun sa maa gba fun mi, ki n lowo temi lọwọ.

Nnnkan ti ọkọ mi ba ni, ni ko fi ran mi lọwọ, ko ma ya akurẹtẹ sugbọn ifẹ se koko nile aye.

Obinrin miran to ba ya ọlẹ, ti ko le ra pata lai si iranwọ awọn ọkunrin lo ma n ro pe owo ni gbogbo nnkan.

Amọ ko dara ki ẹni to talaka meji fẹra, ko dara."

Itan igbe aye Tosin Olaniyan

Ọjọ kẹfa osu Kẹfa ọdun 1993, eyiun ọdun mẹtalelọgbọn sẹyin ni wọn bi gbajumọ osere tiata, Janet Oluwatosin Olaniyan sile aye.

Oluwatosin, ti ọpọ eeyan tun maa n pe ni ‘Idaamu Industry‘ jẹ osere tiata ati alakoso ere sinima.

Ere sinima kan ti wọn n pe ni Big Mummy lo sọ Tosin di gbajumọ lagbo tiata.

Ileesẹ ti wọn ti n kọ ere tiata ti gbajugbaja osere nni, Odunlade Adekola da silẹ nilu Abeokuta ni Tosin ti kọsẹ ere sise.

Awọn ipo to nii se pẹlu awada si ni Tosin maa n se eyi to maa n da awọn eeyan laraya.

Bakan naa, Tosin tun maa n se ere kekeke pẹlu awọn agba akẹẹgbẹ rẹ lagbo tiata eyi to maa n gbe soju opo ayelujara rẹ.

Latipasẹ awada naa si ni wọn ti fun ni orukọ inagijẹ ,9 Idaamu Industry’.

Lakota, Tosin ti kopa ninu ere sinima to le ni ogun lati igba to ti de agbo tiata.

Diẹ lara awọn sinima naa ni wọnyii:

Amookun

Empty

Amerah

Eniolorunda

Ota Aje

Mama Nla

Iremide

Yeye Alara

Big Mummy

Tipa Tipa

Eni Ola

Alani Pomolekun

Kara

Saamu Alajo

Irawo Osan