Àṣírí tú lórí bí ọwọ́ ọlọ́páà ṣe tẹ afurasí 33 tó kọlu ṣọ́ọ̀ṣì CAC Oke Isegun, Eruku ní Kwara

Ọpọ awọn afurasi agbebọn duro, wọn so ibọn mọra

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kwara ti fi ṣikun ofin mu awọn afurasi ti wọn kọlu ile ijọsin CAC Oke Isegun, niluu Eruku, nipinlẹ naa ninu oṣu Kọkanla ọdun 2025.

Asiko ti awọn olujọsin naa jọsin lọwọ ni irọlẹ lawọn agbesunmọmi naa ya bo ile ijọsin ọhun, wọn ṣekupa eeyan meji ki wọn to ji awọn to le ni ọgbọn lọ nibẹ.

Olusọ agutan Taye Rotimi to jẹ igbakeji pasitọ ijọ naa sọ fun BBC pe oun n fẹ ki awọn agbesunmọmi naa foju wina ofin ijọba.

O ni "Ilu to ni ofin ni orilẹede wa. Ti ijọba ba le mu wọn, ẹ jẹ ki ofin ṣiṣẹ rẹ. Inu mi dun pe ọwọ ti tẹ wọn."

Pasitọ naa ṣalaye pe iyawo oun wa lara awọn ti wọn ji gbe ninu ikọlu naa amọ wọn pada tu silẹ lẹyin ti ijọba dundura pẹlu awọn agbesunmọmi ọhun.

Ijọba ni ajọṣepọ awọn agbofinro lati ipinlẹ Kwara ati Kogi lo mu ko ṣeeṣe lati mu awọn ọdaran naa.

Ọlọpaa sọ ninu atẹjade kan pe afurasi mẹtalelọgbọn lọwọ awọn tẹ lori ikọlu ile ijọsin naa.

A gbọ pe lara ẹsun ti wọn fi kan awọn afurasi ọhun ni ẹsun iditẹ lati hu iwa ọdaran, ijinigbe, idigunjale, nigba ti wọn fi ẹsun jiji maluu ẹlomiran ko, nini ohun ija oloro lọwọ lai kii ṣe agbofinro ati iwa igbesunmọmi kan awọn mii ninu wọn.

Ijọba Naijiria ni oun ti bẹrẹ iṣẹ lati maa kapa eto abo to mẹhẹ.

Ti ẹ ko ba gbabe, lọsẹ to kọja ni ile ẹjọ ṣedajọ awọn afurasri ti iye wọn to 400 ti wọn n ṣatilẹyin fun oniruru ẹgbẹ agbesunmọmi bii Boko Haram ati Iswap ni Naijiria.

Inu wa dun si bi ọwọ ṣe tẹ awọn agbesunmọmi naa - Ọwa Eruku

Ọwa ti ilu Eruku, Ọba Busari Ayinde Olanrewaju ti ṣalaye fun BBC pe inu oun bi ọlọpaa ṣe mu awọn kọlọrọsi ẹda naa.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, lọpọ igba ti irufẹ iṣẹlẹ bẹẹ ba waye, awọn araalu kii gbọ nnkankan nipa rẹ titi ti ọrọ ọhun yoo fi kuregbe-kuregbe.

Amọ o ni iwuri lo jẹ fun oun ati fun gbogbo eeyan ilu Eruku pe ọwọ tẹ awọn afurasi laarin oṣu diẹ ti wọn kọlu ile ijọsin Eruku.

O wa fikun pe lẹyin ikọlu si ṣọọsi naa ni awọn agbofinro ti bẹrẹ si n paara agbegbe ọhun lati pese aabo to peye fun awọn eeyan oun loorekoore.