Àlàyé rèé lórí ìdí tí ààrẹ Trump àti Pope Leo XIV ṣe ń tahùn síra wọn

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 7

Poopu ijọ Aguda, Pope Leo XIV, ti sọ pe oun ko ni dakẹ nipa sisọrọ tako ogun to n lọ lọwọ ni Iran, lẹyin ti Aarẹ Donald Trump koro oju si iha ti Pope kọ si ogun naa.

Ṣaaju ni Trump sọ pe Poopu ko ṣọkan akin lori ọrọ iwa ọdaran ati ilana eto ijọba Amẹrika nipa ilẹ okeere.

Aarẹ Amẹrika to sọrọ yii loju opo Truth Social rẹ lori X, sọ pe oun ko gba ti Poopu Leo rara.

Poopu sọ fawọn akọroyin nigba to n lọ si orilẹede Algeria wi pe oun ko ni ṣe arohun-bọhun pẹlu Trump, amọ, oun ko ni dakẹ lati maa sọrọ tako ogun.

Lati igba ti ogun naa ti bẹrẹ ni Poopu ti tako ogun ti Amẹrika ati Israel gbe ko Iran.

Papa mimọ tun ṣapejuwe ọrọ idunkokomọni ti Trump sọ pe oun yoo sọ Iran di ahoro gẹgẹ bi ọrọ ko bakun gbe.

Lẹyin naa lo rọ Trump lati wa ọna ti ogun naa yoo fi pari.

Ko saba wọpọ ki Poope sọrọ nipa nnkan tawọn adari orilẹede agbaye ba sọ.

O le ni aadọrin miliọnu ọmọ ijọ Aguda to wa lorilẹede Amẹrika, eyi to jẹ ida 20% eeyan to wa l'Amẹrika.

Ọrọ Trump yii jẹ jade lasiko ti Poopu gunle abẹwo ọlọjọ mọkanla si ilẹ Afirika.

Igba keji ree ti Poopu yoo gunle irinajo bayii lati igba to ti dori oye lọdun 2025.

'''Ti mi o ba jẹ aarẹ Amẹrika ni, Leo ko le di Poopu''

Aarẹ Trump sọ loju opo ayelujara rẹ lọjọ Aiku pe Poopu ni lati tun ero ara rẹ pa tori ko ṣọkan akin nipa ọrọ nnkan ija oloro.

Nnkan ti Trump n sọ nipa rẹ ni ọrọ Iran to n gbero lati ko ohun ija oloro jọ.

O ni eyi wa lara awọn nnkan to mu ki Amẹrika ati Israel gbogun ti Iran

Trump tun woye wi pe Poopu lanfaani lati gori oye Papa Mimọ nitori pe o jẹ ọmọ Amẹrika.

''Ti mi o ba jẹ aarẹ Amẹrika ni, Leo ko le di Poopu.''

''Mi o ro pe o n ṣe daadaa, o dabi ẹni pe o fẹran iwa ọdaran.

O fi aye gba gbogbo eeyan, o jẹ ẹnikan ti ko gbagbọ ninu dida iwa ibajẹ duro, o tun jẹ ẹnikan to n fi ọrọ orilẹede to n ko ohun ija oloro jọ ṣere, ki wọn le fi pa gbogbo eye run,'' Trump lo sọ bẹẹ.

Mi o fẹ maa ni itakurọsọ pẹlu Trump - Pope

Poopu Leo XIV ni ''mi o fẹ maa ni itakurọsọ pẹlu Trump.

Mo maa tẹsiwaju lati maa sọrọ tako ogun lati wa laafia ati ijiroro laarin awọn orilẹede agbaye ki a le wa ojutuu si iṣoro to wa nilẹ.

Ogunlọgọ eeyan ni iṣẹ n ba finra lonii, ọpọ eeyan ti ko mọwọ mẹsẹ lo ti ku lonii.

Mo gbagbọ pe ẹnikan gbọdọ dide lati wa ọna abayọ si gbogbo nnkan to n ṣẹlẹ.''

Ọpọ eeyan papaa julọ lati inu ijọ Aguda lo ti bẹnu ẹtẹ lu ọrọ ti Trump sọ nipa Poopu.

Onwoye kan tiẹ sọ pe Adolf Hitler gan an ko tako Poopu bi Trump ṣe tako Pope Leo.

Ni ọpọ igba ni Poopu sọrọ nipa ogun to n lọ ni Iran ati ẹkun Middle East, Poopu si ti rọ awọn orilẹede tọrọ kan wi pe ki wọn jẹ ki ogun o sinmi.

Poopu tun bu ẹnu ẹtẹ lu bi ijọba Trump ṣe huwa ti ko dara sawọn ọmọ orilẹede mii to wa l'Amẹrika.

Ọpọ lo ti sọ pe Poopu Leo tẹsiwaju pẹlu didaabo bo ẹtọ ọmọniyan eyi ti Pope Francis ṣe nigba aye rẹ.

Ti ẹ o ba gbagbe, Pope Francis lo sọ pe Trump kii ṣe ọmọlẹyin Kristi pẹlu awọn ọrọ kobakun gbe to n sọ sawọn ọmọ orilẹede mii to wa l'Amẹrika lasiko ipolongo ibo aarẹ lọdun 2016.

Trump naa da a pada fun Pope Francis wi pe alabuku ni Poopu.

Trump kéde ìgbésẹ̀ tó kàn lẹ́yìn tí ìjíròrò pẹ̀lú Iran forí sánpọ́n

Lẹ́yìn ìjíròrò láàárín Amẹ́ríkà àti Iran forí sánpọ́n ní ọjọ́ Àbámẹ́ta, Ààrẹ Amẹ́ríkà, Donald Trump ti kéde ìgbésẹ̀ míì láti fi wá ojútùú sí àwọn ọ̀nà tí ogun fi máa parí.

Trump, nínú àtẹ̀jáde tó fi sórí ìkànnì Truth Social rẹ̀ sọ pé ìjọba máa fi àwọn ológun ojú omi máa di Iran pa.

Amẹ́ríkà ní àwọn kò ní gbà kí ọkọ̀ ojú omi Iran gbé epo jáde ní orílẹ̀ èdè náà, tí wọ́n kò bá ṣí Strait of Hormuz.

Ó kọ sójú òpó náà pé " kò sí ẹni tó máa ọ̀nà tí kò bá òfin mú tó máa gba orí omi láì farapa.

Ó ní Amẹ́ríkà máa bẹ̀rẹ̀ sí ní wà kùsà ní Strait of Hormuz láti ri dájú pé gbogbo àwọn ọkọ̀ ojú omi tó ní ìbáṣe pẹ̀lú Amẹ́ríkà rí ọ̀nà náà gbà kọjá.

Trump ní àwọn ọmọ ogun Amẹ́ríkà ti setán láti bẹ̀rẹ̀ ìkọlù padà sí Iran tí àsìkò bá tó

Trump ní àwọn ọmọ ogun Amẹ́ríkà ni wọ́n ti gbáradì, tí wọ́n sì ṣetán láti bẹ̀rẹ̀ ìkọlù padà sí Iran tí àsìkò bá tó.

Ó fi kun pé bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ìtẹ̀síwájú kan wà, ó ní Iran kọ̀ láti fẹnukò pẹ̀lú Amẹ́ríkà láti dáwọ́ ṣíṣe àdó olóró "nuclear weapon" dúró.

Àmọ́ ọ̀rọ̀ tí Trump sọ yìí tako ohun tí òṣìṣẹ́ Amẹ́ríkà kan tó wà níbi ìjíròrò tí igbákejì Ààrẹ Amẹ́ríkà, JD Vance ṣe pẹ̀lú àwọn asojú Iran ní Islamabad, Pakistan, ẹni tó sọ pé nǹkan ni wọ́n kò fẹnukò lé lórí, tó fi mọ́ àkóso Strait of Hormuz.

Ìdúnkokò Trump yìí ló ń jẹ́ ìpèníjà fun Amẹ́ríkà èyí tó le mú kí àwọn ọmọ ogun Iran ṣe ìkọlù sí wọn.

Onírúurú ìbéèrè tó ti ń jẹyọ ni pé báwo ni àwọn orílẹ̀ èdè bíi China, tí wọ́n ń gbáralé epo rọ̀bì Iran ṣe máa gba ìròyìn yìí? Ṣé ó máa dènà bí owó ṣe ń wọlé fún Iran àti pé ṣé ó máa tún mú kí owó epo rọ̀bì lọ sókè lọ́jà àgbáyé?

Ní alẹ́ ọjọ́ Àìkú ni iléeṣẹ́ ológun Amẹ́ríkà tún kéde pé ìgbésẹ̀ Amẹ́ríkà náà máa dènà àwọn ọkọ̀ láti gbé epo wọ Iran tàbí gbé epo jáde níbẹ̀.

Aṣòfin Mike Turner ti Ohio sọ pé dídí ọ̀nà mọ́ Iran máa mú kí ìfẹnukò wáyé lórí Strait of Hormuz

Sẹ́nétọ̀ Mark Wagner ti Virginia sọ fún iléeṣẹ́ ìròyìn CNN pé òun kò mọ bí dídí ọ̀nà mọ́ Iran ṣe máa mú àwọn aláṣẹ Iran láti ṣí Strait of Hormuz.

Àmọ́ aṣòfin Mike Turner ti Ohio sọ pé dídí ọ̀nà náà máa jẹ́ ìgbésẹ̀ láti mú kí ìfẹnukò wáyé lórí Strait of Hormuz.

Ó ní ọ̀rọ̀ tí Trump sọ nípa pé àwọn kò ní jẹ́ kí Iran jẹ́ alákòso tó ń ṣàmójútó àwọn tó ń gba ọ̀nà náà kọjá túmọ̀ sí pé, ó ń pe àwọn alábàáṣepọ̀ Amẹ́ríkà láti dá sí ọ̀rọ̀ náà nítorí ó nílò àmójútó.

Ṣáájú kí Amẹ́ríkà àti Iran tó fẹnukò láti dáwọ́ ogun dúró fún ìgbà kan ná, Trump ni ó sọ pé òun máa ṣe ìkọlù sáwọn ohun amáyédẹ̀rùn Iran.

Ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn, pàápàá àwọn ara Amẹ́ríkà, ló gbàgbọ́ pé ìdí tí Amẹ́ríkà fi ń gbógunti Iran, tó fi mọ́ ṣíṣí Strait of Hormuz, fífún àwọn èèyàn Iran ní àǹfààní láti gbé ìgbé ayé tó wù wọ́n àti fífi òpin sí ṣíṣe àdó olóró nuclear weapon ni kò wá sí ìmúṣẹ.