Wo ọ̀pọ̀ ọ̀rọ̀ tó wà nídìí fídíò ọ̀mùtí ọlọ́pàá tó gbòde

A lukoro ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria ti fesi lori ọlọpaa ọmuti kan ti fidio rẹ gbori ayelujara, to ti muti yo lai le da rin mọ.

M uyiwa Adejobi, to jẹ alukoro agba nileeṣẹ ọlọpaa sọ pe awọn ti gbe igbesẹ ti o yẹ, tawọn si ti ba ọlọpaa to ṣe aṣemaṣe yii wi ni ibamu pẹlu ofin ileeṣẹ ọlọpaa.

A dejobi sọ pe lọdun 2020 ni ọlọpaa yii mu ọti yo ninu fidio tawọn eeyan ṣẹṣẹ wa n pin kaakiri bayii.

O ni nigba naa lọhun ti fidio yii jade, awọn gbe igbesẹ to yẹ lati ri pe Insipẹkọtọ naa koju ibawi ni ilana to yẹ.

"Iyalẹnu ni bawọn eeyan ṣe n gbe fidio yii sita lai ṣe alaye ohun to ṣẹlẹ gan"

G ẹgẹ bi Adejobi ṣe wi, iyọniniṣẹ ati igbesẹ ibawi to yẹ fun ọlọpaa yii ni wọn ti ṣe lati igba ti fidio yi kọkọ waye.

M uyiwa sọ pe o jẹ iyalẹnu bi awọn eeyan ṣe wa n gbe fidio yii sita lai ṣe alaye ẹkunrẹrẹ nipa ohun to ṣẹlẹ gan.

O ni ileeṣẹ ọlọpaa ko ni ye ṣe iṣẹ wọn bo ṣe yẹ ni gbogbo igba ti wọn ba wa lẹnu iṣẹ ati igba ti wọn ko ba ṣi lẹnu iṣẹ naa.