Amẹrika àti Iran fẹnukò láti dáwọ́ ogun dúró fún ọ̀sẹ̀ méjì

Oríṣun àwòrán, AFP via Getty Images
- Author, Kelly Ng
- Reporting from, Singapore
- Author, Khashayar Joneidi
- Role, BBC Persian
- Reporting from, Washington
- Author, Daniel De Simone
- Reporting from, Jerusalem
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2
Ijọba Iran ati Amẹrika ti fẹnuko lori adehun lati dawọ ogun duro fun ọsẹ meji, laarin ọsẹ meji naa ni wọn yoo ṣi oju ọna Strait of Hormuz.
Igbesẹ yii lo n waye lẹyin oṣu kan o le ti ijọba Amẹrika ati Israel bẹrẹ ogun si Iran ati lẹyin wakati diẹ ti Aarẹ Trump kede pe oun yoo pa gbogbo awọn eeyan ilẹ Iran run.
Olootu ijọba Pakistan, Shehbaz Sharif to n ṣiṣẹ alarena laarin ijọba mejeji sọ pe lẹsẹkẹsẹ ni adehun naa yoo bẹrẹ si n mulẹ.
Iwọnyii ni ohun ti a mọ nipa adehun ọhun.
Ki ni ijọba Amẹrika ati Iran sọ?
Trump ni oun yoo dawọ sisọ ado oloro si Iran duro fun ọsẹ meji ti Iran ba gba lati ṣi oju ọna Strait of Hormuz.
Ninu atẹjade kan loju opo ayelujara rẹ, Trumo ti kọkọ kilọ pe oun yoo pa Iran run lalẹ ọjọ kan ṣoṣo.
Amọ ajọ UN ati poopu ijọ Aguda, Pope Leo XIV bu ẹnu atẹ lu ọrọ naa.
Lẹyin naa ni Trump tun kede pe ijọba oun yoo maa ṣiṣẹ papọ pẹlu Iran lati wọgile awọn iya kan to fi n jẹ ilẹ naa nipa owo ori atawọn nnkan mii.
O tun fi kun pe Amẹrika yoo maa gba owo ori to pọ lọwọ awọn orilẹede to ba n ta nnkan ija ogun fun Iran
Ni ti Iran, o ni oun yoo gba awọn ọkọ oju omi to n gbe omi kọja loju ọna Hormuz lati maa kọja lai kogun ja wọn.
O tun kede pe oun yoo dawọ ogun duro pẹlu awọn orilẹede bii Iraq, Lebanon ati Yemen, ati pe oun ko ni gbiyanju lati ni ohun ijan oloro nuclear.
Ki ni Israel sọ?
Israel ni oun n kọju ija si awọn ado oloro ti Iran ju si oun lati oju ofurufu, bẹẹ lo si n funrere rẹ fun awọn eeyan rẹ.
Oniruru iro ado oloro lo n dun ni Jerusalem lalẹ ọjọ Iṣẹgun.
Lẹyin wakati diẹ ti wọn fidi adehun jogun-o-omi naa mulẹ, olootu ijọba Israel, Benjamin Netanyahu ni "Israel faramọ igbesẹ Amẹrika lati dawọ ogun duro fun ọsẹ meji niwọn igba ti Iran ba ṣi oju ọna ti wọn n ko epo rọbi gba kọja.
O fi kun pe adehun jogun-o-ominaa ko kan Lebanon.
A ko le sọ boya Trump bun Netanyahu gbọ ṣaaju igbesẹ jogun-o-omi naa.
Ki ni igbesẹ to kan bayii?
Ijọba Pakistan, to ti n ṣe alarena laarin awọn mejeji lati ibẹrẹ ogun naa ti ke si awọn aṣoju orilẹede mejeji lati pade ni Islamabad lọjọ Ẹti fun itẹsiwaju ijiroro wọn.
Akọwe ijọba Amẹrika, Karoline Leavitt sọ pe lootọ ni ijoro n lọ lọwọ amọ o di igba ti Aarẹ Trump ba buwọlu ọrọ naa ki igbesẹ kankan to waye lori rẹ.
Bo tilẹ jẹ pe jogun-o-omi wa lode, o da bii pe ija ṣi n lọ lọwọ gẹgẹ bi Kuwait ṣe sọ pe Iran ṣi kọlu awọn laarọ Ọjọbọ.
Ẹwẹ, awọn olori orilẹede lagbaye ti sọ pe awọn fọwọ si adehun jogun-o-omi naa bayii.























