Àwọn ọlọ́pàá tó ti fẹ̀yìn tì lẹ́nu iṣẹ́ ṣèwọ́de l'Abuja lórí owó ìfẹ̀yìntì sísan, gbégi dínà ilé-iṣẹ́ Ààrẹ

Oríṣun àwòrán, @DokunOjomo/X
Awọn ọlọpaa to ti fẹyin ti lẹnu iṣẹ ṣe ifẹhonuhan niluu Abuja eyi ti wọn fi kepe Aarẹ Bola Tinubu wi pe ko buwọlu abadofin ọdun 2025 lori ilana tuntun fun sisan owo awọn ọlọpaa to ti fẹyin ti.
Awọn ọlọpaa to fẹyin ti ọhun gbegi dina ileeṣẹ aarẹ lati ri pe o gbọ ẹbẹ wọn.
Loṣu Kejila ọdun 2025 ni ile aṣofin agba l'Abuja buwọlu abadofin ọhun.
Awọn olufẹhonuhan naa n fẹ ki ijọba apapọ gbe awọn oṣiṣẹ fẹyin ti ọlọpaa kuro ninu eto owo ifẹyinti ti wọn wa bayii eyi to n jẹ ''Contributory Pension Scheme'' ki ijọba si gbe wọn sori ilana ''Police Exit.''
Ninu oorun lawọn ọlọpaa to ti fẹyin ti naa n ṣe ifẹhonuhan l'Abuja, koda wọn gba iwaju olu ileeṣẹ ọlọpaa kọja.
Oniruuru iwe ilewọ ni wọn mu dani to fi mọ asia orilẹede Naijiria ati asia ileeṣẹ ọlọpaa.
Bi awọn oluwọde kan ti n kọrin lawọn mii sun silẹ lati le fẹhonu han.
Awọn oluwọde naa ti CSP Raphael Irowainu dari wọn sọ pe ilana ti ijọba fi n san owo ifẹyinti fawọn ọlọpaa to ti kuro lẹnu iṣẹ ko ba ofin mu.
Nnkan ti awọn ọlọpaa to ti fẹyin ti lẹnu iṣẹ naa n beere fun ni pe ki Aarẹ Tinubu buwọlu abadofin eto owo ifẹyinti awọn ọlọpaa ki o le di ofin.
Lati ọjọ kérindinlogun oṣu Kéta ọdun yii ni abadofin naa ti de iwaju aarẹ fun ibuwọlu.
Wọn ni ti Tinubu ba buwọlu ofin naa lawọn ọlọpaa to ti fẹyin ti yoo to kuro loko ẹru.
Awọn iyawo atawọn ọmọ awọn ọlọpaa naa tẹle wọn lọ sibi ti wọn ti ṣe ifẹhionuhan ọhun.
Pabo ni igbiyanju awọn agbofinro to fẹ di wọn lọwọ lati ma le ṣe iwọde wọn jasi.
Bi awọn kan ti n kọrin lawọn mii ninu wọn sun silẹ lati le fẹhonu han.
Nigba to n bawọn akọroyin sọrọ, adari awọn oluwọde naa, CSP Irowainu sọ pe gbogbo awọn ajọ oṣiṣẹ eleto aabo yooku ni wọn ko lo ilana owo ifẹyinti ti ijọba n lo fawọn ọlọpaa mọ.
Irowainu ni ''ohun ti a n beere ni pe ki Aarẹ Tinubu bawa buwọlu ilana owo ifẹyinti sisan fawọn ọlọpaa to ti fẹyin ti lẹnu iṣẹ.''

























