Coronavirus treatments Nigeria : Gómìnà ìpínlẹ̀ Abia, Okezie Ikpeazu ti fara kásá àrùn Covid-19

Abia

Oríṣun àwòrán, Abia state Government

Ijọba ipinlẹ Abia ti kede pe Gomina ipinlẹ naa, Okezie Ikpeazu, ti lugbadi arun Coronavirus.

Gomina ọhun ni gomina kẹrin ti yoo fara kasa arun naa lati igba ti arun naa ti wọ orilẹ-ede Naijiria loṣu keji ọdun 2020.

Agbẹnuṣo Gomina ọhun, Onyebuchi Ememanka to fidi iroyin naa mulẹ fun BBC sọ pe gomina ọhun ti wa ni igbele, ati pe awọn akọṣẹmọṣẹ dọkita ti n ṣe itọju rẹ.

Ememanka ni ki awọn eeyan ipinlẹ naa ma foya, nitori gomina naa kii ṣe gomina akọkọ ti yoo ko arun Coronavirus ni Naijiria.

Ṣaaju ni kọmiṣọna ọrọ to n lọ ni ipinlẹ ọhun, John Okiyi Kalu ti kọ sọ ninu atẹjade kan pe gomina naa ti fun igabkeji rẹ ni aṣẹ lati dele dee ki esi ayẹwo arun naa to ja

Ọgbọn ọjọ, oṣu karun un ọdun 2020 ni gomina ọhun gba lati ṣe ayẹwo, to si paṣẹ pe ki gbogbo awọn to n ba ṣe ijọba ṣe bẹ.

Ọjọ keji oṣu Kẹfa ni esi ayẹwo naa jade ṣugbọn ko ni arun ọhun.

Ni ọjọ Kẹrin kan naa ni o tun ayẹwo naa ṣe ti esi si fi han pe o ti ni arun Coronavirus.

Àkọlé fídíò, Say no to rape: Àwọn òṣèré tíátà Yorùbá pariwo síta lórí wàhálà ìfipábánilòpọ̀