Ìyá tó bí ìbaàrún ní ìpínlẹ̀ Kano jáde láyé

Awọn ọmọ marun-un ti wọn ṣẹṣẹ bi ni Kano n gba itọju lori ibusun ti wọn tẹ wọn si

Oríṣun àwòrán, Abubakar MK Gwantu/Screenshot

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Arábìnrin Hafsat Yusuf tó bí ìbaàrún sí ilé ìwòsàn Murtala Muhammad Specialist Hospital ní ìpínlẹ̀ Kano ní ọjọ́rú ọ̀sẹ̀ yìí ti pàdánù ẹ̀mí rẹ̀.

Agbẹnusọ iléesẹ́ tó ń rí sí ètò ìlera ní ìpínlẹ̀ Kano, Nabilusi Abubakar ló fìdí ìròyìn náà fáwọn akọ̀ròyìn ní ìlú Kano,

Abubakar sọ pé lẹ́yìn wákàtí díẹ̀ tí obìnrin náà bí àwọn ìbaàrún náà tán ló jáde láyé.

Ó ṣàlàyé pé ohun tó ṣokùnfà ikú Hafsat ni bí ẹ̀jẹ̀ ṣe ń dà lára rẹ̀ lẹ́yìn tó bí àwọn ọmọ náà tán láti aago méjì òru ọjọ́bọ̀.

Ó ní gbogbo ìgbìyànjú àwọn dókítà láti lè jẹ́ kí ẹ̀jẹ̀ náà dúró ló jásí pàbó, tí Hafsat sì padà dágbére fáyé ní òwúrọ̀.

Iléeṣẹ́ ètò ìlera náà wá sọ pé láyọ̀ àti àlááfíà ni àwọn ọmọ máráàrún tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ bí náà wà àti pé wọ́n ń gba ìtọ́jú nílé ìwòsàn.

Abubakar wá sọ pé àwọn ń bèèrè fún ìtọrẹ àánú látọ̀dọ̀ àwọn èèyàn pàápàá láti pèsè mílìkì àti àwọn ohun èèlò fáwọn ọmọ náà.

Wọ́n ti sin Hafsat Yusuf sí ilé rẹ̀ tó wà ní agbègbè Hotoro tó wà ní ìjọba ìbílẹ̀ Tarauni ní ìlànà ẹ̀sìn Islam.

Obìnrin ọlọ́mọ mẹ́jọ bí ọmọ márùn ún lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo

Bi o ti wu Oluwa lo n ṣọla, Eledua ti fi ọmọ marun un ta obinrin kan ti ti bimọ mẹjọ tẹlẹ lọrẹ niluu Kano.

Ọkunrin mẹta ati obinrin meji lawọn ibarun-un naa ti Eleduwa fi jinki Hafsatu Yusuf, nile iwosan Murtala Specialist hospital lo bi awọn ọmọ naa si ni Kano.

Salisu Nafiu to jẹ baba awọn ọmọ ọhun ṣalaye pe ni nnkan bii aago meji ọsan ni Hafsat bi awọn ọmọ naa l'Ọjọru ọsẹ yii.

Nafiu to n wa kẹkẹ Maruwa dupẹ lọwọ Ọlọrun lori iyawo rẹ to ru arusọ, o ni awọn ọmọ maraarun-un ati iya wọn n ṣe daadaa.

Baba awọn ọmọ tuntun naa ni ikunlẹ kẹsan an ni awọn ibarun-un naa jẹ fun iyawo oun.

Ọgbẹni Nafiu ni awọn oṣiṣẹ eleto ilera nile iwosan ti iyawo oun bawọn ọmọ naa si n tọju wọn daadaa.

Ẹwẹ, ijọba ipinlẹ Kano ti kede pe oun yoo ṣe itọju awọn ọmọ naa ati iya wọn.

Nabilusi Abubakar Kofar Na'isa to jẹ agbẹnusọ fun ileeṣẹ ijọba to n ri eto ilera nipinlẹ Kano sọ pe ijọba pinnu lati ṣetọju awọn ọmọ naa ati iya wọn lati ri pe adinku ba bi ọpọ ọmọ ikoko ṣe maa n ku lọmọde.

Bakan naa ni o sọ pe ijọba ko ni kaarẹ nipa ṣiṣe iranwọ fawọn ẹbi ti ko rọwọ họri nipinlẹ Kano lati ṣe itọju ara wọn nile iwosan.

Nafiu ọkọ iya awọn ọmọ naa tun dupẹ lọwọ ijọba ipinlẹ Kano fun iranwọ wọn fun ẹbi oun lori awọn ọmọ naa.

Bibi ọmọ marun-un lẹẹkan ṣoṣo ko wọpọ rara, ti iru rẹ ba si waye, awọn ọmọ bẹẹ maa n nilo itọju gidi.