Kókó ọ̀rọ̀ Tinubu níbi ìfilọ́lẹ̀ pápákọ̀ òfurufú Gateway ní ìpínlẹ̀ Ogun

Aarẹ Bola Tinubu wọ agbada adirẹ nibi to ti ṣi papakọ ofurufu Gateway International l'Ogun, Gomina ipinlẹ Ogun, Dapo Abiodun ati Gomina tẹlẹri ipinlẹ naa, Oloye Olusegun Osoba, naa wọ iru agbada kan naa pẹlu aarẹ

Oríṣun àwòrán, Dapo Abiodun/X

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Aarẹ orilẹede Naijiria, Aṣiwaju Bola Ahmed Tinubu ti gbe oṣuba kare fun Gomina Dapo Abiodun ti ipinlẹ Ogun lori awọn akanṣe iṣẹ idagbasoke ti ijọba rẹ n ṣe nipinlẹ naa.

Tinubu sọrọ yii nigba to n ṣi papakọ ofurufu Gateway lanaa ọjọ Abamẹta ọjọ kẹrin oṣu Kẹrin ọdun yii niluu Iperu-Ilisan.

Aarẹ Naijiria tẹlẹri, Oloye Olusegun Obasanjo; Aarẹ ile igbimọ aṣofin agba Naijiria, Godswill Akpabio; Oloye Olusegun Osoba toun naa jẹ gomina tẹlẹri nipinlẹ Ogun naa lu gomina lọgọ ẹnu.

Nigba to n sọrọ, Aarẹ Tinubu sọ pe papakọ ofurufu naa ṣafihan wi pe Gomina Abiodun lo owo to n gba daradara.

"Mo fi tọkan tọkan dupẹ fun anfaani ti a ni lonii, lati ṣajọyọ afojusun to ni ipa rere ti gomina ati awọn gomina tẹlẹ nipinlẹ Ogun ni.

A n ṣe ifilọlẹ agbegbe eto ọrọ aje tuntun to wa ni arọwọto wa.

Laaarin ọdun meje, iwọ Dapo Abiodun ti ṣafihan ifarajin, afojusun ati akikanju lati mu Naijiria dagba soke, a ba ọ yọ lori idagbasoke apapọ yii.

"N ko kabamọ lori ohunkohun ti a ti ṣe pẹlu yin, gẹgẹ bi aarẹ yin, inu mi dun lati rii pe ẹ lo owo ijọba apapọ ti a gbe soke fun un yin daradara lati mu ki orileede wa tẹsiwaju.

Mo ba awọn ọmọ ipinlẹ yii yọ nipa ṣiṣagbatẹru ijọba to n ṣe ojuṣe fun itẹsiwaju, bẹẹ si ni mo dupẹ lọwọ yin fun igbagbọ ti ẹ n ni ninu orileede wa," Tinubu sọ bẹẹ.

Tinubu sọ pe Ọlọrun ti n gba Naijiria silẹ kuro ninu inakuna atẹyinwa.

O ni "a ti pada gẹgẹ bi orileede ti wọn n bọwọ fun gidigidi, ati eyi ti wọn da mọ daadaa."

Inú mi dùn pé Abiodun kò ná owó tó n gbà lọ́dọ̀ ìjọba àpapọ̀ báṣu bàṣu - Tinubu

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Aarẹ Tinubu ni iwuri nla ni agbekalẹ Abiodun lori eto agbẹ jẹ, to fi mọ alupupu igbalode to n lo ina mọnamọna, to si ni yoo tun ṣe iranwọ pupọ fun eto irinna.

Bakan naa, nigba to n naa n sọrọ, aarẹ tẹlẹri, Oloye Olusegun Obasanjo dupẹ gidigidi lọwọ Aarẹ Tinubu lati wa nibi akanṣe eto ifilọlẹ naa, eyi to lo jẹ itan tuntun fun ipinlẹ Ogun.

O dupẹ lọwọ Gomina Abiodun naa fun bo ṣe kọ papakọ ofurufu naa lati ibẹrẹ titi de opin, to si ni iṣẹ akanṣe aritọkasi to jọju ni.

Ninu ọrọ rẹ, Obasanjo sọ pe "mo ti wọ ọkọ baluu lati Abuja wa si papakọ ofurufu yii, o si gba mi ni iṣẹju marundinlaadọta lati de ile mi, eleyi lo si jẹ iṣẹju marundinlọgbọn lo fi ja kuro ninu akoko ti mo maa fi n rin to ba jẹ pe Eko ni mo gba wọle.

"Mo fẹẹ dupẹ lọwọ gomina wa lati mu ori wa wu nipa ohun ti a n ṣe ifilọlẹ rẹ lonii.

O jẹ ohun idunnu fun mi lati wa nibi ifilọlẹ itan tuntun yii."

Bakan naa lo jẹ ko di mimọ pe bo tilẹ jẹ pe oun wa lara awọn to gbimọ papọ lati da ipinlẹ Ogun silẹ lọdun 1976, sibẹ awọn ko ni afojusun wi pe iru idagbasoke bayii yoo waye, to si loun dupẹ pe aṣeyọri naa ṣoju ẹmi oun.

Nigba toun funra rẹ n sọrọ, Gomina Abiodun fi idunnu rẹ han si aarẹ fun atilẹyin lati jẹ ki erongba naa waye nipa afikun owo tijọba apapọ n fun awọn ipinlẹ.

O sọ pe agbekalẹ Aarẹ Tinubu lori atunṣe Ireti ti jẹ ki Naijiria wa ni ipo rẹ fun agbegbe lati dokoowo si fun awọn olokoowo agbaye.

Abiodun sọ pe nigba toun gba ijọba lọdun meje sẹyin, oun pinnu lati di alafo to wa laaarin ipinlẹ Ogun ati Eko, to si lo jẹ ohun iwuri pe ala rere oun wa si imuṣẹ.

O wa jẹ ko di mimọ pe ọkan pataki ni ipinlẹ Ogun jẹ ninu awọn ipinlẹ ti eto ọrọ aje rẹ tete n ni idagbasoke nilẹ Naijiria, nipa awọn agbekalẹ ati ilana.

Bakan naa lo fi kun ọrọ rẹ pe yatọ si papakọ ofurufu tuntun yii, ati ọkọ baluu tuntun meji ti ijọba ipinlẹ naa ni, iṣakoso oun tun ti ṣe ọpọlọpọ opopona to le diẹ ni ẹgbẹrun kan aabọ kilomita ati ile gbigbe olowo pọọku ti ko din ni ẹgbẹrun meje.