Ìjọba Plateau kéde ìṣéde ọlọ́jọ́ méjì lẹ́yìn ìkọlù agbébọn, léri láti máṣe sin àwọn òkú ní àsinpọ̀

Gomina Caleb Mutfwang ti ipinlẹ Plateau wọ asọ shaati ati sokoto alawọ buluu, n fi ọwọ kan ọkunrin kan to sun sori ibusun nile iwosan, wọn fi ọpọ bandeji yi ori, ẹsẹ ati ọwọ rẹ, ti wọn si n fa omi si lara.

Oríṣun àwòrán, Government of Plateau state/Facebook

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 8

Gomina ipinlẹ Plateau, Caleb Mutfwang, ti sabẹwo si agbegbe ti iwa isekupani naa ti waye, to si leri fawọn ẹbi alaisi to fara gba ninu isẹlẹ naa pe oun ko ni gba, ki wọn sin awọn oku naa papọ.

O ni ko ni sin oku asinpapọ, ti ijọba yoo si jiroro pẹlu awọn mọlẹbi oku, ti awọn si maa sin wọn ni ilana to yẹ.

Nigba to n sọrọ nipa awọn eeyan to wa nile iwosan tori bi wọn se fara gbọgbẹ ninu isẹlẹ naa, gomina ni qijọba ni yoo sanwo itọju wọn nile iwosan.

Mutfwang wa sisọ loju afurasi kan to n dunkooko lori ayelujara nipa ikọlu naa ni ọwọ awọn agvbofinro ti tẹ, ti wọn si tun n dọdẹ awọn afurasi yoku.

Wayi o, awọn eeyan ti isẹlẹ isekupani to waye nipinlẹ Plateau soju wọn ti n sọrọ nipa bi iwa ika naa se waye.

Bẹẹ ba gbagbe, a ti mu iroyin wa fun yin saaju nipa bi awọn agbebọn to gun ọkada to le ni ogun, wọ asọ ajọ to n gbogun ti gbigbe oogun oloro, se ya wọ adugbo Gari Ya Waye ni agbegbe Angwan Rukuba, nijọba ibilẹ Ariwa ilu Jos.

Lẹyin isẹlẹ naa, eeyan bii ogun lo jade laye nigba ti ọpọ eeyan mii fara pa yanna-yanna.

Ileesẹ iroyin BBC fẹsẹ kan agbegbe naa lati ba awọn eeyan ti isẹlẹ ọhun soju wọn sọrọ.

Gomina Caleb Mutfwang ti ipinlẹ Plateau wọ asọ shaati ati sokoto alawọ buluu, n fi ọwọ kan ọkunrin kan to wọ asọ pupa,di irun sori, sun sori ibusun nile iwosan. Obinrin Nọọsi kan to wọ ibọwọn duro niwaju gomina.

Oríṣun àwòrán, Government of Plateau state/Facebook

"To ba jẹ pe ijọba ko tii kede konile gbele ni, ọpọ eku ni ko ba ti sun, amọ isede naa ti jẹ ki ara awọn eeyan balẹ, ti alaafia si ti n pada si agbegbe naa."

Nigba to n ba BBC News Yoruba sọrọ lori isẹlẹ naa, Malam Salami Ibrahim Sulaiman ni deedee aago mẹjọ alẹ ni isẹlẹ naa waye.

"A kan sadede ri awọn ọkunrin kan to gun ọkada, ti wọn kan n pa awọn eeyan laibikita.

A ko le sọ pe iru awọn eeyan bayii ni wọn, isẹlẹ naa si ba wa ninu jẹ.

A gbọ pe gomina ipinlẹ Plateau, Caleb Mutfwang, ti kede asẹ konile gbele ni agbegbe naa.'"

Nigba to n sọrọ lori igbesẹ tijọba n gbe lati tako ipenija eto aabo, Sulaiman ni ijọba ti gbe igbesẹ to dara pupọ pẹlu isede Konile o gbele naa to se.

"To ba jẹ pe ijọba ko tii gbe igbesẹ naa, ọpọ eku ni ko ba ti sun, amọ isede naa ti jẹ ki ara awọn eeyan balẹ, ti alaafia si ti n pada si agbegbe naa."

Gomina Caleb Mutfwang ti ipinlẹ Plateau wọ asọ shaati ati sokoto alawọ buluu, n fi ọwọ kan ọbinrin kan to joko sori ibusun nile iwosan, o dirun, to si n rẹrin si gomina

Oríṣun àwòrán, Government of Plateau state/Facebook

"Iṣẹlẹ ipaniyan naa ti se akoba nla fun ọrọ aje, okoowo ati igbayegbadun wa"

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ninu ọrọ tiẹ naa pẹlu BBC, Anest Ibrahim Sulaiman ni isede ti ijọba se dara pupọ, tori lẹyin irun aarọ ọjọ Aje lawọn eeyan sẹsẹ mọ ohun to sẹlẹ ni agbegbe naa.

"A gbọ ni Mọsalasi pe wọn ko gba ki ẹnikẹni maa rin gbere-gbere kiri aarin ilu, amọ ki onikaluku fidi mọle ni."

Nigba to n sọrọ lori ipa ti iwa isekupani ati isede naa yoo ni lori okoowo, ọrọ aje ati igbayegbadun awọn eeyan agbegbe naa, Sulaiman ni ipa nla ni isẹlẹ naa yoo ni lori gbogbo eeyan, ati Musulumi, ati Kristiẹni.

"Ta ba ni ka sọ otitọ, isẹlẹ naa yoo se akoba nlanla fun ajọsepọ to wa laarin awọn Kristiẹni ati Musulumi.

Ti mi o ba gbagbe, ni bi ọsẹ meji sẹyin, awọn ileesẹ to n polongo alaafia ba wa sọrọ, ti wọn si gba wa nimọran.

Bakan naa, o daju pe ọpọ eeyan ni ko ni le lọ na ọja, eyi ti yoo se akoba fawọn ọdun to n bọ lọna.

Fun apẹrẹ, ọjọ Ẹti yii ni ayajọ ọjọ Ẹti rere fawọn ọmọlẹyin Kristi, ti wọn si nilo lati lọ sọja, lọ ra ọpọ eroja ti wọn yoo fi se ọdun.

Eleyi yoo ko ba ọrọ aye wa, ti awọn onisowo ati onibara yoo si mọ ipa isẹlẹ yii lara."

Sulaiman wa rọ ijọba ipinlẹ naa lati gbe ẹsẹ kuro lori ofin Konile o gbele, amọ ko gbe awọn igbesẹ ti yoo dena iwa isekupani bi iru eyi.

O ni o yẹ kawọn eeyan agbegbe naa maa foju sọri, ki wọn si maa fura nipa alejo ati oju ti wọn ko ri ri, to ba n rin ladugbo wọn.

Àkọlé fídíò, "Mo ra ‘Sim Card’ táwọn ajínigbé ti fi gbá owó ìtúsílẹ̀ N50m, pa ẹni tí wọn jí gbé, mo bá dèrò ọgbà ẹ̀wọ̀n"

Agbèbọ́n tún ṣọṣẹ́ ní Plateau, pa ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́jọ́ Ìsinmi Ọ̀pẹ

Ikọlu tuntun mi-in tun waye lanaa ọjọ Aiku, ọjọ kọkandinlọgbọn oṣu Kẹta ọdun 2026 yii ti i ṣe ọjọ isinmi Ọpẹ, nipinlẹ Plateau, nibi ti ọpọ eeyan ti di oloogbe ti ọpọ si farapa yanna-yanna.

Ilu kan ti wọn n pe ni Gari Ya Waye, lagbegbe Angwan Rukuba, ipinlẹ Plateau ni iṣẹlẹ naa ti waye.

Alẹ ọjọ Aiku ana ti ikọlu naa waye ni ijọba kede ofin konilegbele ọlọjọ meji, lati so okun aabo le si i.

Konilegbele ọhun ti yoo bẹrẹ ni aago mejila oru ni yoo wa bẹẹ titi di lọjọ akọkọ ninu oṣu Kẹrin ọdun 2026 yii.

Aworan awon agbebon to gbe ibon kọrun ninu igbo, wọn n rin lọ.

Oríṣun àwòrán, Others

Ki lo ṣẹlẹ gan-an?

Nnkan bii aago meje aabọ si mẹjọ alẹ ọjọ Aiku ni awọn agbebọn ṣina ibon bolẹ fun awọn olugbe Gari Ya waye, eyi to wa ni Angwan Rukuba.

Ibi kan ti awọn eeyan pe jọ pọ si ni a gbọ pe wọn ti deede ṣina ibọn bolẹ, to si ba ọpọ eeyan lojiji.

O kere tan, eeyan mejila lo di oku lẹsẹkẹsẹ gẹgẹ bi awọn iroyin agbegbe naa ṣe ṣalaye.

Ọpọ eeyan ni wọn lo tun farakaasa ibọn pẹlu, ti wọn si balẹ si ile iwosan to wa nitosi, nibi ti wọn ti n gba itọju.

Lasiko ti a n kọ iroyin yii, awọn alaṣẹ ko ti i sọ pato iye eeyan to di oloogbe ninu ikọlu ọhun.

"Ẹ fidi mọle yin bi awọn ẹṣọ alaabo ṣe n wọde kiri"

Atẹjade lati ọdọ ijọba ipinlẹ Plateau ti rọ awọn olugbe ilu naa lati fidi mọle bi awọn ẹṣọ alaabo ṣe n wọde kiri.

Kete ti ibọn yinyin ọhun wa sopin ni wọn ti da awọn eleto aabo naa sita pẹlu awọn agbofinro ti yoo ri si ki alaafia jọba, ti wọn yoo si mu awọn to ṣiṣẹ ibi naa.

Ikọlu agbebọn yii ti mu ọpọ nnkan duro ni Plateau, pẹlu bi awọn ile ẹkọ titi kan Yunifasiti ilu Jos ṣe ti tun ilana iṣẹ wọn to nitori ai si aabo to peye.

Bakan naa lo jẹ pe ipinlẹ Plateau wa lara awọn apa ibi ti ikólu ti maa n ṣẹlẹ l'Ariwa.

Ilu Jos to jẹ olu ilu naa ti foju wina ọpọ ikọlu ṣaaju lati bii ọdun mẹwaa sẹyin, gbogbo igbiyanju ijọba lati ṣẹgun rẹ ko si ti i fi bẹẹ so eso rere.

Bo si tilẹ jẹ pe ijọba ipinlẹ Pleateau n sọ pe ohun gbogbo wa labẹ akoso alaafia, sibẹ, ofin konilegbele ti wọn gbe jade yii ti mu ọpọ eeyan maa sọ pe ina ti jo de ori koko bayii nipa ọrọ aabo.

"Ko si idi kankan fun ikọlu yii rara, o buru jai''

Nigba to n ṣalaye nipa ikọlu yii, Gomina ipinlẹ Plateau,

Caleb Manasseh Mutfwang, sọ pe ohun ti ko si idi kankan fun ni.

Ninu atẹjade to fi sita ni Gomina Mutfwang ti koro oju si iṣẹlẹ yii, to si ni oun ti paṣẹ fun awọn ẹṣọ eleto aabo lati wa awọn agbebọn naa ki wọn si mu wọn ṣinkun.

O ni wọn gbọdọ fi wọn jofin gẹgẹ bo ṣe yẹ.