"Laylatul Qadri", òru tí olóríibú máa ń di olóríire ni tóo bá bẹ Ọlọ́hun, orú agbára gidi ni - Akeugbagold
Alẹ ọjọ Laylatul Qadr jẹ alẹ ọjọ to pọndandan fun awọn Musulumi ni agbaye.
O jẹ alẹ ọjọ ti awọn Musulumi gbagbọ wi pe Allah fi ọpọlọpọ ibukun si fun gbogbo awọn to ba yege fun lati gba ibukun bi Ọlọrun ṣe sọ ninu iwe Suratai Qadri.
Alaye ree lori ohun to yẹ ki awọn Musulumi mọ nigba alẹ yii ati igba to yẹ ki eniyan gbadura fun ni alẹ ọjọ naa.
Gẹgẹ bi wọn ṣe maa n reti oṣu ti yoo sọ ọjọ ti awẹ yoo bẹrẹ, oru pataki kan tun wa ti awọn Musulumi maa n foju sọna fun ti wọn si maa n waa lati mọ ọjọ ti yoo bọ si pato. Ki ni idi ti wọn fi n wa a?
Ọjọ mẹwaa to kẹyin oṣu Ramadan ni oru ti wọn n pe ni Lailatu-l-Qodri.
Ilumọọka aṣiwaju ẹsin Islam kan to fi ilu Ibadan ṣe ibujoko, Sheikh Al-Wasir Taofeek Akeugberu ti ọpọ mọ si Akeugbagold ṣalaye pe oru iyi, oru agbara ti Ọlọrun maa n ṣe ọla ni oru Lailatul Qadri jẹ.
Onimọ nipa ẹsin Islam naa ni "oru ti oloriire le di oloriibu ti ko ba ṣọra ni, kọda, oru ti oloriibu o di oloriire ni."
O ni ọjọ ti yoo ṣẹlẹ, ko sẹni ti yoo mọ amọ ṣiṣọ asiko ṣe pataki gidi gan ninu asiko aawẹ.
Lara awọn nkan ti yoo jẹ ki laada rẹ pe ni: didide yan nọfila loru, too ba le ṣe e tori o ni o pataki gan loju Ọlọrun.
Bakan naa ni Alaga Ajọ awọn Musulumi ni ipinlẹ Oyo tẹlẹ naa tun mẹnu ba yiyan nọfila to si ni ki onikaluku mura si ẹsin ati ibaada lasiko Ramadan.
Anọbi yoo tun ara ṣe ni nkan bii ọjọ mẹwaa to gbẹyin lasiko aawẹ

Oríṣun àwòrán, Getty Images
"Ṣiṣọ akoko ṣe pataki ninu aawẹ, ọpọ eeyan ni ko mọ pe asiko ẹ pataki ninu aawẹ".
Ni ọjọ kọkandinlogun aawẹ, Anọbi yoo tunra ṣe, Anọ́bi yoo tun sokoto rẹ san, yoo tun ara ṣe yoo wa sọ pe na'am".
Akeugbagold gba awọn Musulumi nimọran gbe ki wọn foju sọna gidi gan de oru agbara naa lọhun ti gbogbo awọn Mọlaika yoo sọkalẹ wa sorilẹ aye.





