Mo ti bí ọmọ márùn-ún tẹ́lẹ̀ kí n tó bí ibẹ́rin báyìí, ìbejì ni scan sọ fún mi- Ìyá Ìbẹ́rin

Àkọlé fídíò, Mo ti bí ọmọ márùn-ún tẹ́lẹ̀ kí n tó bí ibẹ́rin báyìí, ìbejì ni scan sọ fún mi- Ìyá Ìbẹ́rin
Mo ti bí ọmọ márùn-ún tẹ́lẹ̀ kí n tó bí ibẹ́rin báyìí, ìbejì ni scan sọ fún mi- Ìyá Ìbẹ́rin

Arabinrin Mutiat Olateju ti bi ọmọ marun un ṣaaju ko to loyun mii lọdun to kọja pẹlu erongba lati sọ wọn di mẹfa.

Pẹlu bii nnkan ṣe ri orilẹede Naijiria, o pinnu lati lọ sẹ oyun naa ṣugbọn nigba to de si ile iwosan, ti wọn ṣe ayẹwo, wọn ri pe oyun ibeji lonii.

Eyi ko ọpọ ironu si ọkan rẹ, ti wọn si ki nilọ pe ko gbọdọ gbiyanju lati sẹ oyun naa.

"Wọn ki mi ni ikilọ pe ti mo ba sẹ oyun yii, ọta mi le jade laye.

"Nigba ti oyun pe oṣu mẹrin, o ya mi lẹnu pe ikun mi tobi ju."

Aworan tọkọtaya to bi ọmọ mẹrin lẹẹkan naa

Oríṣun àwòrán, BBC/GettyImages

Mutiat tẹsiwaju pe ni oṣu kinni, oun tun lọ ṣe ayẹwo miiran, ti o si pe ọmọ mẹta ni wọn ri lara oun.

"Nigba ti oyun mu mi ni oṣu kẹta yii, ti wọn gbe mi lọ si ile iwosan, ni wọn bẹrẹ si ni ma gbe awọn ọmọ yii bọ sita, ti wọn si jẹ mẹrin.

"Aya mi ja pe bawo ni mo ṣe fẹ sẹ ọrọ aye mi, ọna wo ni mo fẹ gbe gba.

"Bi wọn ṣe gbe awọn ọmọ naa sit ani mo ti bẹrẹ si ni ma sunkun, ti wọn si sọ fun mi pe ẹkun ayo ni"

Nigba ti mo gbọ pe iyawo mi bi ọmọ mẹrin, ẹ ru ba mi, mo si fẹ ṣalọ- Baba Ibẹrin

Seun Tejuola, baba ibẹrin ni oun ti fẹ salọ nigba ti oun gbọ pe iyawo oun bi ọmọ mẹrin lẹẹkan naa. ṣugbọn awọn eeyan duro ti oun lasiko naa.

Baba Ibẹrin ni iṣẹ ti oun ṣe ko to bọ awọn ọmọ naa nitori alapata ni oun to si jẹ idi nla ti ẹru fi ba oun.

"Nnkan o lọ daada fun mi, mo nilo iranlọwọ awọn ọmọ Naijiria nitori nnkan yii ju mi lọ lati le ṣe."