You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
N kò ní darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ ADC àmọ́ bí APC bá fún mi ní ipò míì, màá gbà á - Iyabo Obasanjo
Lara awọn obinrin oloselu ti ko se fi ọwọ rọ sẹyin, ti orukọ wọn si gbajumọ ni Iyabo Obasanjo jẹ.
Ọmọ aarẹ tẹlẹ nilẹ wa, Olusegun Obasanjo nii se, ile lo ba oselu sise, ti oun naa si jẹ eekan gbogi lagbo oselu.
Onimọ isegun nipa itọju ẹranko ni Iyabo, o si ti jẹ Kọmisana feto ilera ri nipinlẹ Ogun.
Bakan naa lo ti dupo wọle sipo Sẹnetọ ri nipinlẹ naa labẹ ẹgbẹ oselu PDP amọ to ti darapọ mọ mọ ẹgbẹ oselu APC bayii.
Koda, Iyabo Obasanjo ni lero lati dije du ipo gomina ipinlẹ Ogun amọ lọjọ Aje to lọ ni awọn agba ẹgbẹ kede pe wọn ti panupọ yan Solomon Olalekan Adeola, ti ọpọ eeyan mọ si Yayi lati gbe apoti ibo gomina fun ẹgbẹ oselu naa.
Ikede yii si lo pagidina erongba Iyabo Obasanjo lati dije fun ipo ọhun.
Idi ree ti BBC News Yoruba se tọ agba oselu naa lọ lati gbọ ti ẹnu rẹ lori iha to kọ si ikede ẹgbẹ oselu naa lati mu Yayi bii oludije sipo gomina.
Nigba to n ba BBC News Yoruba sọrọ, Iyabo Obasanjo ni lootọ ni ẹgbẹ oselu APC nipinlẹ Ogun ti panupọ mu ẹnikan laarin awọn oludije sipo gomina naa.
Amọ o ni oun ti pe onitọun lati ki ku oriire, ti oun si rọ ọ lati se daadaa lori ipo naa ni kete to ba dori aleefa.
"O da mi loju pe ẹgbẹ oselu APC lo maa wọle ibo gomina nipinlẹ Ogun, ti Yayi si maa di gomina fun ipinlẹ naa.
Saaju ni mo ti seleri pe ti ẹgbẹ oselu APC ba fẹnuko lati gbe oludije kan kalẹ fun ipo gomina, maa fara mọ ipinnu ẹgbẹ, wọn si ti kede orukọ ẹni ti ẹgbẹ fara mọ lati dije, emi naa si gba bẹẹ."
Nigba to n dahun ibeere pe se lootọ lo fẹ kuro ninu ẹgbẹ oselu APC lọ darapọ mọ ẹgbẹ ADC,. Iyabo Obasanjo ni eyi ko ri bẹẹ rara.
"Emi ko ba eeyan kankan sọ iru ọrọ yii, ti wọn ba sọ bẹẹ, irọ ni wọn pa mọ mi,
N ko ba ẹnikẹni sọrọ ninu ẹgbẹ oselu ADC ayafi to ba jẹ eeyan kan ninu ADC to ti jẹ ọrẹ mi."
"Awọn eeyan lo pe mi jade lati du ipo gomina, mo si ti sọ fun wọn tẹlẹ pe n ko fẹ se e"
Nitẹsiwaju ọrọ rẹ, Iyabo Obasanjo ni awọn eeyan kan lo pe oun jade lati wa du ipo gomina fẹgbẹ oselu APC.
Amọ o ni oun ti sọ fun wọn tẹlẹ pe oun ko fẹ se e, amọ nibayi ti oun ti kede lati du ipo naa, o si tẹ oun lọrun bi gbogbo rẹ se lọ.
"Igbesẹ naa mu inu mi dun pe awọn eeyan ipinlẹ Ogun fẹran mi, wọn si fẹ ki n se asoju wọn amọ ko see se nisinsinyii.
Mo dẹ fẹ dupẹ lọwọ awọn eeyan ipinlẹ Ogun atawọn ọmọ ẹgbẹ oselu APC naa, tori wọn gba mi tọwọ tẹsẹ tori a lọ kaakiri ipinlẹ yii lati ba wọn sọrọ.
Mo si ri pe wọn fẹran mi pupọ, emi naa si fẹran wọn denudenu tori gbogbo maa dijọ fọwọ sowọpọ fun ilọsiwaju ipinlẹ Ogun ni."
Ki ni ero baba Iyabo, Olusegun Obasanjo, nigba ti ọmọ rẹ ko ri tikẹẹti ipo gomina gba lati soju ẹgbẹ oselu APC nipinlẹ Ogun?
Bakan naa ni Iyabo Obasanjo sisọ loju rẹ pe awọn eeyan to pe oun jade ni lero pe oun maa se daadaa nipo gomina ni.
"Wọn ko pe mi jade lati gba ipo oselu miran, amọ ti ẹgbẹ ba fẹ fun mi ni nnkan miran, maa ro o, maa si gba a.
Amọ ipo gomina yẹn gan ni mo jade fun lati dupo rẹ."
Lori ibeere pe ki ni ero baba rẹ, Olusegun Obasanjo nigba ti ko ri tikẹẹti gba lati soju ẹgbẹ oselu APC nipinlẹ Ogun?
Iyabo dahun pe " Baba Obasanjo nikan lo le dahun ibeere yẹn amọ mo maa pe ẹni ọgọta ọdun lọdun 2027 eyi to tumọ si pe emi gan ti di agba lawujọ.
Awọn gan gbiyanju lati dije bọ sinu igbimọ alakoso ajọ isọkan agbaye (United Nations) amọ wọn fidi rẹmi.
Eyi tumọ si pe kii se gbogbo ohun ti eeyan ba fẹ, lo maa tẹ lọwọ. Eyi ko yẹ ko soro fun iya ati baba mi lati gba mọra"
Iyabo Obasanjo se agbeyẹwo isejọba gomina Dapo Abiodun
Nigba to n se igbelewọn isejọba gomina Dapo Abiodun ti ipinlẹ Ogun, Iyabo Obasanjo ni gomina naa ti se daadaa lati mu ilọsiwaju ba ipinlẹ naa.
"Ẹ wo papakọ ofurufu ti ijọba Abiodun se, eeyan le ri pe iyatọ nla ti ba ipinlẹ Ogun laarin ọdun mẹjọ ti gomina naa ti n dari ijọba.
Bakan naa, awọn ileesẹ nla nla ti wọn da silẹ nipinlẹ Ogun ti pọ si ju ti atẹyinwa lọ.