Ìjọba yóò máa gba ìwé ìrìnnà lọ́wọ́ àwọn tó bá ní àwọn kì í ṣe ọmọ Naijiria mọ́

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Minisita ọrọ abẹle, Olubunmi Tunji-Ojo, ti paṣẹ pe kawọn ileeṣẹ to n ri si iwọle-jade (Nigeria Immigration Service) maa gba iwe irinna awọn ọmọ orilẹede yii ti wọn ba ni awọn ki i ṣe ọmọ Naijiria mọ, ki wọn si ri i pe ko ṣiṣẹ mọ fun wọn.
Oni ọjọ Abamẹta, ọjọ kọkanla oṣu Kẹrin ọdun 2026 ni Tunji-Ojo kede igbesẹ tuntun naa ninu atẹjade kan to ti ọwọ Olugbani-nimọran lori iroyin rẹ, Alao Babatunde, jade.
Atẹjade naa ṣalaye pe awọn eeyan ti Aarẹ ba ti gba pe wọn ki i ṣe ọmọ Naijiria mọ ni ọrọ yii kan.
" Ọmọ Naijiria yowu to ti to lọjọ ori, to si wu u lati ma ṣe jẹ ọmọ Naijiria mọ yoo kede lọna to tọ.
"Aarẹ yoo paṣẹ ki wọn ṣe akọsilẹ ikede naa labẹ ofin abala akọkọ, lẹyin iforukọsilẹ naa, ẹni naa ko ni i jẹ ọmọ Naijiria mọ."
Bẹẹ ni apa kan ikede naa wi.
Ẹni ti ki i ṣe ọmọ Naijiria mọ ko le ni iwe to jẹ aṣẹ Naijiria, titi kan iwe irinna.
Minisita Tunji-Ojo ṣalaye pe eyi wa ni ibamu pẹlu abala ofin 29 (1) ati ikeji ninu ofin ọdun 1999.
O ni ẹni ti ki i ṣe ọmọ Naijiria mọ ko le ni iwe to jẹ aṣẹ Naijiria, titi kan iwe irinna.
Bakan naa lo ni igbesẹ yii wa lati dena awọn ti ki i ṣe ọmọ Naijiria mọ lati maa fi iwe irinna Naijria rin irinajo.
" A o maa ṣeto to n da aabo bo awọn ẹnu ibode Naijiria, dena jibiti idanimọ, ati eyi ti yoo maa jẹ ki eeyan rin irin ajo lọna to tọ, ti yoo tun dena awon ti ko yẹ lati wọ ilẹ wa."
Bẹẹ ni atẹjade naa ṣalaye.

























