A ti dóòlà èèyàn 31 tí wọ́n jí gbé nílé ìjọsìn lọ́jọ́ ọdún Àjínde – Ilésṣẹ́ ọmọ ogun

Oríṣun àwòrán, HQ Nigerian Army
Ileeṣẹ ọmọ ogun Naijiria ni oun ti doola eeyan mọkanlelọgbọn ti awọn agbesunmọmi ji gbe lasiko ikọlu wọn sile ijọsin laarọ ọdun Ajinde.
Eeyan marun un lo ku lasiko ikọlu naa ti wọn ṣe si awọn olujọsin niluu Ariko, nipinlẹ Kaduna.
Amọ atẹjade lati ile ijọsin naa sọ pe eeyan mẹtadinlogun lo padanu ẹmi wọn nibẹ.
Ileeṣẹ ọmọ ogun Naijiria sọ pe awọn doju ija kọ awọn agbesunmọmi naa ti iro ibọn si n dun lakọlakọ, eyii to mu ki awọn agbesunmọmi ọhun na papa bora.
Ologun ninu atẹjade loju opo Facebok wọn sọ pe awọn agbesunmọmi naa salọ, wọn si fi awọn ti wọn ji gbe silẹ, to fi mọ awọn oku awọn akẹgbẹ wọn to ṣubu loju ija.
Ijinigbe lati pa owo wọle ti di tọrọfọnkalẹ ni Naijiria, paapaa ni iha Ariwa.
Yatọ si awọn ọmọ ogun Boko Haram to n ṣọṣẹ nibẹ, oniruru ẹgbẹ mii lo n ji eeyan ni Ariwa bii janduku, agbebọn, Fulani darandaran, Lakurawa atawọn ọmọ ẹgbẹ mii.
Bo tilẹ jẹ pe ileeṣẹ ọmọ ogun sọ pe awọn ko fi akoko ṣofo ki awọn to ya bo ile ijọsin ti ikọlu naa ti waye, awọn to wa nibẹ sọ fun awọn akọroyin pe fun ọpọ wakati lawọn agbesunmọmi naa fi ṣọṣẹ lai si idwọ kankan.
Gẹgẹ bii ohun ti ileeṣẹ ọmọ ogun sọ,pupọ ninu awọn agbesunmọni naa to salọ lo farapa ni bi awọn ṣe ria pa ẹjẹ wọn nilẹ.
Wọn ni ileeṣẹ naa ti da awọn ologun sinu igbo lati maa wa awọn kọlọrọsi naa bayii.
Wọn tun rọ awọn araalu lati pin awọn iroyin to le ṣamọna bi ọwọṣe le tẹ awọn afurasi fun ileeṣẹ ọmọ ogun.
Ninu iroyin mii, ileeṣẹ ologun tun ṣekuoa agbesunmọmi marunlelgọta nipinlẹ Zamfara.
Ṣaaju ni ọlọpaa ti kọkọ sọ pe awọn agbesumọmi naa ji ọpọ eeyan gbe nipinlẹ naa ati awọn agbofinro ti n tọpasẹ awọn agbesunmọmi ọhun.
Ọdun to kọja ni Aarẹ Amẹrika, Donald Trupm ke gbajare pe awọn alakakiti ẹsin Islam n ṣekuoa awọn ọmọlẹyin ni Naijiria, ati pe ijọba oun ko ni la oju rẹ silẹ ki irufẹ ikọlu bẹẹ maa tẹsiwaju.
Amọ ijọba Naijiria ni ko ri bẹẹ nitori bi awọn agbesunmọmi ṣe n pa awọn Kristẹni naa ni wọn n pa awọn Musulumi.
























