Wo ohun tó mú àyájọ́ ọjọ́ ìsinmi 'Palm Sunday' yàtọ̀

Ọkunrin kan gun ẹṣin atawọn eeyan mii ti wọn mu imọ ọpẹ lọwọ
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Oni ni ayajọ 'Palm Sunday' eyi ti awọn Yoruba maa n pe ni ọjọ isinmi imọ ọpẹ.

Ayajọ yii jẹ ọjọ ti awọn ọmọlẹyin Kristi fi maa n ṣe ami bi Jesu Kristi ṣe gun kẹtẹkẹtẹ wọ Jerusalem nigba aye rẹ.

Lasiko igba naa, gẹgẹ bi iwe mimọ Bibeli ṣe sọ, niṣe ni awọn eeyan fi ijo ati ayọ pade rẹ pẹlu imọ ọpẹ lọwọ.

Lati ara imọ ọpẹ yii naa ni ayẹyẹ naa si ti gba orukọ.

Ti ayẹyẹ ọdun ajinde ba ku ọsẹ kan ni ayẹyẹ yii maa n waye ni ọjọ Aiku to ba ṣaaju ọdun ajinde.

Kaakiri agbaye si ni wọn ti maa n ṣe ayẹyẹ yii to si maa n waye nigba ti awẹ awọn ọmọlẹyin Kristi ba ku ọsẹ kan to maa pari.

Awọn ọmọlẹyin Krisiti n ṣayajọ ọjọ isunmi Imọ Opẹ
Imọ ọpẹ niluu Ilorin
Ọkunrin kan wọ aṣọ funfun ati fila funfun nibi ayajọ ọjọ isinmi imọ ọpẹ niluu Ilorin

Lasiko ayẹyẹ yii ni awọn ọmọlẹyin Kristi maa n fi imọ ọpẹ dara oriṣiriṣi to ba wu wọn.

Awọn mii maa n fi ṣami agbelebu eyi to tumọ si bi wọn ṣe kan Jesu mọ agbelebu

Ọlọtọ ni toun ọtọ ni bi awọn ọmọlẹyin Kristi ṣe maa n ṣayẹyẹ ni ilu Ilorin, olu ilu ipinlẹ Kwara.

Niṣe ni awọn ọmọlẹyin Kristi ni ilu Ilorin maa n ko ara wọn jọ lati ṣe iwọde kaakiri awọn agbegbe kọọkan lati ṣami ayajọ yii.

Gbogbo awọn ọmọlẹyin Kristi ni ilu Ilorin lai fi ti ijọ tabi ile ijọsin ti wọn n lọ ṣe ni wọn maa n fi orin ati ilu ṣe iwọde.

Bakan naa ni wọn tun ṣe ni ọdun yii nigba ti wọn fijo ati ayọ yide lati ṣayẹyẹ ọdun imọn ọpẹ .