Rògbòdìyàn PDP: Wo àwọn tọ kọ̀yìn sí ìpàdé àpapọ̀ igun Wike tí yóò wáyé l'Abuja lónìí

Asia ẹgbẹ PDP to duro pẹlu awọn ọmọ ẹgbẹ naa nibi ipade kan

Oríṣun àwòrán, PDP

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Igun ẹgbẹ oṣelu PDP to n tẹle Minisita ilu Abuja, Nyesom Wike, ti fẹnuko pe oni ọjọ Aiku, ọjọ kọkandinlọgbọn oṣu Kẹta ọdun 2026 ni ipade apapọ awọn yoo waye niluu Abuja.

Pẹlu bi ẹgbẹ PDP ṣe ti pin, ti awọn alaga ẹgbẹ ti ṣe ọtọọtọ, ti ọpọ gomina PDP si ti kuro nibẹ, awọn kan ti sọ pe awọn ko ni i de ibi ipade ti Wike atawọn eeyan rẹ gbe kalẹ yii.

Ipade naa ti wọn ni yoo tun tẹsiwaju lọla ọjọ Aje ni yoo waye ni papa iṣẹre Moshood Abiola National Stadium, l'Abuja.

Àwọn to kọyin si ipade naa

Alaga fun awọn alaga ipinlẹ kọọkan ninu PDP, Tony Aziegbemi, lo ti kọkọ ṣalaye pe ko yẹ ki ipade yii waye rara pẹlu bi ẹjọ PDP ṣe wa nile ẹjọ to ga julọ, ti wọn ko ti i gbọ ọ.

"Ipade ti Wike n gbero ẹ yii ko ba ofin mu, ma a rọ awon alaga ipinlẹ ninu ẹgbẹ PDP lati ma ṣe lọ sibẹ rara."

Bẹẹ ni Alaga awọn alaga ẹgbẹ oṣelu PDP naa wi.

O rọ ajọ INEC paapaa lati wo awon eeyan ti wọn fẹ lo bii aṣoju nibi ipade naa, o ni awọn ti wọn n pe ara wọn lohun ti wọn ko jẹ ni.

Bakan naa ni PDP ipinlẹ Sokoto sọ pe awọn ko ni I de ibi ipade Wike yii.

Akọwe ikede wọn, Hassan Sanyinawal, sọ pe awọn yoo maa woran titi ti rogbodiyan yii yoo fi dopin ni.

Akọwe ipolongo igun PDP fun awọn gomina to ṣi wa ninu PDP, Ini Ememobong, sọ pe Gomina Seyi Makinde ipinle Oyo ko ni i lọ sipade yii.

O ni Gomina ipinlẹ, Bauchi; Bala Mohammed ati Alaga igbimọ olufọkantan; Adolphus Wabara, ko ni i lọ sipada naa pẹlu.

Awọn ti wọn n lọ

PDP Kwara: Wọ ni awọn yoo lọ s'Abuja ni tawọn.

Alaga wọn, Alhaji Isa Bawa, ṣalaye pe awọn fẹnuko lati lọ lẹyin apero lori ohun to n ṣẹlẹ lọdọ awọn olori PDP.

PDP Kebbi: Wọn ni awọn ti ran awọn aṣoju lọ sibẹ lati Kebbi, awọn si ti jẹ ki Akọwe ipinlẹ, Abubakar Kalgo, mọ pe awọn n bọ.

PDP Osun: Alaga PDP l'Osun, Sunday Bisi, sọ pe ipinlẹ Osun yoo kopa ninu ipade ẹka Wike.

"Mo ti maa n lọ sipade wọn tẹlẹ, mo si maa gbiyanju lati kopa ninu eyi naa."

O kere tan, aṣoju to to ẹgbẹrun meji aabọ ni wọn n reti nibi ipade naa.

Ṣaaju ni Nyesom Wike naa ti sọ pe aaye wa fun ẹnikẹni lati darapọ mọ PDP, nitori Aburada awọn tobi daadaa.

Wike sọ pe ẹjọ ti igun Kabiru Turaki gbe lọ sile ẹjọ to ga julọ ko ni nnkan kan lati ṣe pẹlu ipade oun yii, o ni ko di ara wọn lọwọ rara.

Tẹ o ba gbagbe, ọjọ Ẹti ati ọjọ Abamẹta ana ni ẹgbẹ oṣelu APC naa ṣe ipade apapọ tiwọn niluu Abuja.