Làáṣìgbò míì wáyé ní Jos bí Tinubu ṣé ń ṣàbẹ̀wò ìbánikẹ́dùn síbẹ̀ lónìí lórí ìkọlù agbébọn

Oríṣun àwòrán, Bayo Onanuga/X
Ibẹru-bojo tun gbalẹ niluu Jos tii ṣe olu ilu ipinlẹ Plateau lẹyin iroyin kan to sọ pe rogbodiyan mii tun bẹ silẹ l'Ọjọru ọjọ kinni oṣu Kẹrin ọdun yii nibi ti eeyan kan ti ku.
Eleyii ṣẹlẹ lẹyin tawọn agbebọn ti kọkọ ṣekupa eeyan mẹrindinlọgbọn lẹkun ariwa ilu naa ti ijọba si ti kede ofin konle-o-gbele latari isẹlẹ naa.
Iroyin ti a gbọ ni pe awọn eeyan kan tun ti ṣekupa eeyan kan eyi to mu ki ibẹru-gbojo tun gbalẹ sii.
Ohun ti awọn araalu sọ ni pe lagbegbe Nasarawa Gwom ni o ṣee ṣe ki awọn ọdọ kan ti ṣekupa eeyan naa.
Iṣẹlẹ yii ni a gbọ pe o ti jẹ kawọn eeyan to n gbe lẹgbẹ agbegbe naa bii Farin Gada, Terminus, Gada Bui ati Filin Ball sa kuro nibi ti wọn n gbe.
Ọjọru ni ijọba dẹ ofin konle-o-gbele ti wọn ni kawọn araalu maa rin lọsan
Fidio kan ti BBC ri lori itakun ayelujara ṣafihan bawọn eeyan ṣe n sa asala fun ẹmi wọn eyi to fa sunkẹrẹ fakẹrẹ ọkọ.
Awọn agbebọn ṣekọlu si agbegbe Angwan Rukuba ati Gari Ya Waye lẹkun ariwa ilu Jos to sun mọ ile ẹkọ giga fasiti UNIJOS.
Ileeṣẹ ọlọpaa ni nnkan bii ago meje aabọ irọlẹ lawọn janduku agbebọn naa de, ti wọn ṣi ṣina ibọn bolẹ lagbegbe naa.
Eeyan mejila nile iṣẹ ọlọpaa kọkọ sọ pe o ku ninu ikọlu naa, nigba to ya ni iroyin gbe e jade pe awọn to ti ku ti di eeyan mẹrindinlọgbọn.
Lẹyin ikọlu naa ni Gomina Caleb Mutfwang ipinlẹ Plateau kede ofin konle-o-gbele fun ọjọ meji ni ẹkun ariwa ilu Jos bẹrẹ lati oru ọjọ Aiku to kọja.
Lanaa Ọjọru ni ijọba dẹ ofin naa ti wọn si ni kawọn araalu maa rin lọsan.
Ẹgbẹ agbesunmọmi kankan ko ti sọ pe awọn lawọn ṣe ikọlu naa, awọn janduku agbebọn ni ijọba pe awọn to ṣe ikọlu naa.
Oriṣiiriṣii ikọlu bayii ti waye lọpọ igba niluu Jos laarin bii ogun ọdun sẹyin.
Ọpọ igba si lawọn eeyan to n gbe nibi ti ikọlu naa ba ti ṣẹlẹ maa n gbẹsan, eyi to maa n da rogbodiyan silẹ.
Tinubu fagile irinajo rẹ si Ogun, morile ilu Jos lẹyin iṣẹlẹ ipaniyan to waye nibẹ
Ẹwẹ, Aarẹ Bola Tinubu ti sun abẹwo rẹ si ipinlẹ Ogun lonii Ọjọbọ siwaju lati le ṣabẹwo ibanikẹdun si ilu Jos lẹyin ikọlu to waye nibẹ nibi ti eeyan mẹrindinlọgbọn ti padanu ẹmi wọn.
Tinubu gbe igbesẹ yii lẹyin to ṣepade pọ pẹlu Gomina Caleb Mutfwang nileeṣẹ ijọba l'Abuja lanaa Ọjọru lori eto aabo ipinlẹ naa.
Bakan naa ni ọga agba ọlọpaa, Tunji Disu, ti paṣẹ pe kawọn ọlọpaa muba ati ẹka ileeṣẹ ọlọpaa mii lọ si ipinlẹ naa lati pese eto aabo to peye.
Oludamọran aarẹ lori eto iroyin, Bayo Onanuga, lo fidi ọrọ yii mulẹ ninu atẹjade to fi sita nirọlẹ Ọjọru.
Onanuga ṣalaye ninu atẹjade naa wi pe Tinubu n lọ siluu Jos lati kẹdun pẹlu ijọba atawọn eeyan ipinlẹ naa lori iṣẹlẹ iṣekupani to waye ni Angwan Rukuba lẹkun ariwa Jos.
Oludamọran aarẹ ni Tinubu yoo lọ silu Eko fun ayajọ Ọjọ Ẹti rere, lati ibẹ si ni yoo ti lọ sibi ifilọlẹ papakọ ofurufu Gateway International Cargo Airport nipinlẹ Ogun lọjọ Abamẹta lopin ọsẹ yii.
Ṣaaju ni Gomina Mutfwang ti sọ fawọn akọroyin pe o ṣee ṣe ki aarẹ ṣabẹwo si ipinlẹ Plateau lati bawọn eeyan ipinlẹ naa kẹdun lori iṣẹlẹ ipaniyan to waye lopin ọsẹ to kọja.
Gomina ni iṣẹlẹ naa jẹ nnkan to ba Aarẹ Tinubu lọkan jẹ gidi gan an, ti o si fẹ wa si ilu Jos fun ra rẹ lati bawọn kẹdun.
Ṣaaju lọjọ Aje ni Tinubu ti kọkọ bu ẹnu ẹtẹ lu ikọlu naa, ti o si ṣeleri pe awọn to wa nidi rẹ yoo foju wina ofin.
Tinubu tun sọ pe oun ranṣẹ pe gomina ipinlẹ Plateau atawọn ọga ileeṣẹ ọmogun to fi mọ ọga ọlọpaa lati wa ojutuu si eto aabo to mẹhẹ ni ipinlẹ naa.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post

























