Iléeṣẹ́ aṣojú Nàíjíríà gbé kókó ọ̀rọ̀ mẹ́wàá jáde lórí ìwọ́de tó ń wáyé ní South Africa

Oríṣun àwòrán, SABC SCREENGRAB
Ileesẹ asoju ilẹ Naijiria ni orilẹede South Africa ti sọrọ lori iwọde to n waye tako awọn ọmọ Naijiria ni orilẹede naa.
Nibayii, ileesẹ asoju Naijiria naa ti gbe ikilọ ati imọran onikoko mẹwa sita fawọn ọmọ Naijiria to n gbe nilẹ South Afrika tori iwọde to n waye.
Gẹgẹ bi a ti sọ fun yin saaju ohun to fa rogbodiyan naa lo nii se pẹlu bi wọn se fi asaaju ẹya Igbo kan jẹ lẹkun Eastern Cape.
Ninu atẹjade tillesẹ asoju Naijiria to wa nilẹ South Afrika fisita lọjọ Aje, to pe akori rẹ ni "Imọran fawọn ọmọ Naijiria to n gbe nilẹ South Afirika "lo ti rọ wọn lati mu eto abo wọn ni pataki, ki wọn maa sọra se lasiko pakaleke naa.

Oríṣun àwòrán, Nigeria High Commission
"Ẹ fi orí ara yín pamọ́, ẹ yàgò síwà ṣekárímí àti àfihàn ọrọ̀"
Bakan naa, o tun rọ wọn lati maa foju sọri nigba gbogbo, se irinkerindo wọn ni iwọntunwọnsi, ki wọn si mu adinku ba ibasepọ wọn pẹlu awọn eeyan ti wọn ko mọ.
Ileesẹ asoju Naijiria naa tun rọ awọn ọmọ Naijiria lati fori ara wọn pamọ fun igba diẹ, ki wọn maa bọwọ fun ofin, ki wọn si tun bọwọ fun asa awọn ọmọ onilu.
Awọn ọmọ orilẹede Naijiria yii si tun ni wọn gba niyanju lati yago ketekete si iwọde tabi ifẹhonuhan, iwa sekarimi ati asehan ni gbogbo ọna.
"Gbogbo awọn ọmọ Naijiria le kan si ileesẹ asoju Naijiria to w ani Pretoria tabi Asoju agba to wa nilu Johannesburg fun alaye lori aabo wọn to ba pọn dandan.

Oríṣun àwòrán, Screen shot
Àlàyé rèé lórí ohun tó fá ìwọ́de táwọn ọmọ onílùú ṣe sí ẹ̀yà Igbo láti Nàíjíríà torí bí wọn ṣe jẹ ọba nílẹ̀ South Africa
Mọto mẹwa ni wọn jo kanlẹ lasiko iwọde kan ńlá kan ti bẹ́ sílẹ̀ ní ẹkùn ìlà oòrùn Eastern Cape ní South Africa lẹ́yìn ètò ìfinjoyè kan táwọn ọmọ Nàìjíríà kan ṣe ní ẹkùn náà.
Bakan naa, ọmọ onilu kan ni ọkan ninu awọn ajeji gun oun lọbẹ, ti oun si fara gba ọgbẹ lasiko ifẹhonuhan ọhun.
Àwọn fídíò tó gba orí ayélujára ṣàfihàn pé ìfẹ̀hónúhàn náà ṣe ti di wàhálà ńlá, táwọn olùfẹ̀hónúhàn náà sì ń dáná sun àwọn dúkìá tó jẹ́ ti aládàni.
Ìfẹ̀hónúhàn yìí ló ń wáyé lẹ́yìn ọjọ́ díẹ̀ tí wọ́n fi ọkùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Solomon Ogbonna Eziko jẹ oyè olórí ẹ̀yà Igbo East London.
Àmọ́ ètò ìfinijoyè náà dá awuyewuye sílẹ̀ lórí ayélujára bí ẹgbẹ́ àwọn olóyè kan ṣe jáde pé ó lòdì sí àṣà láti máa fi èèyàn jẹ ọba ní agbègbè tó ní àwọn lọ́balọ́ba tó ń darí ibẹ̀.
Gẹ́gẹ́ bí alága ẹgbẹ́ àwọn olóyè, Eatern Cape House of Traditional and Khoisan Leaders, ECHTKL , Nkosi Mpumalanga Gwadiso ṣe sọ fún àwọn akọ̀ròyìn, ó ní agbègbè náà ló wà ní abẹ́ ìdarí ẹkùn amaRharhabe, èyí tí Ọba Sandile ń ṣe àkóso rẹ̀.
"Inú ń bí mi pé àwọn ọmọ Nàìjíríà le wá láti máa wá pe ara wọn ní orílẹ̀ èdè míì"
Iléeṣẹ́ ìròyìn orílẹ̀ èdè South Africa, SABC sọ pé àwọn ẹgbẹ́ tí kìí ṣe ti ìjọba ní ìlú KuGompo àtàwọn olùgbé Eastern Cape ni wọ́n ṣe ìfẹ̀hónúhàn náà, tí wọ́n sì dí gbogbo òpópónà pa.
Wọ́n ní iléeṣẹ́ tó ń rí sí ọ̀rọ̀ ìṣèjọba àtọ̀rọ̀ oyè, tó fi mọ́ àwọn aláṣẹ agbègbè náà ti bu ẹnu àtẹ́ lu ìgbésẹ̀ náà.
Ọmọọba Xhanti Sigcawu tó wá láti ìdílé oyè Amathole sọ pé, níṣe ló yẹ kí wọ́n lé gbogbo àwọn tó lọ́wọ́ lórí ọ̀rọ̀ oyè jíjẹ náà.
Bí ó ṣe sọ pé inú ń bí òun pé àwọn ọmọ Nàìjíríà le wá láti máa wá pe ara wọn ní orílẹ̀ èdè míì.
Zolile Williams, tó jẹ́ alákòóso iléeṣẹ́ tó ń rí sí ọ̀rọ̀ oyè ní Eastern Cape sọ pé iléeṣẹ́ náà kò lọ́wọ́ nínú fífi àwọn èèyàn ilẹ̀ òkèèrè jẹ oyè ní ẹkùn náà.
Èyí ló ń wáyé lẹ́yìn tí ẹgbẹ́ àwọn ọmọ Nàìjíríà tó wà ní South Africa ń gbìyànjú láti ṣàlàyé ohun tí jíjẹ Ọba Nàìjíríà ní East London túmọ̀ sí gan-an.
Wọ́n ní oyè náà kàn jẹ́ láti gbé àṣà ilẹ̀ Nàìjíríà lárugẹ láàárín àwọn ọmọ Nàìjíríà tó ń gbé nílẹ̀ òkèèrè lásán ni àti pé kò ní nǹkankan ṣe pẹ̀lú ìlànà oyè jíjẹ orílẹ̀ èdè n;áà.
Ààrẹ àwọn ọmọ Nàìjíríà tó wà ní South Africa, Nwobi Smart sọ fún iléeṣẹ́ ìròyìn SABC pé ẹni tí wọ́n fi jẹ oyè náà ló máa ń dàbí alárinnà láàárín ìjọba àti àwọn ọmọ Nàìjíríà tó ń gbé orílẹ̀ èdè náà.
Ó ní tí ìjọba bá fẹ́ bá àwọn ọmọ Nàìjíríà sọ̀rọ̀ tàbí tí èèyàn kan bá ṣe aṣemáṣe láàárín wọn, ẹni tó jẹ́ olóyè yìí ló máa jẹ́ alárinnà láti yanjú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀.

Oríṣun àwòrán, Screen shot


























