'Ọdún tó kọ́já ni mo bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ Akéwì, bí mo ṣe wá ṣe kòńgẹ́ ire tí mo ń lọ Cotonou, Eko àti gbogbo ìlu ...'
N i awọn ipinlẹ to wa nilẹ Yoruba, arabinrin kan wa to ti di ilumọka to jale jako tori iṣẹ ewi to yan laayo.
E yinju Olodumare ni ọpọlọpọ mọ ọ si amọ orukọ rẹ gangan ni Folorunsho Arike.
I ṣẹ Akewi ti wa di ọna kan to n gba pa owo wọle amọ kii ṣe pe ko ni ipenija tirẹ naa.
" Taa ba lọ ibi inawo, ẹẹ maa gbọ ti MC a maa ni, awọn elewi yẹn da ti wọn pe, iṣẹju marun pere lo ni... Wọn o kaa kun".

E yinju ṣalaye pe iwa yii ti awọn atọkun eto maa n hu ko dara amọ awọn ni ireti ninu awọn eeyan to jẹ wipe boo ba ṣe n ki wọn, ori wọn a maa wu ti awọn mii a si maa bu owo tabua jade.
E yinju eledumare wa gba awọn eeyan nimọran lati jẹ ki iṣẹ ewi naa gbalẹ kan ko tan kaakiri gẹgẹ bi iṣẹ awọn olrin ṣe maa n tan ki wọn si ma foju kere ewi to jẹ aṣa ilẹ Yoruba.
























