Mo tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ẹ̀yin ọmọ Naijiria fún iná ọba tí kò sí lásìkò yìí- Adelabu

Oríṣun àwòrán, Adebayo Adelabu/X
Latari ai si ina mọnamọna deede lorilẹede Naijiria mọ, ti ko si agbegbe kan to le fọwọ sọya pe oun n ri ina ọba lo daadaa mọ, Minisita eto agbara, Adebayo Adelabu, ti ni kawọn ọmọ Naijiria dakun fi ori jin oun.
Ọjọ Iṣẹgun ana ni Adelabu bẹbẹ naa niluu Abuja, lasiko ipade awọn oniroyin to ba wọn ṣe.
Adelabu ṣo pe oun paapaa mọ pe ai si ina ọba deede yii n ṣe akoba pupọ fun ọrọ aje awọn eeyan, ka ma ti i sọ ti ooru buruku to n mu lasiko yii lai ṣiwọ.
"Mo fẹ bẹ ẹyin ọmọ Naijiria pẹlu ipo mi gẹgẹ bii minisita eto agbara, fun ti iṣoro aisina to n waye lọwọ, to si n mu inira dani, paapaa lasiko ẹẹrun yii, ti ooru n mu gidi kaakiri.
"O n kan awọn okoowo, ile ẹkọ ati awọn ileeṣẹ pẹlu. Ko wu awa naa ka ba ara wa niru ipo yii, ṣugbọn awọn idi kan to kọja agbara wa lo n fa a."
Bẹẹ ni Minisita eto agbara forilẹ ede Naijiria naa ṣalaye.
"Nigba ti yoo ba fi to ọsẹ meji si asiko yii, ina a maa wa daadaa"
Ni itẹsiwaju ọrọ rẹ, Adelabu sọ pe inira aisi ina yii ki I ṣe ohun ti yoo pẹ lọ titi.
O ni awọn ti gbe igbimọ kan kalẹ ti yoo ri si opin iṣoro yii.
"Mo le sọ fun yin pe pẹlu igbimọ ti a ti gbe kalẹ, atawọn igbimọ to wa lati ọdọ awọn to n pese afẹfẹ gaasi, pẹlu asiko ti wọn yoo fi tun awọn ọpa gaasi ṣe, nigba ti yoo ba fi to ọsẹ meji si asiko yii, o ti yẹ ka maa ri iyatọ."
Adelabu sọ pe gbogbo ohun ti yoo mu ki ina mọnamọna maa wa deede bo ṣe ri ni 2025, to bẹẹ ti awọn ọmọ Naijiria n ki ijọba kuuṣẹ, ni awọn ti n ṣiṣẹ nipa rẹ, ki ina le maa wa bii ti ọdun to kọja.
O fi kun un pe ijọba apapọ n ṣiṣẹ tọ ipese ina onimẹgawaati ẹgbẹrun mẹfa (6,000 megawatts) ki ọdun 2026 too pari.
Adelabu sọ pe idakureku ina asiko yii, fun igba diẹ ni.
"Bi a ba le pese iru ina to wa daadaa ni 2025 yẹn, 2026 ree, a fẹ ṣe daadaa ju bẹẹ lọ."
Adelabu lo sọ bẹẹ.
Band A, B ati C lásìkò yìí
Tẹ o ba gbagbe, ẹka ina mọnamọna Naijiria ti n koju awọn iṣoro bii: aito gaasi, awọn nnkan eelo ti ọdun wọn ti pẹ, iṣoro ina pinpin ka ati bẹẹ bẹẹ lọ fun igba pipẹ.
Lori rẹ naa ni ijọba bẹrẹ eto to pin bi araalu yoo ṣe maa lo ina ati iye owo ti wọn yoo maa san.
Wọn pin in si isọri bii Band A, B ati C.
Ṣugbọn pẹlu idakureku ina asiko yii, gbogbo isọri naa ni ko ri ina ọba lo, kaluku si n ke irora labẹ ooru buruku to n mu.
Oju ọjó to yi pada, afẹfẹ ti ko fẹ bii ti tẹlẹ mọ, ati awọn onina to tun n mu aye nira fun wọn pẹlu ai rina lo.

























