Wo bí ìgbẹ́jọ́ àwọn afurasí méje tó dáná sun ilé Asabi Olórìṣà n'Ilọrin ṣe lọ

Toyin Asabi Olorisa wọ aṣọ ankara, o si we sikaafu funfun niwaju ile rẹ ti wọn dana sun
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6

Igbẹjọ awọn afurasi meje ti ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kwara ge lọ si ile-ẹjọ fun ẹsun didana sun ile iya onisẹse kan, Asabi Olorisa tẹsiwaju lonii ọjọ Ọjọru, ọjọ kẹrindinlogbọn oṣu yii.

Igbẹjọ naa bẹrẹ lago mẹsan aarọ kọja diẹ labẹ adajọ Gafaru Mahmud ti ile ẹjọ giga ipinlẹ Kwara ni ilu Ilọrin.

Gbogbo awọn olujẹjọ meje naa ati olupejọ ni wọn farahan niwaju ile-ẹjọ.

Orukọ awọn olujẹjọ naa ni Alhaji Yẹkini Ọlọruntẹlẹ to jẹ alaga ẹgbẹ awọn onile lagbegbe Isalẹ Koko Ọja gbọrọ.

Awọn toku ni Saliu Usman,Garuba Amuda, Alhaji Mumini Shọla,Imam Isiaq Raji, Alhaji Saliu Abubakar, Abdulmumuni Muhammed.

Bí ìgbẹ́jọ́ ṣe lọ ní ilé-ẹjọ́ n'Ilorin

Lẹyin ti akọwe ile ẹjọ ka orukọ wọn tan, awọn agbẹjọro bẹrẹ afihan ara wọn.

Agbẹjọro ijọba lati ile iṣẹ eto idajọ ipinlẹ Kwara, Babatunde Afọlayan lo ko awọn agbẹjọro ijọba sodi.

Arabinrin Toyin Asabi iya Olorisa lo kọkọ rojo niwaju ile ẹjọ.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Agbẹjọro bi Asabi leere pe ṣe o da gbogbo awọn afunrasi mọ, o si ni bẹẹ ni.

Asabi Olorisa ni ninu Oṣu kọkanla ni ọkan lara awọn olujẹjọ agbeyangi ran ọmọ rẹ si oun lati wa bi oun ṣe debẹ oun ba awọn mẹsan ni ibẹ ni ile agbeyangi.

Adajọ sọ pe ṣe iya naa da ẹni to sọ fun pe wọn jo ile rẹ bi koba ko kuro ilu Ilọrin.

Asabi Olorisa ni olujẹjọ keji sọ fun oun pe awọn ti fẹ le oun ni Ilọrin tẹlẹ ṣugbọn tori pe oun ti kọle .

O tẹsiwaju pe afunrasi keji sọ fun oun pe bi wọn ba jo ile rẹ owa bi igbalọ .

Asabi Olorisa ni oun ṣi gba agọ ọlọpaa ọja Ọba ilu Ilọrin lọ pe awọn kan ni awọn o Jo Ile oun.

Pẹlu alaye pe awọn ọlọpaa pe wọn pe ki wọn mọn jẹ ki wala ṣẹlẹ.

O fi kun pe awọn ọlọpaa ṣe pe oun lori ẹrọ ibanisọrọ pe awọn ti ba wọn sọrọ pe koni si wala.

O salaye pe lọjọ kini oṣu kini ọdun yii ni gba ti oun lọ ile ọdun ni wọn pe oun lori ẹrọ ibanisọrọ pe ile oun jona ni ilu Ilọrin.

Oun pariwo pe ha wọn sọ bẹ wọn si se bẹ nna.

Ọjọ keji Oṣu kini ọdun yii ni o de pada si ilu Ilọrin ti oun ṣi ri pe ile oun ti jona tan yanyan .

Oun si gba agọ ọlọpaa Ọja Ọba lọ lati lọ fi ẹjọ sun .

O ni lara awọn ikan to jona ni Ẹrọ Ilọta,Asọ,masinni Irnsọ mẹta,Iwe ẹri,Golu, Ẹrọ amunle tutu( AC) Ẹrọ amun ohun tutu( Frezer)koko Irin,Awo,ati bẹbẹ lọ.

O fikunpe pe awọn ọlọpaa ni dandan ni ki awọn to wu iru iwa yi foju ba ile ẹjọ.

Ti ajọ ọlọpaa si lọ mun awọn meje naa tori awọn mẹsan ni wọn jo ile naa.

Agbẹjọro olujẹjọ ni o le jẹ ina ọba lo jo ile Asabi Oloriṣa

Agbẹjọro olujẹjọ ni niwọn igba ti Asabi Olorisa ti sọ pe oun lo ina mọnamọna ninu ile oun tori naa o le jẹ ina ọba lo jo ile.

Aṣabi Olorisa ni awọn NEPA ti ja ina ile oun, wọn si ti ko waaya oun lọ nitori oun jẹ owo ina.

Ọlọpaa agbefọba sọ pe lọjọ keji osu kiní ọdún yi ni Aṣabi Olorisa wa fi ẹjọ sun agọ ọlọpaa ọja ọba ni ilu Ilọrin pe awọn kan jo ile oun.

O tẹsiwaju pe Aṣabi Olorisa ti wa fẹ jọ sun tẹlẹ pe wọn ni oun o gbọdọ ṣe iṣẹnse mọn.

Ọlọpaa Onifade Elizabeth ni lẹyin ti Aṣabi Olorisa wa fẹjọsun tan ni awọn lọ mun awọn afurasi naa.

Lẹyin naa ni awọn gbe ẹjọ naa lọ si ẹka ọtẹlẹmuyẹ ajọ ọlọpaa ipinlẹ Kwara (CID).

Ọlọpaa naa ni ọga ọlọpaa awọn tẹlẹ ni iya Aṣabi Olorisa kọkọ fẹ jọ sun pe wọn dun koko mọn oun pe ki oun fi iṣẹnse kalẹ.

Ẹleri keji wọle, Bisi Balogun Muhammad to je Ọlọpaa agbefọba lati ẹka ọtẹlẹmunyẹ ajọ ọlọpaa ipinlẹ Kwara.

O salaye pe awọn mẹrin ni awọn mun lori ẹsun didana sun ile Asabi Olorisa..

O si ṣafihan iwe ti wọn fi gba ọrọ silẹ lẹnu awọn ifunra si naa.

Ẹleri kẹta ni inspector Adegoke Bamidele lati ẹka ọtẹlẹmunyẹ (CID)

ajọ ọlọpaa ipinlẹ Kwara.

O salaye pe lọjọ kẹta oṣu kini ọdun yii ni wọn ọlọpaa ọjà ọba ní Ilọrin gbe ẹjọ wa Aṣabi Olorisa ni awọn kan dun koko mọ oun losu kọkanla ọdun to kọja pe awọn o Jo ile oun.

Ti ile naa si Jona lọjọ kini oṣu kini ọdun yii.ti awọn ṣi lọ sí ile naa lati lọ wo Asabi Olorisa sí darukọ awọn to wa ni idi iṣẹlẹ naa.

Agbefọba sì fi ìdí iwe ti wọn fi gba ọrọ ẹnu awọn afunrasi mun lẹ.

Ọlọpaa agbefọba fìdí rẹ munlẹ ni ile ẹjọ pe kosi ina lati bi ọsẹ meji sẹyin lagbegbe naa ki iṣẹlẹ naa to sẹlẹ.

Lẹyin ọpọlọpọ wakati ile ẹjọ sun igbẹjọ siwaju di ọjọ kejidinlogun oṣu karun ọdun yii.

Òní ni ìgbẹ́jọ́ àwọn tí wọ́n fẹ̀sùn kàn pé wọ́n dáná sun ilé Asabi olórìṣà n'Ilọrin

Toyin Asabi Olorisa ati ile rẹ ti wọn dana sun

Owurọ oni, ọjọ kẹrindinlọgbọn oṣu Kẹta ọdun 2026 ni igbẹjọ awọn eeyan ti wọn fẹsun kan pe wọn dana sun ile iya Oniṣẹṣe kan; Toyin Asabi Olorisa, yoo maa tẹsiwaju nile ẹjọ, niluu Ilorin.

Tẹ o ba gbagbe, lati oṣu Kin-in-ni ọdun 2026 yii ni igbẹjọ naa ti bẹrẹ nile ẹjọ giga ipinlẹ Kwara.

Eeyan meje lo n koju igbẹjọ naa pẹlu bi wọn ṣe fẹsun kan wọn pe wọn mọ nipa bi odidi ile ṣe jona raurau lasiko ti Asabi Oloriṣa ko si nile, to lọ ṣe ọdun niluu rẹ.

Ẹ o ranti pe ọjọ kin-in-ni oṣu, Kin-in-ni ọdun yii gan-an ni awọn kan lọ dana sun ile Asabi Olorisa lasiko to lọ sile ọdun.

Ile ọdun naa ni iya yii wa ti wọn ti pe e lori foonu pe gbogbo ile rẹ ti jona pata.

Nigba ti Asabi de to ba ile rẹ to ti jona lo figbe ta pe awọn Musulumi kan laduugbo oun lo dana sun ile koun too de.

Iya naa sọ pe oun ko ṣe ọdun Iṣẹṣe n'Ilorin, oun gbe e lọ siluu abinibi oun ni.

O ni iyalẹnu lo wa jẹ pe oun ko ti i de lati ile ọdun naa ti awọn kan ti sọ ina si ile toun kọ, ti gbogbo rẹ si jo kanlẹ.

Asabi Oloriṣa ke sawọn Oniṣẹṣe ẹgbẹ rẹ nigba naa lati ma ṣe jẹ ki iya yii jẹ oun gbe, o ni nitori bawọn to ṣiṣẹ naa ba mu un jẹ bẹẹ, a jẹ pe oju ti awọn Oniṣẹṣe niyẹn.

Latigba naa lọrọ ti de kootu, ti wọn si ti n ba igbẹjọ ọhun bọ pẹrẹwu.

BBC News Yoruba yoo maa mu àbọ̀ kootu naa wa fun yin bo ba ṣe lọ lonii.