Ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí ẹni tí kò bá dìbò fún Tinubu lọ́dún 2027 rè é - Portable

Oríṣun àwòrán, @portablebaeby/Instagram
Ẹnu kìí sìn lára ẹni tó bá fọ́ ike ìbomi.
Gbajúmọ̀ olórin tàkasúfèé nnì, Habeeb Okikiola tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Portable tún ti di ẹni tí wọ́n ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ lórí ayélujára lẹ́yìn tó tún gbé fídíò kan jáde.
Níṣe ni ẹnu tún bẹ̀rẹ̀ sí ní kun Portable lẹ́yìn tó sọ pé gbogbo àwọn ọmọ Yorùbá gbọdọ̀ dìbò fún Ààrẹ Nàìjíríà, Bola Tinubu fún sáà kejì níbi ètò ìdìbò ọdún 2027.
Nínú fídíò kan tí akọrin náà gbé sójú òpó Instagram rẹ̀ ló ti ń sọ àwọn ọ̀rọ̀ àlùfàńṣà, tó sì ń sọ̀rọ̀ sí àwọn tí kò bání dìbò fún Tinubu lọ́dún 2027.
Ó ní gbogbo àwọn tí wọ́n bá gbowó lọ́wọ́ ààrẹ tàbí jẹ nínú owó rẹ̀ ni wọ́n gbọdọ̀ dìbò fún-un níbi ètò ìdìbò náà.
"A nílò àlááfíà, tí ẹ ò bá ti fẹ́ ogun ní Nàìjíríà, ẹ tẹ̀lé Tinubu o, mi ò fẹ́ wàhálà o, Yorùbá ló ń lọ ní ẹlẹ́kèejì o.
"Ègbé ni fún ọmọ Yorùbá tí kò tẹ̀lé Tinubu," Portable sọ.
Ó ní òun ti gba aṣọ láti ṣe ìpolongo fún Tinubu tó sì jẹ́ pé nígbà tí òun bá ti rí owó gbà, òun máa pín oúnjẹ fún àwọn èèyàn láti ṣe ìpolongo fún Tinubu.
Ó wòye pé dídìbò fún Tinubu ló máa mú ìrọ̀rùn bá orílẹ̀ èdè Nàìjíríà àti pé òun ló máa ìrọ̀rùn bá àwọn aráàlú.
Ta a ni Portable, Were Olorin, Idaamu Adugbo?
Ọmọ bibi ilu Abeokuta ni Habib Okikiola ti a mọ si Portable, amọ adugbo Sango Ota ni wọn bi si, to si gbe Mushin Olooṣa dagba.
Ni ipari ọdun 2021 ni Habeeb Okikiọla kan lu agbami orin takansufe kikọ, nigba ti orin to kọrin pẹlu gbajumọ olorin Ọlamide ati gbajumọ onijo kan, ti ọpọ mọ si Pocolee.
Orin Zeh to kọ naa, ti di gbajugbaja kaakiri agbaye, to si ti yi igbe aye rẹ pada.
Lati igba ti orin rẹ naa si ti di aigbọdọ maa kọ nibi ariya ati ile ijo gbogbo ati lẹnu tonile talejọ, Portable ti ṣe alabapade awọn agbaagba onkọrin bii Wizkid ati Davido.
Portable sọ fun BBC News Yoruba pe ọdun kẹẹdogun ree ti oun ti bẹrẹ isẹ orin kikọ amọ ọdun kẹwa ree ti oun ti di gbajumọ, ki Ọlọrun to wa ni ko orin Zeh.
Nigba to n salaye awọn ohun ti oju rẹ ti ri sẹyin, Portable salaye bi awọn eeyan bii ọdunrun se dawọ bo o, lati ja si ihooho ọmọluabi lori ẹsun pe o ji kẹkẹ Maruwa.

























