Èmi ṣì ni alága NURTW- MC Oluomo

MC Oluomo wọ aṣọ funfun, ó dé fìlà olómi aró, ó ń wo ọ̀ọ́kán

Oríṣun àwòrán, @officialkingmcoluomo/Instagram

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Tani o yọ MC Oluọmọ kuro nipo alaga fun awọn ẹgbẹ awakọ oju popo ni Naijiria?

Alhaji Musiliu Ayinde Akinsanya tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí MC Oluomo ti tẹnumọ pe òun ṣì ni ààrẹ àpapọ̀ fún ẹgbẹ́ àwọn onímọ́tò, National Union of Road Transport Workers, NURTW.

Oluomo ló ń sọ̀rọ̀ yìí lẹ́yìn tí ìròyìn ti kọ́kọ́ gbòde lọ́jọ́ Ajé, ọjọ́ Kẹtàlélógún, oṣù Kẹta pé Tajudeen Baruwa ti gba àkóso ilé ẹgbẹ́ náà tó wà ní ìlú Abuja.

Báyìí ni ọ̀rọ̀ dé dúró lórí ìfaǹfà tó ń wáyé láàárín Baruwa àti MC Oluomo lórí ipò alága NURTW

Ṣáájú ni ìròyìn tí kọ́kọ́ gbòde pé Baruwa àti àwọn èèyàn rẹ̀ yawọ ilé ẹgbẹ́ NURTW tó wà ní Abuja tí wọ́n sì fẹ́ àkóso ilé ẹgbẹ́ náà pé òun ni ilé ẹjọ́ dájọ́ pé òun ó jẹ́ ojúlówó alága ẹgbẹ́ náà.

Ṣùgbọ́n, MC Oluomo nínú àtẹ̀jáde kan tó fi sórí ìkànnì Instagram rẹ̀ lọ́jọ́ Ajé kan náà sọ pé Baruwa àtàwọn èèyàn rẹ̀ fẹ́ fi ipa gba àkóso ẹgbẹ́ náà àti pé ìgbẹ́jọ́ ṣì ń lọ nílé ẹjọ́ lórí ẹjọ́ náà.

Oluomo sọ pé òun kò sí lára olùjẹ́jọ́ níbi ẹjọ́ tí Baruwa sọ pé òun gba ìdájọ́ lórí rẹ̀ àti pé òun àti Baruwa kò ì tíì ní àjọsọ kankan tklẹ̀ rí.

Ó ní òun tí òun mọ̀ ni pe ìgbẹ́jọ́ ṣì wà nílé ẹjọ́ àti pé àwọn agbófinró ti ń dá sí ọ̀rọ̀ náà.

Ẹ ó rántí pé láti bíi ọdún méjì sẹ́yìn ni ìfaǹfà ti ń wáyé nínú ẹgbẹ́ NURTW lẹ́yìn tí wọ́n ṣe àpérò níbi tí wọ́n ti dìbò yan àwọn olórí tuntun.

Àmọ́ lẹ́yìn ìgbà náà ni Baruw agba ilé ẹjọ́ lọ lórí ètò ìdìbò náà tó sì sọ pé ilé ẹjọ́ ti dá òun láre pé òun ni alága ẹgbẹ́ náà báyìí.

Èyí ló sì ṣokùnfà bí ó ṣe kó àwọn èèyàn rẹ̀ lọ sí ilé ẹgbẹ́ náà láti lọ gba àkóso ẹgbẹ́ ṣùgbọ́n tí wàhálà bẹ́ sílẹ̀ lásìkò tí wọ́n fẹ́ gba àkóso náà.

A kò yìnbọn mọ́ ẹnikẹ́ni - iléeṣẹ́ ọlọ́pàá Abuja

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìlú Abuja ti wá jiyàn ìròyìn tó gba orí ayélujára pé àwọn ọlọ̀pàá yìnbọn mọ́ àwọn èèyàn Baruwa lásìkò tí ìfaǹfà wáyé nílé ẹgbẹ́ náà.

Àtẹ̀jáde tí agbẹnusọ ọlọ́pàá Abuja, Josephine Adeh fi léde lọ́jọ́ Ajé sọ pé ìròyìn òfégè ni pé àwọn ọlọ́pàá lọ ṣíná ìbọn bolẹ̀ níbi ètò náà.

Adeh sọ pé àwọn ọlọ́pàá lọ sí ilé ẹgbẹ́ NURTW nígbà tí àwọn gba ìpè láti lọ dẹ́kun ìṣẹ̀lẹ̀ tó ń wáyé ní agbègbè, Garki II, ìlú Abuja.

Ó ní nǹkan bíi aago méje òwúrọ̀ ọjọ́ Ajé ni àwọn gba ìpè pé àwọn èèyàn kan tí wọ́n tó ọ̀ọ́dúnrún kó àdá, ìgò, àti ọfà dání láti lọ dá wàhálà sílẹ̀ ní ilé ẹgbẹ́ NURTW, táwọn èèyàn náà sì ń jí nǹkan kó nílé ẹgbẹ́ náà.

Ó ṣàlàyé pé igbákejì ọ̀gá ọlọ́pàá tó wà fún iṣẹ́ ṣíṣe ló ṣáájú àwọn ọlọ́pàá láti lọ wá ojútùú sí ohun tó ń ṣẹlẹ̀ níbẹ̀.

Ó ní ìwádìí àwọn ọlọ́pàá nígbà tí wọ́n dé ibi ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣàfihàn pé àwọn èèyàn náà fk gba àkóso ilé ẹgbẹ́ náà pẹ̀lú àṣẹ ilé ẹjọ́ láì sí òṣìṣẹ́ ilé ẹjọ́ kankan tó tẹ̀lé wọn.

Ó ṣàlàyé pé wàhálà bẹ́ sílẹ̀ nígbà tí ikọ̀ MC Oluomo kọ̀ láti fún àwọn èèyàn náà láàyè láti ṣe ohun tí wọ́n fẹ́ ṣe láti gba àkóso ilé ẹgbẹ́ náà.

Ágbẹnusọ ọlọ́pàá náà fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé àwọn afurasí méje ló ti wà ní àhámọ́ àwọn báyìí tó fi mọ́ Sulaiman A. Musa, Nasiru Ibrahim, Alhaji Sadisu Musa, Dalha Suleiman, Abdullahi Garba, Saheed Fojebi àti Ibikunle T. Baruwa, tí wọ́n nawọ́ gán níbi ìṣẹ̀lẹ̀ náà.