Ìjọba ìpínlẹ̀ Ondo gbé ìgbésẹ̀ tuntun nípa owó orí ayẹyẹ

Oríṣun àwòrán, Ebenezer Adeniyan/ODIRS
Ijọba ipinlẹ Ondo ti yi ohun pada lori ofin owo ori ayẹyẹ to kede ṣaaju nibi to ti sọ pe awọn araalu yoo maa san owo ori fun gbogbo ayẹyẹ ti wọn ba n ṣe.
Ajọ to n gba owo ori nipinlẹ naa, ODIRS, lo fi ikede naa sita.
Ikede ọhun lo n waye lẹyin ti ọpọ araalu bu ẹnu atẹ lu owo ori naa pe kii ṣe ohun to bojumu lasiko yii.
Pupọ ninu awọn eeyan naa, ti inu wọn ko dun si owo ori ọhun sọ pe kii ṣe ijọba ti ko ṣiṣe bo ṣe yẹ bii ti Aiyedatiwa lo yẹ ko tun maa fi aye ni awọn araalu lara pẹlu owo ori tuntun.
Ijọba ipinlẹ naa ti wa kede pe oun yoo gbe owo ori naa ti bayii fun awọn akoko kan.
Elo ni owo ori naa?
Owo ori naa ni ijọba Ondo sọ pe awọn eeyan gbọdọ maa san ti wọn ba ti n ṣe ayẹyẹ bii isinku, igbeyawo, isọmọlorukọ, oye jijẹ, ati bẹẹ lọ.
Bayii ni wọn ṣe to owo ori naa ati iye ti araalu yoo maa san lori ayẹyẹ kọọkan:
- Ayẹyẹ eto isinku: ₦25,000
- Igbeyawo: ₦25,000
- Ayẹyẹ isọmọlorukọ: ₦20,000
- Ayẹyẹ oye jijẹ: ₦20,000
- Ayẹyẹ ikẹkọọjade: ₦20,000
- Ayẹyẹ awọn ẹlẹgbẹjẹgbẹ: ₦20,000
- Eto isinku (aṣalẹ onigbagbọ): ₦20,000
- Oniruru ayẹyẹ miran: ₦50,000
- Awọn ayẹyẹ mii ti wọn ko kede: ₦20,000

Oríṣun àwòrán, ODIRS
Wayi o, adari ajọ ODIRS, Bayo Rojugbokan, ti kede ki wọn da mimuṣẹ ofin naa duro bayii.
O ni eredi ti oun fi kede ki wọn da owo naa duro ni lati fopin sisan owo ori lọna to pọ.
Lẹyin naa lo rọ awọn oniṣowo ipinlẹ ọhun ki wọn maṣe yẹsẹ ninu sisan owo ori wọn loorekoore.
O tun rọ awọn eeyan naa ki wọn maa lo oju opo 'i-Ondo' fun gbogbo ohun to ba jọ mọ owo ori sisan nipinlẹ ọhun.
























