Kókó àdéhùn méjì tí ìjọba Nàíjíríà àti UK tọwọ́bọ rèé lásìkò àbẹ̀wò Tinubu

Ààrẹ Nàìjíríà, Bola Tinubu àti olóòtú ìjọba UK, Sir Keir Starmer dúró, wọ́n ń ba ara wọn lọ́wọ́

Oríṣun àwòrán, Nigerian Presidency

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ìjọba United Kingdom ti tọwọ́bọ ìwé pẹ̀lú ìjọba Nàìjíríà láti máa fi tó àwọn aláṣẹ Nàìjíríà létí nígbà tí wọ́n ba fẹ́ lé àwọn ọmọ Nàìjíríà tí kò ní ìwé àṣẹ láti wà ní orílẹ̀ èdè náà.

Èyí ni yóò mú ètò náà rọrùn ju ti àtẹ̀yìnwá lọ gẹ́gẹ́ bí àdéhùn náà ṣe sọ.

Fún ìgbà àkọ́kọ́, ìjọba Nàìjíríà yóò máa gbà láti ṣàmúlò lẹ́tà láti UK – èyí tó ṣe é ṣàmúlò fún àwọn tí kò bá ní ìwé ìrìnnà.

O túmọ̀ sí pé àwọn tó bá fẹ́ pada sile kò ní ṣẹ̀sẹ̀ máa dúró de ìwé ìrìnnà fún ìgbà pípẹ́, kí wọ́n tó padà sí orílẹ̀ èdè wọn.

Ìfẹnukò yìí ló wáyé nígbà tí Ààrẹ Nàìjíríà, Bola Tinubu ṣèpàdé pẹ̀lú olóòtú ìjọba ilẹ̀ UK láti àbẹ̀wò Tinubu sí orílẹ̀ èdè náà.

Àdéhùn tuntun yìí máa jẹ́ kó rọrùn láti dá àwọn èèyàn tó bá ti lo kọjá àkókò físà wọn padà sílé, tí wọ́n sì máa tètè dá àwọn ọ̀daràn láti ilẹ̀ òkèèrè mọ̀

Agbẹnusọ olóòtú ìjọba UK sọ pé àwọn olórí ìlú méjéèjì náà ní ìfarajìn láti ri dájú pé àjọṣepọ̀ tó wà láàárín orílẹ̀ èdè méjéèjì lórí ìdókoòwò, ìdàgbàsókè àti ohun amáyédẹrùn ń tẹ̀síwájú síi.

Bákan náà ni wọ́n fẹnukò láti ṣiṣẹ́ papọ̀ lórí ètò ààbò lójúnà àti dẹ́kun àwọn ìwà ọ̀daràn àti ìgbéṣùmọ̀mí ní orílẹ̀ èdè méjéèjì.

Iléeṣẹ́ ètò ìrìnnà UK sọ pé àdéhùn tuntun yìí máa jẹ́ kó rọrùn láti dá àwọn èèyàn tó bá ti lo kọjá físà wọn padà sílé, tí wọ́n sì máa tètè dá àwọn ọ̀daràn láti ilẹ̀ òkèèrè mọ̀.

Iléeṣẹ́ náà ní àwọn èèyàn tí wọ́n máa ń dá padà sí Nàìjíríà ní ọdọọdún ni iye wọn ti wọ 1,150 báyìí.

Orílẹ̀ èdè májéèjì tún jọ fẹnukò láti ṣiṣẹ́ papọ̀ láti lè máa nawọ́ gán àwọn ọ̀daràn tí wọ́n máa ń ṣe àṣìlò ètò ìrìnnà lọ sí ilẹ̀ òkèèrè.

Wọ́n ní àwọn máa ṣe àgbékalẹ̀ ìlànà tuntun èyí tí yóò máa ṣe àfihàn òótọ́ nípa àwọn tó bá fẹ́ rìnrìnàjò, tí yóò sì máa ṣpafihàn àwọn tí wọ́n bá lu jìbìtì tàbí gba ọ̀nà ẹ̀bùrú wọ orílẹ̀ èdè UK.

Bákan náà ni ìjọba Nàìjíríà ni àtúnṣe máa wáyé sí ìjìyà tó wà fún àwọn tó máa ń ṣèrú ètò ìrìnnà lọ sí ilẹ̀ òkèèrè.

Mínísítà fún ètò ààbò ẹnubodè àti wíwá ààbò lọ sílẹ̀ òkèèrè ní UK, Alex Norris sọ pé Nàìjíríà jẹ́ orílẹ̀ èdè kan tó ṣe gbòógì láti kojú ètò ìrìnnà lọ́nà àìtọ́.

Ó ní àwọn ọmọ Nàìjíríà ni ọmọ ilẹ̀ Africa tó pọ̀ jùlọ ní UK, tí ọ̀pọ̀ wọn ló sì ti ń gbé ìgbé ayọ̀ níbẹ̀.

Nàìjíríà àti UK tọwọ́bọ àdéhùn £746m láti ṣàtúnṣe àwọn pápákọ̀ ojú omi méjì ní Eko

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ṣáájú ni Ààrẹ Nàìjíríà, Bola Tinubu àti olóòtú ìjọba UK, Sir Keir Starmer ti ṣèpàdé ní Downing Street tí wọ́n sì buwọ́lu àdéhùn lórí kíkó irin wọ Nàìjíríà.

Nínú àdéhùn náà, Britain máa kó irin ìwọ̀n tóònù 120,000 ránṣẹ́ sí Nàìjíríà láti fi tún àwọn pápákọ̀ ojú omi ṣe ní ìpínlẹ̀ Eko, tí àkànṣe iṣẹ́ náà sì tó £70m.

Sir Keir kan sáárá sí àbẹ̀wò ààrẹ Nàìjíríà sí UK èyí tí irú rẹ̀ ti wáyé kẹ́yìn ní ọdún mẹ́tàdínlógójì sẹ́yìn.

UK buwọ́lu àdéhùn £746m pẹ̀lú Nàìjíríà láti ṣe àtúnṣe pápákọ̀ Lagos Port Complex àti TinCan Island Port Complex.

Iléeṣkẹ́ ètò ìsúná UK, UK Export Finance, iléeṣẹ́ ètò ẹ̀yàwo UK fún àwọn ilẹ̀ òkèèrè ti ṣe onídùúró fáwọn ilé ìfowópamọ́ tó máa pèsè ẹ̀yáwó náà pẹ̀lú àdéhùn pé UK ni wọ́n ti máa ra ìdá ogún (20%) nínú àwọn ohun èlò tí wọ́n fi máa ṣe iṣẹ́ náà.

Ìgbésẹ̀ yìí ló ń wáyé bí UK ṣe ń wá ọ̀nà láti mú àgbéga bá ẹ̀ka tó ń pèsè irin ní orílẹ̀ èdè náà.

Àbẹ̀wò Tinubu yìí ni ìgbà àkọ́kọ́ tí olórí orílẹ̀ èdè tó jẹ́ mùsùlùmí máa ṣe àbẹ̀wò sí UK lásìkò ààwọ̀ Ramadan láti bíi ọgọ́rùn-ún ọdún sẹ́yìn.