Toyosi Adesanya, òṣèré tíátà Yoruba, di ọlọ́mọ láyé fún ìgbà àkọ́kọ́ nípasẹ̀ ìlànà abánigbóyún

Oríṣun àwòrán, Biola Bayo/Instagram
Ariwo ayọ wọle tọ gbajugbaja oṣere tiata, Toyosi Adesanya ati ọkọ rẹ, Bola Oyinadejobi, nigba ti wọn bi ọmọ fun igba akọkọ pẹlu ilana abanigboyun.
Biola Bayo, oṣere tiata mii lo kede iroyin naa loju opo ayelujara Instagram rẹ, to si jẹ ko di mimọ pe tọkọtaya naa di ọlọmọ laye ni ilana abanigboyun.
Biola dupẹ lọwọ ọpọ eeyan to ti tọkọtaya naa lẹyin lati ọdun 2024 ti wọn ti bẹrẹ igbesẹ naa.
"Mo tun di iya lẹẹkan si !!!. A ku orire oo!
@officialadesanyatoyosi ati @bola_oyinade bi ọmọ obinrin lantilanti pẹlu ilana abanigbe oyun.
"A fẹ dupẹ lowọ gbogbo awọn to ti wa lẹyin lati igba ti a ti bẹrẹ irinajo yii ni ọdun 2024, paapa dokita wa, Dr Ivie ti @the_fertility_doctor. Ẹ ṣe adupẹ fun gbogbo nnkan ti ẹ ṣe fun dokita, ẹ ti wa lẹyin ninu irinajo yii.
"Ọlọrun yoo tunbọ ma ran yin lọwọ. Aunti Toyosi di ọlọmọ laye. Ọkan mi kun fun ayọ, Ẹ ṣe Jesu."
Wo awọn mii to bimọ ni ilana abanigboyun
Biola Bayo bi ọmọ rẹ akọkọ lẹyin ti ọpọ IVF lulẹ. O sọ gbogbo ohun to lakọja ko to di pe o bi ọmọ rẹ ọkunrin ni ọdun meji sẹyin.
Bakan naa ni ọdun 2025, gbajugbaja sọrọsọrọ, Toke Makinwa bi ọmọ rẹ akọkọ ni ẹni ogoji ọdun.
Ọga agba fun ileeṣẹ Royal Hugs Surprise, Oluwatoyin Deborah Oyesanya, naa lo ilana yii ni ẹni ogoji ọdun, to si di ọlọmọ laye.
Ni ọdun 2024, oṣere tiata mii, Dayo Amusa bi ọmọ ọkunrin lantilanti pẹlu ilana yii.
Lẹyin ọpọ ọdun ninu igbeyawo, oṣere tiata, Tawa Ajisefinni ati ọkọ rẹ bi ọmọ pẹlu ilana yii.
Ni ọdun 2023, oṣere Mount Zion, Doyin Hassan di ọlọmọ laye lẹyin ọdun mẹrinlelogun ninu igbeyawo ni ilana abanigboyun.
Ohun to yẹ ko mọ nipa Surrogacy
Idunnu ọpọ tọkọtaya ni pe lẹyin igbeyawo, ki wọn o ri ọmọ wọn gbe jo.
Ṣugbọn nigba miran, ọrọ kii ri bẹẹ, eyi to ma n waye nitori oriṣiriṣi nnkan to le fa airọmọbi fun tọkọtaya to wu lati bimọ.
Ni aye igba kan, ko fi bẹẹ si ọna abayọ si iṣoro airọmọbi ju pe ki tọkọtaya kun fun adura, gba itọju nileewosan tabi ni ilana ibilẹ. Awọn miran si ma n gba ọmọ ọlọmọ tọ, eyi ti wọn n pe ni 'Adoption' ni ede Gẹẹsi.
Amọ lasiko yii, paapaa lati bi ọdun melo kan, ilana iranlọwọ kan fun ọmọ bibi ti awọn eeyan tun n lo ni ki ẹlomiran ba wọn gbe oyun ọmọ wọn.
Ilana yii ni wọn n pe ni 'Surrogacy''.
Awọn onimọ iṣegun oinbo ma n fi ilana surrogacy lọ awọn obinrin to n woju Ọlọrun fun ọmọ, paapaa awọn ti ile ọmọ wọn ba ni ailera kan, eyi to mu ko nira fun wọn lati gbe oyun si ikun wọn.
Ẹlomiran naa tun le lo surrogacy boya nitori ko wu u lati gbe oyun si ikun, tabi ẹlomii to ni ailera ti ko le jẹ ko ni agbara lati gbe oyun.
Nitori imọ ijinlẹ tuntun yii, awọn ileeṣẹ kan wa to ma n ṣawari awọn obinrin to le ba obinrin akẹẹgbẹ wọn gbe oyun, ti awọn naa yoo si gba owo iṣẹ wọn


























