Mi ò ní í ṣe aláìní láyé mi, èmi àti Ọlọ́run nìkan la ní ọrọ̀ jù - Pásítọ̀ Chris Oyakhilome

Pasitọ Chris Oyakhilome

Oríṣun àwòrán, Pastor Chris Oyakhilome/ Facebook

Àkọlé àwòrán, Pasitọ Chris Oyakhilome
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ọkan lara awọn pasitọ to gbajumọ fun idi kan tabi ikeji lorilẹede yii ni Chris Oyakhilome, awọn ọrọ to maa n sọ nigba mi-in si kun idi ti orukọ rẹ fi maa n gba ori ayelujara kan.

Lara iru ọrọ naa ni eyi to fi lede bayii lasiko to n dari isin kan, Oyakhilome sọ pe Ọlọrun nikan ṣoṣo pẹlu oun ni awọn ni ọrọ ju ni gbogbo aye.

Nigba to n fidi ọrọ naa mulẹ, pasitọ ijọ Christ Embassy naa sọ pe o maa n ya oun lẹnu bi awọn eeyan ba n fi owo ati ipo aye ṣe odiwọn ọrọ̀ oun.

O ni ọla nini ati ọrọ̀ ko mọ nibi dukia ati nnkan ile aye lasan.

Pasitọ Oyakhilome ni oun ko ni i ya akuṣẹ laye oun.

Ki lo fa idi ọrọ yii?

Awọn ti wọn maa n kọ iye owo ti gbajumọ, ọlọla ati awọn olorukọ lawujọ ba ni si oju opo ayelujara lo da ọrọ yii silẹ.

Pasitọ Oyakhilome sọ gbangba pe ki wọn ma fi owo ṣe odiwọn ọla ati ọrọ̀ oun, nitori ọla ti oun ni kọja owo to wa ni banki tabi dukia afowokojọ.

Ṣaaju si ni ọmọ rẹ obinrin kan ti sọ pe baba oun ati Ọlọrun nikan ni ọlọrọ to ga ju lọ.

Lati kin ọrọ ọmọ naa lẹyin, Pasitọ Oyakhilome sọ pe:

"Ọrọ̀ tootọ ko ṣee ṣiro nipa lilo ẹrọ iṣiro tabi iye owo to wa nipamọ ni banki.

"Iwe Efesu ori kẹta ẹsẹ kẹjọ, ṣalaye nipa ai le tán, ai ni ààla, aileṣiro ati ailopin ọrọ̀ Kristi."

Pasitọ Oyakhilome sọ pe iru ọla ti iwe mimọ Bibeli ṣalaye rẹ yii kọja òye ẹda, ko si le tan laye.

Iru rẹ lo ni oun n lo, oun ko si le di akúṣẹ̀ẹ́ laye.

"Mi o ni i ṣe alaini laye mi."

Pasitọ Chris Oyakhilome lo fi igboya sọ eyi, o ni ọla oun ko kan ti bi wọn ṣe n ṣe odiwọn ọlọla laye.

Ta a ni Pasitọ Chris Oyakhilome?

Pasitọ Chris Oyakhilome

Oríṣun àwòrán, Others

Christian Oyakhilome ni wọn bi ni lọjọ keje, oṣu Kejila ọdun 1963, nipinlẹ Edo.

Pasitọ to maa n waasu lori amohunmaworan to si jẹ oludasilẹ ijọ Love World Incorporated tawọn eeyan tun mọ si Christ Embassy ni.

Bakan naa ni Oyakhilome jẹ onkọwe to maa n ṣe iwasuu sinu iwe to si maa n ha pupọ rẹ kiri lọfẹẹ.

O lọ sile ẹkọ Edo College, o si lọ si Bendel State University to pada di Ambrose Alli University, niluu Ekpoma, ipinlẹ Edo.

Nibẹ to ti kẹkọọ nipa ile kikọ.

Chris Oyakhilome fẹ iyawo rẹ; Anita Ebhodaghe, lọjọ keji, oṣu Keji ọdun 1991.

Wọn bi ọmọbinrin meji, Sharon ati Charlene.

Ọdun 2014 ni ede aiyede ṣẹlẹ laaarin awọn mejeeji, wọn si tu igbeyawo naa ka loṣu Keji ọdun 2016.

Ni 2011, Forbes to maa n kede iye owo awon olowo, ṣe odiwọn owo Oyakhilome si aarin $30 million ati $50 million.

Ni 2025, awọn akọsilẹ kan sọ pe owo rẹ wa laaarin $50 million to $60 million