Ìdí rèé táwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa fi lè gba ẹ̀jẹ̀ ará wọn pamọ́ báyìí láti lò fún ìtọ́jú tó bá nílò kí wọ́n gbẹ̀jẹ̀

Oríṣun àwòrán, EPA
Ijọ awọn ẹlẹrii Jehofa ti kede ayipada lori ofin wọn to ti pẹ wi pe awọn ko le gba ẹjẹ sara awọn fun itọju nile iwosan.
Fun ọpọlọpọ ọdun, alaisan to ba jẹ ẹlẹrii Jehofa tawọn dokita ba sọ fun un wi pe o nilo ki wọn fa ẹjẹ si i lara nile iwosan ko ni gba ki wọn ṣe bẹẹ tori o tako igbagbọ wọn.
Ohun ti wọn maa n sọ ni pe Ọlọrun ni pe kawọn sa fun ẹjẹ, tori Ọlọrun ri ẹjọ gẹgẹ nnkan abẹmi, awọn ko si fẹ ṣe aigbọran si Ọlọrun.
Amọ, ninu oṣu Kẹta yii ni awọn alaṣẹ ijọ awọn ẹlẹrii Jehofa tan imọlẹ si igbagbọ ijọ naa lori fifa ẹjẹ sara ẹni to ba n ṣaisan.
Ohun to ti yi pada bayii ni pe awọn ọmọ ijọ ẹlẹrii Jehofa le fa ẹjẹ ara wọn pamọ titi di ọjọ ti wọn le nilo iru ẹjẹ bẹẹ bo ya lasiko ti wọn ba n ṣiṣẹ abẹ tabi ti wọn ba nilo ẹjẹ itọju ara mii.
Sibẹ, ijọ naa ko tii faye gbawọn ọmọ ijọ lati maa gba ẹjẹ ẹlomiran lasiko ti wọn ba n ṣiṣẹ abẹ tabi ti wọn ba nilo ẹjọ nile iwosan.
Odu ni ijọ awọn ẹlẹrii Jehofa nipa ṣiṣe iwaasu ojule de ojule papaa julọ lorilẹede Naijiria.
Ko din ni orilẹede igba kaakiri agbaaye ti ijọ awọn ẹlẹrii Jehofa wa, ẹgbẹlẹgbẹ miliọnu si ni wọn.
Idi ti ijọ ẹlẹrii Jehofa fi ṣe ayipada ofin wọn lori ẹjẹ gbigba fun alaisan

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ofin ijọ awọn ẹlẹrii Jehofa to ti pẹ ni pe, awọn ọmọ ijọ naa ko gbọdọ jẹ ki wọn fa ẹjẹ si wọn lara nile iwosan.
Amọ, ọpọ eeyan lo ti tako ofin yii wi pe ko mu ọpọlọ dani rara tori awọn eeyan maa n nilo ki wọn fẹjẹ siwọn lara papaa julọ lasiko ti wọn ba ṣiṣẹ abẹ.
Fun apẹẹrẹ, iṣẹlẹ kan ṣẹlẹ ni Naijiria ninu eyi ti ọmọ ijọ ẹlẹrii Jehofak kan ti padanu ẹmi rẹ.
Ọpọ ọmọ Naijiria ni wọn koro oju si bi arabinrin kan to n ta ounjẹ, Omolola Mensah, ti ọpọ eeyan mọ si Aunti Esther ṣe kọ lati jẹ ki wọn fa ẹjẹ si i lara nile iwosan nitori o jẹ ọmọ ijọ ẹlẹrii Jehofa.
Iroyin sọ pe Omolola ti kọkọ rawọ ẹbẹ sawọn ẹlẹyinju aanu lori ayelujara wi pe ki wọn ṣeranwọ owo foun lati le tọju aisan jẹjẹrẹ ọyan to ba a finra, awọn eeyan si da ọgbọn miliọnu naira fun un.
Gẹgẹ bi o ti ṣalaye, o nilo lati gba itọju arun jẹjẹrẹ ti wọn n pe ni ''chemotherapy'' eyi to maa mu un gba ẹjẹ.
Ṣugbọn dipo ko gba ẹjẹ, niṣe lo lọ n jẹ ounjẹ ti yoo jẹ ki ẹjẹ pọ lara rẹ, tori ọmọ ijọ ẹlẹrii Jehofa ni.
Lẹyin o rẹyin, obinrin naa pada dagbere faye.
Amọ, ni bayii, awọn alaṣẹ ijọ naa ti sọ pe awọn ọmọ ijọ le ṣeto bi wọn ṣe fẹ fi ẹjẹ ara wọn pamọ di ọjọ ti wọn yoo nilo rẹ.
Ninu ọrọ ti ọkan lara awọn abẹnugan ijọ ẹlẹrii Jehofa sọ ninu fido kan to wa lori ikanni ijọ naa ni ọkunrin naa ti sọ pe Bibeli ko sọ pato nnkankan lori bi eeyan ṣe le ṣe ẹjẹ ara rẹ.


























