Mẹ́ta nínú èèyàn márùn-ún tó so àdó olóró mọ́ra wọ Maiduguri ló yin tiwọn, méji ṣì kù tí à ń wá báyìí- Gomina Zulum

Bi ina ko ba tan laṣọ, ẹjẹ ko le tan lori eekanna.
Eyi ni alaye ti gomina ipinlẹ Borno, Babagana Zulum, ṣe fun BBC ninu ifọrọwerọ to ṣe lẹyin ibugbamu ado oloro to pa awọn eeyan ni Maiduguri laipẹ yii, ti ọpọ si tun farapa.
Ninu ifọrọwerọ ti BBC ṣe pẹlu Gomina Zulum lo ti ni awọn marun-un lo wọ Maiduguri ti wọn so bọmbu mọra, amọ mẹta ninu wọn lo ṣi yin tiwọn ti ijamba fi waye laipẹ yii.
Gomina Zulum sọ pe awọn meji to ṣẹku ṣi n farapamọ sibi kan lati ṣiṣẹ ibi ọwọ wọn.
'A ṣi n ṣewadi ibi ti awọn meji yẹn wa, ọwọ wa si maa tẹ wọn'

Oríṣun àwòrán, Vanguard Newspaper
Gẹgẹ bi Gomina Babagana Zulum to fi aidunnu rẹ han si iṣẹlẹ to pa o kere tan, eeyan mẹtalelogun naa ṣe sọ, o ni iwadii ti bẹrẹ lati mọ ibi ti awọn alado iku meji naa fara ṣoko si.
Zulum sọ pe pẹlu aṣẹ Oluwa, ọwọ yoo ba wọn.
Gomina ipinlẹ Borno naa rọ awọn araalu lati maa wa ni ifura.
O ni oun ko le fi gbogbo ẹnu ṣalaye igbesẹ ti ijọba n gbe lori ọrọ yii, nitori ọrọ aabo to gbẹgẹ ni.
Zulum fi kun un pe gbogbo aṣọ kọ ni a n sa loorun ni igbesẹ ti ijọba n gbe lati ri I pe awọn onibọmbu meji to ṣẹku ko yin in, o ni ko ṣee sọ lori afẹfẹ ki omi ma baa ti ẹyin wọ igbin lẹnu.
"Olobo to ta wa ni pe marun-un ni awọn apaayan-pa-ara rẹ (Suicide bombers) to wọ Maiduguri, mẹta ninu wọn ti lo tiwọn, a si n wadii lati mọ ibi ti awọn meji ti ko ti I lo tiwọn wa.
"Mi o fẹ sọ ju bẹẹ lọ, a wa lori ẹ, pẹlu ogo Oluwa, a maa ba ero awọn meji yẹn jẹ, wọn o ni I le lo ado oloro tiwọn."
Gomina Babagana Zulum lo sọ bẹẹ.
'Ko dẹrun lati koju ọta ti ko foju han'
Nigba to n dahun ibeere BBC, pe asiko aawẹ Ramadan ati asiko ibo ni awọn apaayan yii maa n saba pitu ju, ki lo de ti ijọba rẹ ko le dena iru eyi, Gomina Zulum dahun pe:
O ṣoro pupọ lati koju ọta ti ko foju han.
O ni ni nnkan bii oṣu meji sẹyin ni awọn ologun ṣi ṣiṣẹ nibi ti a mọ si Timbuktu Triangle, ti wọn si n ṣe omin lọwọ nigbo Sambisa bayii.
"Erongba wa ni lati ṣẹgun ikọlu wọnyi ko too di asiko ojo, nitori ti yoo ba fi di oṣu kan si meji bayii, igbo Sambisa ko ni i ṣee wọ mọ."
Zulum sọ pe awon to n pa eeyan naa n wọ Maiduguri lasiko ọdun bii iṣe wọn ki wọn le ri aarin ọpọ eeyan duro si bi wọn ba fẹ pitu ni.
"O ṣoro fun ijọba lati tu ara gbogbo eeyan to n gbe ni Maiduguri wo, ṣugbọn mo fẹ fi da yin loju pe a ti bẹrẹ awọn igbesẹ kan."
Bẹẹ ni Gomina Babagana Zulum wi
Ki lo ṣẹlẹ ṣaaju?
Ọjọ Aje, ọjọ kẹrindinlogun oṣu Kẹta ọdun 2026 yii ni aimọye àdó ikú bù nilu Maiduguri, tí í ṣe olú ìlú ìpínlẹ̀ Borno, tó sì gbemi ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn.
A gbọ pe o kere tan, eeyan mẹtalelogun lo ku, tib ii ọgọrun-un si farapa.
Iwájú ilé ìwòsàn ẹ̀kọ́ṣẹ́ isegun fásitì Maiduguri áti lawọn ọjà ńlá méji tí wọ́n ń pè ní ọjà Post Office àti ọjà ọjọ́ Mọnde ni ibugbamu naa ti waye.
Gẹ́gẹ́ bí olórí àjọ to n ṣètò ìdẹ̀rùn pajawiri nílẹ̀ wa, NEMA, Sirajo Abdullahi, se wi, ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn lo forí sọta Ìṣẹ̀lẹ̀ náà, tí wọn sì ń gbà itoju lọ́wọ́ nile iwosan àmọ́ ó ní òun kò le sọ iye wọn ní pàtó.
Akọtun ìṣẹ̀lẹ̀ ìbúgbàmù àdó olóró yìí ló wáyé lásìkò yìí ti eto aabo mẹhẹ yíká Nàìjíríà, nítorí ìkọlu àwọn agbébọn to n sọsẹ lápá àríwá ílẹ̀ wá.
Gomina Ìpínlẹ̀ Borno, Babagana Zulum, bu ẹnu atẹ lu ìṣẹ̀lẹ̀ ibugbamu náà, pẹ̀lú àfikún pe ọwọ́ àwọn ológun to n dun àwọn agbésùnmọ̀mí nínú igbó Sambisa tí wọn wá, lo mú kí wọn máa jẹ aporo yìí.
"Ero ati àdúrà mi wa lara awon eniyan tó forí sọta ìṣẹ̀lẹ̀ yìí, èyí tó burú jáì, tó sì jẹ ìwà ìkà ponbele."
Bakan naa, agbẹnusọ fún iléeṣẹ́ Ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Borno, Nahum Daso Kenneth, ní àwọn agbófinró àtàwọn adoola ẹ̀mí tí ṣiṣẹ níbi iṣẹlẹ ọ̀hún.


























