Mọ̀ nípa àwọn ewu méje tó rọ̀ mọ́ ṣíṣe ìdí ńlá, BBL, àti ìlànà tí wọ́n ń gbà ṣe é

Àkọlé fídíò, Iṣẹ abẹ BBL
Mọ̀ nípa àwọn ewu méje tó rọ̀ mọ́ ṣíṣe ìdí ńlá, BBL, àti ìlànà tí wọ́n ń gbà ṣe é

N jẹ o mọ pe sise isẹ abẹ idi nla ti oloyinbo n pe ni Brazillian Butt Lift (BBL) wa lara awọn isẹ abẹ oge, Cosmetic surgery, to lewu julọ lagbaaye?

BBL lewu de bi pe, o kere tan eeyan kan ninu ẹgbẹrun mẹta to ba se isẹ abẹ yii lo se e se ko padanu ẹmi wọn lasiko isẹ abẹ naa.

Ti awọn dokita ba se isẹ abẹ yii, wọn yoo mu ọra lara awọn ẹya ara miiran bi itan tabi ikun.

Wọn yoo wa lẹ awọn ọra ti wọn ge wonyii pẹlu ilana kan ti wọn n pe ni Liposuction tabi Induction, lati le jẹ ki idi ẹni ti wọn sisẹ abẹ naa fun tobi.

Dokita kan n se ayẹwo idi to se fun obinrin kan wo

Sugbọn ṣa, awọn ewu wa to rọ mọ isẹ abẹ yii pọ diẹ, to si maa n mu ẹmi lọ lọpọ igba.

Awọn ewu naa ni iwọnyii:

  • Ọra ti wọn gbe lati inu ikun si ibi idi yii le ko sinu ẹjẹ ẹni ti wọn sisẹ abẹ yii fun, ti wọn n pe ni fat embolism.
  • Ọra yii si tun le lọ sinu awọn ẹya ara bii ẹdọ fooro, ọpọlọ ati bẹẹ bẹẹ lọ eyi to le fa aisan rọparọsẹ.
  • Bakan naa, ole se okunfa ki oju ẹni to se isẹ abẹ naa fọ.
  • O tun lee mu ki onitọun ma le sọrọ.
  • Lakotan, isẹ abẹ idi nla yii tun le tete fa iku ojiji fun ẹni to ba se e tori awọn ewu to rọ mọ.
  • Awọn ewu mii to tun rọ mọ isẹ abẹ idi nla ni ki kokoro aifojuri, ti oloyinbo n pe ni infection, wọ oju isẹ abẹ yii.
  • Nigba miran, idi ti wọn ko ọra si yii ma duro daadaa, o le wọ́, ti idi kan yoo si ju ikeji lọ.

Lootọ ọpọ obinrin lo n ṣe iṣẹ abẹ yii kaakiri agbaye, sugbọn ko i tii si pato iye onka obinrin to n ṣe lorilẹede Naijiria lodọọdun.

To o ba wa fẹ se isẹ abẹ idi nla, ri i daju pe o lọ sọdọ awọn akọṣẹmọṣẹ dokita to mọ nipa isẹ abẹ yii daadaa.

Yoo si dara ki o lọ si ileewosan ti ijọba fi ontẹ lu, ki o si ni imọ to to lori awọn ewu to rọ mọ isẹ abẹ yii.