Kí ni àbẹ̀wò ààrẹ Tinubu sí UK túmọ̀ sí?

Àkọlé fídíò, Kí ni àbẹ̀wò ààrẹ Tinubu sí UK túmọ̀ sí?
    • Author, Makuochi Okafor
    • Role, West Africa reporter
    • Reporting from, Lagos, Nigeria
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

O ti fẹ to ogoji ọdun bayii ti olori orilẹede Naijiria ti ṣe abẹwo si ọdọ ọba ilẹ Gẹẹsi.

Ọba Charles III ati Queen Camilla si ti n gbaradi bayii lati gbalejo Aarẹ Bola Ahmed Tinubu ati iyawo rẹ, Oluremi, ni aafin Windsor Castle ni ọjọ Isẹgun.

Aabo to peye ni wọn ti ṣeto kaakiti ni ayika aafin Windsor ṣaaju ohun ti ọpọlọpọ wo bi "iṣẹlẹ itan" eyiti o ṣe afihan ibasepọ ọlọjọ pipẹ laarin awọn orilẹ-ede mejeeji.

Ilẹ Gẹẹsi ṣe akoso Naijiria lasiko ijọba amunisin ati pe ọpọlọpọ awọn ile-iṣẹ igbalode ti orilẹ-ede naa si n ṣe afihan ipa ilẹ Gẹẹsi.

Ijọba Gẹẹsi ṣe eto ofin Naijiria ati awọn apakan ti iṣẹ ilu rẹ.

Aworan aarẹ Bola Tinubu to wọ agbada dudu, to si na ọwọ kan soke

Ki lo ti waye saaju ati ohun ti yoo sẹlẹ lori abẹwo naa?

Abẹwo orilẹ-ede Naijiria to kẹyin si UK waye ni ọdun 1989, nigbati aarẹ ologun, Ọgagun Ibrahim Babangida rin irin-ajo lati pade Ọbabinrin Elizabeth II fun irin-ajo ọlọjọ mẹrin.

Ọgagun Ibrahim Babangida ni wọn gboriyin fun nile loke nígba to de si ilu Gẹẹsi pẹlu agbada alawọ buluu, aṣọ kan to ní aṣa ibilẹ Naijiria. Iyawo re, Maryam Babangida, wo aso ibile Naijiria ti alawọ ewe ati ewu. Opolopo awon omo Naijiria ni won tun n wo iyawo Babangida, Maryam, gege bi iyaafin Aare to gbajugbaja julo lorile-ede naa.

Nigba to n sọrọ nipa abẹ yẹn, opitan ọmọ orílẹ-ede Naìjíria, Dokita Oludamọla Adebowale sọ fun BBC pe orílẹ-edè Naijíríà ṣi jẹ́ "orílẹ-edè ti ko ti pẹ lasiko naa, ọrọ oṣelu si yatọ sí eyí to wa lọwọlọwọ.

O sọ lasiko naa, Naijiria n ṣiṣẹ lati fi idi "ofin" rẹ mulẹ gẹgẹbi orilẹ-ede olominira. Loni o jẹ ọkan gboogi orilẹede jakejado Afirika.

"Ibaraẹnisọrọ loni jẹ nipa ẹtọ ati diẹ nipa ajọṣepọ, ifowosowopo ni iṣowo, idokowo, aabo, idagbasoke awujọ ati aje laarin awọn orilẹ-ede mejeeji," o sọ.

Sunday Dare, oludamọran fun Aare Tinubu, sọ fun BBC pe awọn anfani ti o pọju wa fun Naijiria nipasẹ "idoko-owo ti o pọ sii, gbigbe imọ-ẹrọ, ṣiṣẹda iṣẹ, ati ifowosowopo owo ti o jinlẹ ti o le ṣe atilẹyin fun idagbasoke aje".

Naijiria n koju ayipada eto ọrọ aje lọwọ yii. Ijọba ti yọ owo iranwọ epo, ṣe ifilọlẹ owo ori tuntun ati bẹbẹ lọ.

Ṣugbọn awọn eto imulo wọnyii ti fa ọpọ inira fun ọpọlọpọ awọn orilẹ-ede Naijiria. Lakoko ti afikun ti bẹrẹ, ni kudiẹ kudiẹ ti de bae to aabo, ti iwa-ipa ati ailewu si ti dawọ iṣẹ-ogbin ni ọpọlọpọ awọn agbegbe ti orilẹ-ede naa.

Aare Tinubu n dojukọ ọpọ ipe lati oke okun pe ko wa atunṣe si eto aabo to mẹhẹ.

Ọba Charles III n bowọ pẹlu Aarẹ Tinubu

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Aarẹ Tinubu ti pada Ọba Charlse tẹlẹ
Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Lati ọdun 2025, Aarẹ orílẹ-ede Amẹríka, Donald Trump ti pariwo sita lori iṣekupani awọn Kistẹni to wọpọ lorilẹede Naijiria, ti ikọlu naa si n waye lati ọdọ awọn alatakiti ẹsin.Ijọba orílẹede Naijiria tako eyi, wọ́n sì tẹnu mọ ọn pe ìwa n koju gbogbo eeyan ni, ki n ṣe eṣin Kristẹni nikan.

Ni Ilu UK, awọn ọmọ ile-igbimọ aṣofin tun ti gbe awọn akiyesi dide pẹlu Akọwe Ajeji nipa ikọlu si awọn Kristiani ni Naijiria. Ni ibẹrẹ ọdun yii, Aṣoju pataki UK lori Ominira ti Ẹsin tabi Igbagbọ dari ariyanjiyan itusilẹ ni ile igbimọ aṣofin lori ọran naa.

Awọn italaya wọnyi ti ṣafikun si bi awọn araalu ko ṣe ni igbagbọ ninu iṣejọba Tinubu bo ti lẹ jẹ pe ẹgbẹ oẹlu rẹ lo ni agbara julọ ni Naijiria.

Idibo Afrobarometer 2025 fihan pe ọpọlọpọ awọn ọdọ gbagbọ pe orilẹ-ede wọn nlọ "ni ọna ti ko tọ."

A nireti orilẹ-ede naa lati ṣe eto idibo ni ọdun 2027, tẹsiwaju ninu ijọba tiwantiwa ti ko ni idiwọ lati ọdun 1999.

Fun Aarẹ Tinubu, o ṣee ṣe ibẹwo naa nilo iṣe iwọntunwọnsi - fifi ilọsiwaju han ni ile, imudara ibatan UK ati Nigeria, ati idahun si awọn ibeere awọn alajọṣepọ kariaye gbe dide.

Labẹ itọsọna rẹ, Naijiria ti wa lati daabobo iṣakoso ijọba tiwantiwa ni Sahel, agbegbe kan ti o ti rii ọpọlọpọ awọniditẹgbajọba ologun ni Niger, Mali ati Burkina Faso.

"Nigeria n tẹsiwaju lati ṣe ipa imuduro ni Iwọ-oorun Afirika, paapaa nipasẹ ifaramọ ti ijọba ilu ati atilẹyin fun awọn iyipada ijọba tiwantiwa ni agbegbe," Oludamoran Sunday Dare sọ.

Aworan awọn ọmọ Naijiria pẹlu Ọba Charles

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Mimu ajọsepọ dan mọran si

Ibẹwo yii waye lẹyin ti ijọba UK ṣe afihan "ọna tuntun si Afirika" ni Oṣu Kejila ọdun 2025. Eto imulo yii ni wọn ṣeto ilana lati mu ajọṣepọ pẹlu awọn orilẹ-ede Afirika fun "anfani igba pipẹ laarin ara wọn."

Minisita ti UK fun Afirika, Baroness Chapman, sọ pe ọna naa ṣe afihan iyipada, ajọṣepọ ti ọwọ ati imudogba."

Fun Ilẹ Gẹẹsi, ibẹwo yii le wa fun awọn ibatan iṣowo, anfani idoko-owo ati jinlẹ ifaramọ ilana pẹlu ijọba tiwantiwa ti o tobi julọ ni Afirika ati ọkan ninu awọn ọja ti o tobi julọ.

Loni, orilẹ-ede Naijiria ati awọn eeyan ni ajọsepọ, ti wọn si n ṣe atilẹyin aṣa to lagbara to wa laarin Nigeria ati UK.

Ọpọ awọn ọmọ Nàìjíríà ni wọn n gbe, ti wọn si n ṣiṣẹ, kawe ni UK. O le ni eniyan 270,000 ṣe akosilẹ Naijiria gẹgẹbi orilẹ-ede ibi wọn ni ọdun 2021 lasiko onka ni n England ati Wales. Naijiria tun jẹ ọmọ orílẹ-ede agbaye Commonwealth, to sì ti fẹ gbalejo 2030 Games Commonwealth.

Ṣaaju abẹwo Aarẹ Tinubu, Ọba Charles ṣe ayẹyẹ ni Aafin St James ni Ọjọbọ lati ṣayẹyẹ awọn orilẹ-ede Naijiria ati awọn iranlọwọ wọn ni awọn agbegbe bii iṣẹ ọna, aṣa, imọ-ẹrọ ati inawo.

Ọba ti sọ tẹlẹ nipa ajọsepọ pẹlu Nigeria. Gẹgẹbi Ọmọ-alade Wales, o ṣabẹwo si orilẹ-ede naa ni igba mẹrin, o si ti sọ pe oun gbadun orin Naijiria ati sisọ Pidgin Naijiria diẹ.