Àwọn agbébọn kọlu ìjọ ECWA ní Kwara, wọ́n jí èèyàn mẹ́jọ gbé.

Aworan ile iwosan

Oríṣun àwòrán, Ileeṣẹ ọlọpaa Kwara

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Awọn agbesunmọmi yawọ ilu Omugo ni ijọba ibilẹ Ifẹlodun ipinlẹ Kwara wọn si ji eeyan mẹjọ gbe lọ ni ile ijọsin kan.

Iṣẹlẹ naa waye lanaa ọjọ Aiku ọjọ kejilelogun Oṣu kẹta ọdun 2026 ni ile ijọsin ECWA to wa ni ilu naa ni nnkan bi ago mẹwa owurọ.

Gẹgẹ bi oṣojumikoro, Ọgbẹni Afọlayan Bayọ ṣe ṣalaye, ile ijọsin ECWA ilu naa lawọn ti n gbọ ti ibọn ro lakọ lakọ.

O salaye pe oun o ti de ile ijọsin lasiko ti iṣẹlẹ naa fi ṣẹlẹ tori oun n wa omi ti oun yoo fi wẹ.

O tẹsiwaju pe, eeyan mẹjọ ni wọn ji gbe ṣugbọn wọn fi awọn mẹta kalẹ ninu wọn.

Ẹni akọkọ ni iya agba lagba ti kole rin dada ati ọmọ kekere kan ti ariwo rẹ pọ nigba to n sunkun, ti obirin kan bọ lọwọ wọn loju ọna.

Pẹlu alaye pe, awọn marun lo ku lọdọ awọn agbesunmọmi naa bayii ti wọn ji gbe.

Ninu ọrọ rẹ, Kọmisọna feto irọyin ati ibanisọrọ ni ipinlẹ Kwara, Arabinrin Bọla Olukoju sọ pe, awọn marun ni wọn ji gbe.

Atẹjade ti kọmisọna naa fi sita lorukọ ijọba ipinlẹ Kwara kansara sawọn ọlọdẹ, ikọ vigilante, ẹṣọ aṣọgbo ati awọn eleto aabo to ku fun ifarajin wọn.

Ijọba ipinlẹ Kwara kesi awọn eleto aabo naa lati doola gbogbo awọn ti wọn ji gbe naa pada lai farapa.

Ijọba ipinlẹ Kwara bu ẹnu atẹ lu iru akọlu bẹẹ sawọn olujọsin ti wọn lọ sin Ẹleda wọn.

Pẹlu arọwa si awọn eleto aabo lati jọ ṣiṣẹ papọ gbogun ti awọn agbesunmọmi naa.

Ijọba ipinlẹ Kwara ni oun farajin lati dabobo ara ilu.

Ki ni ohun to ti ṣẹlẹ tẹlẹ?

Ilu Omugo lẹkun Oroagọ ni ijọba ibilẹ Ifẹlodun ipinlẹ Kwara foju wina akọlu awọn agbebọnja.

Laipẹ yii ni wọn ṣi sekupa ọkunrin kan ti wọn pe ni Ajise Ayọ ti wọn si ji iyawo rẹ ati awọn ọmọ rẹ gbe.

Bakan naa, wọn tun ji eeyan mẹrin gbe ninu oko kasu ti wọn ti lọ ṣiṣẹ.

Ijọba ibilẹ Ifẹlodun ni ipinlẹ Kwara jẹ ọkan lara awọn ijọba ibilẹ to n koju akọlu awọn agbesunmọmi.

Inufu aya fu lawọn eeyan agbegbe naa wa latari ibẹru akọlu awọn agbebọnja naa.

Igbesẹ wo ni ijọba gbe?

Losu kini ọdun yii ni ijọba ipinlẹ Kwara pẹlu ifọwọsowọpọ ijọba apapọ ko awọn ọmọ Ogun lọ agbegbe Oroagọ.

Awọn ọmọ Ogun naa ṣiṣẹ lagbegbe naa fun nnkan bi ọsẹ meji ti wọn si ko gbogbo Fulani ti wọn n ṣiṣẹ lagbegbe naa kuro.

Bẹẹni wọn ju ọpọ Ado oloro si ibuba awọn agbesunmọmi naa.

Awọn Fulani pọ lagbegbe naa ti wọn n ṣiṣẹ agbẹ tawọn mi si n daran jẹ.

Ki ni ọlọpaa ipinlẹ Kwara sọ?

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kwara fidi iṣẹlẹ ikọlu si ile ijọsin ECWA Omugo ijọba ibilẹ Ifẹlodun ipinlẹ Kwara mulẹ.

Atẹjade Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kwara Ejirẹ Adeyemi Toun sọ pe ikan bi ago mẹwa owurọ Ana ni iṣẹlẹ naa sẹlẹ.

Ofikun pe wọn ti dola awọn mẹta ninu awọn mẹjọ ti wọn jigbe.