Israel ní Motjaba ọmọ Ali Khameni tó di olórí tuntun fún Iran, 'ti di ẹni tí àwọn ń fi ikú wá kiri'

Aworan Motjaba Ali Khamenei, olori tuntun fun orilẹede Iran.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

    • Author, BBC News Persian
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Wọn ti kede Motjaba Khamenei, ọmọ Ayatollah Ali Khamenei to ku ninu ikọlu Amẹrika ati Israel si Iran, gẹgẹbi olori tuntun fun orilẹede naa.

Nibayii gẹgẹbi olori tuntun ti wọn ṣẹṣẹ yan fun Iran, ọpọ lo n reti pe Motjaba yoo tẹsiwaju pẹlu igbesẹ ilana lile ti baba rẹ gbe nigba aye rẹ.

Ọpọ dẹ tun gbagbọ pe, gẹgẹbi ẹni to padanu baba, iya ati iyawo rẹ ninu ikọlu Amẹrika ati Israel, ko daju pe yoo fi oju rere wo wọn tabi tẹ fun wọn rara.

Bakan naa ni yoo tun koju ipenija iwalaaye orilẹede Iran ati titukọ orilẹede naa atawọn eeyan rẹ jade kuro ninu wahala ati ọgbun eto oselu ati eto ọrọ aje.

Ohun to gbilẹ ju ninu ipenija rẹ ni pe oun naa ti di ẹni ti wọn n fi iku wa kiri bayii. Lọsẹ to kọja ni minisita fun eto abo lorilẹede Israel kede pe ẹnikẹni ti wọn ba yan gẹgẹbi adari nipo Ali Khameni "ti di ẹni ti wọn yoo maa fi iku wa kiri".

Ṣaaju asiko yii Motjaba ko di ipo ijọba kankan mu, bẹẹni kii ṣe ifọrọwanilẹnuwo pẹlu ileeṣẹ iroyin kankan , kii sii sọrọ ni gbangba. Iwọnba perete lawọn fidio tabi fọto rẹ to wa nigboro.

Ṣaaju eyi, awọn iroyin kan n lọ kiri pe o jẹ ọkan lara awọn alagbara to n fa gburu labẹnu lorilẹede Iran.

Taa ni Mojtaba Khamenei, ọmọ Ayatollah Ali Khamenei tó ṣeéṣe kó di adarí Iran tuntun?

Mojtaba Khamenei ree lasiko eto ilu kan

Oríṣun àwòrán, Tasnim News Agency

Lẹyin ti ogun ti Amẹrika ati Isreal gbẹmi Aarẹ Iran, Ali Khamenei, ọpọ lo n bere boya ọmọ rẹ Mojtaba naa ti jade laye.

Ko si iroyin kankan nikan nipa rẹ fun ọjọ diẹ amọ nigba to di ọjọ kẹta, oṣu Kẹta, ọdun 2026, ileeṣẹ iroyin Iran kan jabọ pe Mojtaba wa laye, o si wa laaye.

Amọ ko ti foju han ni gbangba lati akoko naa.

Mojtaba ni ọpọ n wo loju bayii pe oun ni ipo naa yoo kan lẹyin iku baba rẹ gẹgẹ bii ileeṣẹ iroyin Reuters ṣe jabọ, amọ o ṣoro lati fidi iroyin naa mulẹ.

Ẹwẹ, awọn agbagba to n yan adari ni Iran, Assembly of Experts, ti n mura lati kede adari tuntun.

A gbọ pe o ṣeeṣe ki wọn ma kede adari tuntun naa titi ti wọn yoo fi sin oku Ali Khamenei.

Mojtaba ko dabi bii baba rẹ nitori igbeaye irẹlẹ to n gbe, bẹẹ ni ko tii dije du ipo oṣelu kankan ri.

Bakan naa ni ọkunrin ọhun ko tii ṣe ifọrọwerọ pẹlu akọroyin ri, koda kii sọrọ ni gbangba.

Aworan tabi fidio diẹ ni awọn eeyan n ri nipa rẹ.

Wayi o, awọn iwadii kan ti sọ pe o wa lara awọn alagbara to wa lẹyin baba rẹ to si ni ipa ti ko kere lara awọn igbesẹ ti oloogbe ti gbe sẹyin.

Ọkunrin ọmọ Iran kan gbe aworan Mojtaba Khamenei,dani ninu oṣu Keji, ọdun 2026 yii

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, O ti le lọdun ti awọn ti n sọ pe Mojtaba Khamenei ni yuoo goti itẹ lẹyin baba rẹ

Wayi o, o ṣeeṣe ki wahala wa lori ikede Mojtaba Khamenei gẹgẹ bii ẹni ti ipo adari naa kan.

Lọdun 1970 ti awọn Musulumi gbajọba Iran, ohun ti wọn ni awọn yoo maa fi yan adari sipo ni ipo ri wọn dimu ninu ẹsin ati iriri ipo adari ti wọn ti di mu ṣaaju, kii ṣe nipa jijogun ipo naa bii awọn lọbalọba ṣe n gori itẹ.

Khamenei funra rẹ ti sọ ṣaaju pe oun ko fọwọ si ki ọmọ oun naa di adari gẹgẹ bii ọkan lara aṣaaju ilẹ naa ṣe sọ lọdun meji sẹyin.

Taa gan ni Mojtaba Khamenei?

Wọn bi Mojtaba Khamenei lọjọ kẹjọ, oṣu Kẹsan an, ọdun 1969 niluu Mashhad si ipo keji ọmọ mẹfa ti baba rẹ bi.

O lọ sile ẹkọ girama ti ẹsin Musulumi Alavi niluu Tehran.

Nigba to wa lọmọ ọdun mẹtadinlogun, o lọ si Qom to jẹ ilu mimọ lati tẹsiwaju ẹko imọ Islam siwaju.

O jẹ alfaa ti ko fi bẹẹ lẹnu nibẹ daadaa, eyii to le ṣakoba fun lati de ipo adari Iran.

Mojtaba Khamenei lasiko to ṣabẹwo si ọfọfisi Hezbollah lọdun 2024.

Oríṣun àwòrán, West Asia News Agency Via Reuters

Lẹnu lọlọ yii, awọn kan ti n oe to Mojtaba Khamenei ni "Ayatollah" to jẹ ipo adari ẹsin to ga.

Ẹsun dida si ọrọ oṣelu

Ifẹhonuhan Green Movement to waye lẹyin eto idibo ọdun 2009

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ifẹhonuhan Green Movement waye lẹyin eto idibo ọdun 2009

Asiko eto idibo Aarẹ ọdun 2005 ni orukọ Mojtaba kọkọ gba igboro kan, eyii ti Mahmoud Ahmadinejad bori rẹ.

Ninu lẹta kan si Khamenei, ajijagbara Mehdi Karroubi fẹsun ka Mojtaba pe o n da si eto idibo naa ti ko yẹ ko ri bẹẹ.

Ọdun mẹrin lẹyin naa ni wọn tun fẹsun kan naa kan Mojtaba.

Iyansipo Ahmadinejad lẹẹkeji fa ifẹhonuhan nla kan kaakiri orilẹede naa ti wọn pe ni Green Movement.

Lara awọn olufẹhonunhan naa n kọ orin pe awọn ko fẹ ki Mijtaba gori alefa lẹyin baba rẹ.