Makinde kéde ₦10,000 owó ìrànwọ́ fáwọn òṣìṣẹ́ ìpínlẹ̀ Oyo torí ọ̀wọ́ngógó epo bẹntiróòlù

Gomina Seyi Makinde ipinlẹ Oyo wọ aṣọ buba buluu pẹlu fila

Oríṣun àwòrán, Seyi Makinde/X

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Gomina Seyi Makinde ipinlẹ Oyo ti kede owo iranwọ ẹgbẹrun un mẹwaa (N10,000) fawọn oṣiṣẹ ipinlẹ naa latari ọwọngogo epo bẹntiroolu to gbode lorirẹede Naijiria.

Makinde ṣalaye pe awọn oṣiṣẹ yoo ri owo yii gba fun oṣu mẹta na lati maa fi wọ ọkọ lọ sibi iṣẹ wọn.

Makinde sọ pe ''inu mi dun lati kede wi pe gbogbo osiṣẹ ijọba nipinlẹ Oyo to fi mawọn oṣiṣẹ ijọba ibilẹ yoo maa gba N10,000 gẹgẹ bi owo iranwọ fun ọkọ wiwọ lọ sibi iṣẹ lati oṣu Kẹrin to n bọ.

Gbogbo oṣiṣẹ ni owo yii wa fun, iye kan naa si ni gbogbo oṣiṣẹ yoo maa gba.

Awọn ti ko ba ijọba ṣiṣẹ naa yoo janfaani owo yii tawọn oṣiṣẹ ijọba ba ti n ri i gba.''

Ọpọ ile epo nipinlẹ Eko ati kaakiri ilẹ Yoruba lo ti n ta jala epo bẹntiroolu kan ni N1,320 si N1,330 bayii.

Ẹwẹ, alaga ẹgbẹ oṣiṣẹ NLC ẹka ti ipinlẹ, Kọmureedi Kayode Martins, naa ti fidi rẹ mulẹ wi pe gomina ti buwọlu ẹbẹ awọn oṣiṣẹ lati maa ṣeranwọ fun wọn pẹlu owo ọkọ lọ sibi iṣẹ.

Ọgbẹni Martins sọ pe laaarọ ọjọ Aje naa ni ẹgbẹ oṣiṣẹ rawọ ẹbẹ si Makinde fun iranwọ pẹlu owo ọkọ, ki gomina to kede igbesẹ rẹ lori ọrọ naa.

Alaga ẹgbẹ oṣiṣẹ NLC ẹka ti ipinlẹ Oyo sọ pe ''lati oṣu Kẹrin to n bọ ni awọn oṣiṣẹ yoo bẹrẹ si ni janfaani owo iranwọ epo naa.

Awọn ẹka ijọba tọrọ kan yoo maa ṣalaye bawọn oṣisẹ yoo ṣe maa ri owo naa gba laipẹ.''