Kò tí ì sí obìnrin kankan tó jáde síta pé wọ́n fipá bá òun lòpọ̀ lásìkò ọ̀dun Ozoro - Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá

Asia nipa ikọlu si awọn obinrin

Oríṣun àwòrán, CRIS BOURONCLE/AFP via Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Delta ni ọwọ ti tẹ eeyan mẹdogun lori ẹsun ifipabanilopọ lasiko ọdun Ozozo nipinlẹ Delta.

Ọpọ fidio lo ti kun ori ayelujara, eyi to ṣafihan bi awọn ọdọ ọkunrin ṣe n kọlu awọn obinrin ti wọn da wa.

Fidio ṣafihan bi awọn ọkunrin ṣe n le awọn obinrin kiri, ti wọn si n ja wọn si ihoho ni ita gbangba, ti wọn si n ka fidio naa sori foonu wọn.

Awọn fidio yii fa ọpọ ibinu lori ayelujara, ti ọpọ eeyan si n pe fun idajọ lori iṣẹlẹ naa.

Ẹwẹ, ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Delta, jẹ ko di mimọ pe titi di asiko yii , wọn ko ti ri pe ki ẹnikẹni jade sita pe wọn fipa bao un lopọ lasiko odun naa.

Bright Edafe, agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa Delta lo sọ nigba to n ba ileeṣẹ iroyin abẹle sọrọ lọjọ Aje pe awọn tib a obinrin mẹrin sọrọ ti wọn si jẹ ko di mimọ pe ẹnikẹni ko fipa ba awọn lopọ.

Ileeṣẹ ọlọpaa ni ọpọ fidio to jade lati bi ọdun naa jẹ ohun to dojutini pupọ, ti wọn si ọwọ ti tẹ awọn eeyan ti fidio ṣafihan wọn.

Ileeṣẹ ọlọpaa ni iwadii si n lọ lori iṣẹlẹ naa .

Kọmisana fun ileeṣẹ Delta

Oríṣun àwòrán, Bright Edafe

Iyawo Aarẹ bu ẹnu atẹlu iṣẹlẹ to waye Ozozo

Iyawo aarẹ orilẹede Naijiria, Oluremi Tinubu, ẹni to wa lati apa ibi kan nipinlẹ Delta ti darapọ mọ awọn ọmọ orilẹede Naijiria lati bu ẹnu atẹlu iṣẹlẹ to waye to kọlu ọpọ obinrin lasiko ọdun Ozozo, to si rọ awọn ẹsọ alabo lati ri daju pe fi oju awọn eeyan to lọwọ ninu iṣẹlẹ jo ofin.

Eyi jẹyọ ninu atẹjade ti iyawo aarẹ buwọlu fun awọn akọroyin nibi to ni aṣa kankan ko tọka si pe ka ma fi iya jẹ obinrin tabi tako ominira wọn.

Bakan naa lo kan sara si ileeṣẹ ọlọpaa fun iṣẹ takuntakun ati bi wọn ti ṣe mu eeyan mẹfa to lọwọ ninu iṣẹlẹ naa.

O wa rọ awọn obinrin ti lugbadi iṣẹlẹ pe ki wọn ra iranlọwọ lori ẹka ati ọpọlọ wọn.

Ọdun Ozozo ko wa fun ikọlu si awọn obinrin- Oba Ozozo

HRM Anthony Uvietobore Ogbogbo (JP), Ibuka 1

Oríṣun àwòrán, Bright Edafe

Ọba Ozozo, Anthony Uvietobore Ogbogbo, Ibuka kini, ti wọgile ero to n kiri pe ọdun Ozozo n ṣe igbelarugẹ fun ikọlu si obinrin.

O ṣapejuwe ọdun naa gẹgẹ bii eyi to wa fun bii obinrin ṣe pe lara si, ti ọpọ si ti da nnkan mii pọ mọ ọdun naa, ti ọpọ ọdun si ti si ọna nipa ọdun naa.

Awọn alaṣẹ ibilẹ ni ilu naa tẹnumọ pe ko si nnkan to jẹ ifipabanilopọ waye lasiko ọdun naa, ati ikọlu to waye jẹ iwa ọdaran, ti ki n ṣe ti aṣa.