Ọ̀dọ́kùnrin ẹni ọdún 21 fipá bá obìnrin lopọ̀, fún un lọ́rùn pa l'Ondo

Aworan afurasi ti ọwọ tẹ ni Ondo

Oríṣun àwòrán, Ileeṣẹ ọlọpaa Ondo

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Inu ibanujẹ ati iporuru ọkan ni awọn olugbe ilu Iboropa Akoko wa bayii bi ọdọmọkunrin, ẹni ọdun mọkanlelogun ṣe fi ipa ba agbalagba kan, Olaseni Veronica ni ajọsepọ, to si yin lọrun pa lẹyin ibalopo naa.

Awọn olugbe ilu naa ko mọ ọjọ ori oloogbe naa, sugbọn wọn salaye pe obinrin agbalagba ni obinrin ti Alabi Anthony fi ipa ba lopọ.

Ọkan lara olugbe ilu naa ti ko fẹ ki orukọ rẹ di mimọ salaye pe wọn fi panpẹ ọba mu Anthony lẹyin ti wọn ri oku arabinrin naa, ti iwadi awọn ọlọpaa si tọka iṣẹlẹ yi si ọmọ ọdun mọkanlelogun naa.

O salaye pe awọn Ọlọpaa gbe Anthony lọ oriko ti iṣẹlẹ naa ti waye lati bere awọn ibere bi iṣẹlẹ naa se sẹlẹ.

Ṣugbọn awọn araalu naa ti wọn koro oju si iwa laabi tì ọmọ naa hu, gbiyanju lati sekọlu si, tí awọn ọlọpaa si gbe sa kuro laarin awọn ero ki ofin le se idajọ ti o tọ lori ọrọ naa.

Kí ni ileeṣẹ Ọlọpaa sọ lórí ọ̀rọ̀ náà?

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa Ipinlẹ Ondo, Jimoh Abayomi fi idi iṣẹlẹ naa mulẹ, to si salaye pe wọn ti fi panpẹ ọba mu Alabi Anthony lori iṣẹlẹ to gbẹmi Olaseni Veronica n'ilu Iboropa Akoko

Abayomi sọ pe isẹ ọtęlẹmuyẹ ti ileeṣẹ Ọlọpaa ṣe lo mu ki wọn bẹrẹ iwadi, eyi to mu ki wọn bẹrẹ si ni tọ pinpin ẹrọ ilewọ oloogbe tó ti di awati, ati fi fi panpẹ ọba mu afunrasi naa.

Agbẹnusọ naa sọ pe afunrasi, Anthony ti jẹwọ asemase rẹ, tó si fi idi rẹ mulẹ pe ohun fi ipa ba obinrin naa lo, ti o si yi ọrun obinrin naa lẹyin asemase to waye lọwọ rẹ.

Abayomi sọ pe ileeṣẹ ọlọpaa Ipinlẹ Ondo koro oju si irufẹ iwa ọdaran yi, to sọ fi dá awọn araalu loju pe wọn yoo se ẹjọ naa ni ibamu pẹlu ofin.

O salaye pe ẹjọ náà tí wá ní olu ileeṣẹ Ọlọpaa Ipinlẹ Ondo lati le tubọ ṣe iwadii lẹkunrẹrẹ ati lati fi afunrasi naa jofin.

Kọmisọna Ọlọpaa nipinlẹ Ondo Adebowale Lawal rọ awọn ara ilu lati maa fi iṣẹlẹ ohun tó n waye ni ayika wọn to awọn agbofinro ni akoko lati le se ohun to yẹ.