"Bí gbogbo àgbáyé bá nílò epo rọ̀bì, Nàíjíríà wà níbẹ̀ láti pèsè rẹ̀ fún wọn"

Mínísítà feto iroyin nilẹ Naijiria, Mohammed Idris Malagi wọ asọ buba ati sokoto alawọ eeru, o si de fila awọ kan naa.
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Mínísítà feto iroyin nilẹ Naijiria, Mohammed Idris Malagi ti kede fun gbogbo agabaye pe orilẹede Naijiria wa nibẹ digbi fun wọn, ti wọn ba nilo epo rọbi.

Malagi fọwọ gbaya bẹẹ nilu London nigba to n ba ikọ iroyin BBC sọrọ lẹnu abẹwo rẹ si UK pẹlu aarẹ Bola Ahmed Tinubu.

Malagi ni "Naijiria setan lati pese epo rọbi fun awujọ agbaye bi aifararọ se n waye lẹka eto ọrọ aje lagbaye tori ogun to wa laarin Israel, Iran ati Amẹrika.

Gbogbo ohunkohun ti orilẹede Naijiria ba le se lati mu ki alaafia pada jọba ni ẹka ipese epo lawujọ agbaye ni yoo se.

Bí gbogbo àgbáyé á nílò epo rọ̀bì, Nàíjíríà wà níbẹ̀ láti pèsè rẹ̀ fún wọn, a si ri daju pe awujọ agbaye ri epo ra si lati orilẹede Naijiria lasiko to ba pọn dandan lati se bẹẹ."

"Ka ma parọ, awọn osisẹ alaabo wa n gbiyanju, sisẹkara lọsan loru, lati dena ikọlu awọn ikọ afẹjẹwẹ"

Nigba to n dahun ibeere lori awọn isẹlẹ ọpọ ado oloro to bu laipẹ yii nilu Maiduguri ati eto aabo to mẹhẹ ni orilẹede Naijiria, minisita feto iroyin ni ijọba apapọ n kọbi ara si eto aabo to dẹnukọlẹ naa.

Malagi ni eto atunto tijọba Bola Tinubu n se, lo wa lati se agbelarugẹ eto aabo to peye, ti irufẹ awọn isẹlẹ isekupani yii yoo fi dinku.

Bakan naa lo ni ijọba ti n seto lati mu adinku bawọn ohun to le se okunfa kawọn eeyan maa huwa aidaa bi eleyi.

Lori ibeere lati mọ boya ẹka eto ọtẹlẹmuyẹ ni Naijiria ti kuna lo n sokunfa ẹka eto aabo to mẹhẹ, Minisita naa ni oun ko lero bẹẹ.

"Mo lero pe o yẹ ka tun tubọ sisẹ kara si ni lasiko yii, alaafia ti pada jọba nilu Maiduguri bayii nitori lasiko kan, nnkan ko fararọ.

Amọ o se ni laanu pe isẹlẹ yinyin ado oloro si papa waye amọ ka ma parọ, awọn osisẹ alaabo nilẹ wa n gbiyanju, sisẹkara lọsan loru lati dena ikọlu awọn ikọ afẹjẹwẹ naa."

Bi UK se ransẹ pe aarẹ Tinubu fun abẹwo safihan oju rere ti UK fi wo eto atunto tí aarẹ n se, yoo si mu ki ipo ti Naijiria duro si lawujọ agbaye tubọ ru gọgọ si"

Lori abẹwo aarẹ Bola Tinubu silẹ UK, Minisita feto iroyin ni abẹwo naa se pataki pupọ fun Naijiria.

O ni abẹwo naa lo se agbelarugẹ itan ajọsepọ asa ati ọrọ aje to wa laarin UK ati Naijiria.

"A si lero pe irufẹ ajọsepọ bayii yoo gbooro si nitori ifẹ awọn eeyan orilẹede mejeeji.

Ta ba si wo eto atunto ti aarẹ Bola Tinubu gun le, eyi ti mu agbega nla ba eto ọrọ orilẹede Naijiria.

Bi UK se ransẹ pe aarẹ Tinubu fun abẹwo yii safihan oju rere ti UK fi wo eto atunto naa.

Abẹwo ọhun si ni yoo tun mu ki ipo ti Naijiria duro si lawujọ agbaye tubọ ru gọgọ si."