Àṣìṣe ni ọ̀rọ̀ tí mo sọ lórí ètò ààbò Nàìjíríà, ẹ foríjìmí - Aremu Afolayan

Oríṣun àwòrán, Aremumimostwantedlikecrudeoil/Instagram
Gbajúmọ̀ òṣèré tíátà, Aremu Afolayan ti tọrọ àforíjì lọ́wọ́ àwọn Nàìjíríà lórí ọ̀rọ̀ tó sọ níbi ètò ìpolongo ìbò EKO57, èyí tí ọ̀pọ̀ àwọn òṣèré tíátà kópa níbi láìpẹ́ yìí.
EKO57 ṣé àkójọpọ̀ àwọn èèyàn tí wọ́n ń ṣe àtìlẹyìn fún àtúnyànsípò ààrẹ Nàìjíríà, Bola Ahmed Tinubu níbi ètò ìdìbò gbogbogbò ọdún 2027.
Ẹ ó rántí pé ní ọjọ́ Àìkú, ọjọ́ Kẹẹ̀dógún, oṣù Kẹta ni ọ̀pọ̀ àwọn òṣèré tíátà tó fi mọ́ Remi Surutu, Yomi Fash-Lanso, Adams Kehinde, tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Lege Miami àtàwọn míì kó ara wọn jọ láti bẹ̀rẹ̀ ìpolongo ìbò fún Tinubu.
Níbi ètò náà ni Afolayan ti sọ pé òun buwọ́lu ìyànsípò Tinubu lọ́dún 2027, tó sì sọ pé òun ń ṣe dáadáa àti pé àìrajaja ètò ọrọ̀ ajé táwọn èèyàn ń pariwo kò dé ọ̀dọ̀ òun rárá.
Bákan náà ló fi kun pé ọ̀pọ̀ àwọn ìròyìn tí wọ́n ń gbé kiri lóró ètò ààbò Nàìjíríà ni kò pọ̀ tó bí wọ́n ṣe ń gbe àti pé ọ̀pọ̀ rẹ̀ ló jẹ́ pé wọ́n máa ń fikún ju bó ṣe wáyé lọ.
Ó sọ pé "tí ẹ bá wo ìròyìn nípa ìgbéṣùmọ̀mí, ẹ má dáwọn lóhùn, àkọ́ọ́lẹ̀ lásán ni."
Ọ̀rọ̀ tó sọ yìí mú kí ọ̀pọ̀ èèyàn faraya lórí ayélujára, táwọn míì sì ń fẹ̀sùn kàn-án pé ó ti gbowó ló ṣe ń sọ bẹ́ẹ̀.
'Ẹ ṣìmí gbọ́ ni, ọ̀tọ̀ ni ohun tí mo sọ'
Ẹ̀wẹ̀, Aremu Afolayan ti wá tọrọ àforíjì lọ́wọ́ àwọn ọmọ Nàìjíríà lórí àwọn ọ̀rọ̀ tó sọ náà bí ó ṣe sọ pé àwọn èèyàn ṣi òun gbọ́ ni nítorí kìí ṣe ohun tí òun ń sọ gan-an ni wọ́n gbé jáde.
Ó ní láti ìgbà tí ìròyìn náà ti jáde ni àwọn èèyàn ti ń kàn sí òun, tí wọ́n ń fi èpè ránṣẹ́, táwọn míì sì ń pè òun láti jẹ́ kí òun mọ̀ pé ọ̀rọ̀ tí òun sọ náà kò bójúmu.
Ó tọrọ àforíjì lọ́wọ́ àwọn ọmọ Nàìjíríà, àwọn olólùfẹ́ rẹ̀, àwọn tí wọ́n ń fẹ́ àyípadà rere fún Nàìjíríà ààwọn ẹ̀yà míì tó wà ní orílẹ̀ èdè yìí.
"Ẹ foríjìí, èpè yìí pọ̀ o, mi ò ṣẹ ẹnikẹ́ni, ẹ ṣì mí gbọ́ ni.
"Ohun tí mò ń sọ ni pé tí èèyàn kan bá ń ka ìròyìn fún-un lórí amóhùnmáwòrán pé ètò ààbò dára, irọ́ ni wọ́n ń pa o.
"Onírúurú nǹkan ló ti ń lọ lórí ayélujára, àwọn nǹkan ń sọ pé mo gbowó láti lọ kópa níbi ètò náà ni, mi ò gbo wó o."
Afolayan fi kun pé níṣe ni ọkàn òun gbọgbẹ́ pẹ̀lú gbogbo nǹkan tó ń lọ lórí ayélujára nítorí òun mọ̀ pé òun ti ṣẹ ọ̀pọ̀ èèyàn pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ òun.
Wọ́n jí ìyá ọ̀rẹ́ mi gbé, ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù la fi gbà á kalẹ̀
Àgbà òṣèré náà tẹ̀síwájú pé ohun tí òun ń sọ níbi ìfilọ́lẹ̀ ètò náà ni pé àìsí ààbò tó péye ń bá Nàìjíríà fínra gidi tó sì jẹ́ pé ìjọba kò jára mọ́ bí wọ́n ṣe máa fòpin síi.
"Ohun tí mò ń gbìyànjú láti sọ nip é bí èèyàn kan bá ń pariwo pé wọ́n ń bọ̀ láti apá ibìkan, tí ẹnìkan wá ń ka ìròyìn lórí tẹlifíṣàn pé kí ẹ má dáhùn, pé kí ẹ fọkàn balẹ̀, ẹ má dá ẹni náà lóhùn nítorí ó ń ka ìwé lásán ni."
Ó ní wọ́n jí ìyá ọ̀rẹ́ òun gbé tí àwọn sì nílò láti san ọ̀pọ̀lọpọ̀ mílíọ̀nù kí àwọn tó rí ìyá náà gbà padà kúrò ní àkàtà àwọn ajínigbé ọ̀hún.
Ó fi kun pé òun kò le sọ pé ètò ààbò dára tó nígbà tí òun náà ń rí ohun tó ń ṣẹlẹ̀ láwùjọ.
Mi ò ṣe òṣèlú mọ́
Aremu Afolayan tún kéde pé òun kò ní kópa nínú òṣèlú mọ́ àti pé òun kò ní ṣe àtìlẹyìn fún olùdíje kankan níbi ètò ìdìbò gbogbogbò ọdún tó ń bọ̀.
Ó ní ohun tó mú òun kópa níbi ètò EKO57 tí Lege Miami pè òun sí kò ṣẹ̀yìn pé òun fẹ́ràn ètò nítorí ó jẹ́ kí ètò ìṣèjọba súnmọ́ aráàlú.
Ó sọ pé bí ó ṣe jẹ́ pé èèyàn le kàn sí àwọn alága ìjọba ìbílẹ̀ èèyàn lórí ètò ìṣèjọba wọn ló jẹ́ kí òun kópa níbẹ̀.
Ó wà sọ pe àmọ́ òun ti jáwọ́ nínú gbogbo ọ̀rọ̀ òṣèlú báyìí pàápàá nígbà tí àwọn olólùfẹ́ òun, tí wọ́n ń ṣe àtìlẹyìn fún iṣẹ́ àti okoòwò òun kò faramọ ohun tí òun ń ṣe.
"Mo ti jáwọ́ nínú gbogbo ohun tó bá jọ mọ́ ọ̀rọ̀ òṣèlú, mo ti dúró pẹ̀lú àwọn èèyàn mi báyìí."


























