Ọba Charles fi èdè Yorùbá kí Tinubu káàbọ̀ sí UK, sàpèjúwe ọmọ Nàíjíríà nílùú ọba bíi "Afárá Ẹlẹ́mìí" láàrin ilẹ̀ méjéèjì

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Se ni ilẹ UK sọkutu wọwọ ni ọjọru ana nigba ti Ọba Charles Kẹta seto ayẹyẹ igbalejo ati apejẹ fun aarẹ orilẹede Naijiria, Bola Tinubu ati aya rẹ, Oluremi.
Nibi ayẹyẹ igbalejo naa si ni Ọba Charles ti yonbo okun ajọsepọ to dan mọran to wa laarin ilẹ Naijiria ati UK.
Charles, ẹni to fi ede Yoruba ki awọn alejo bii ọgọjọ to peju sibi ayẹyẹ igbalejo naa, tun sọrọ nipa awọn ọmọ Naijiria to wa nilẹ UK.
O si sapejuwe wọn bii "afara ẹlẹmi" ninu ọrọ rẹ to ka ni gbọngan St George to wa ni aafin Windsor.

Oríṣun àwòrán, Reuters
Ninu ọrọ ti Ọba ilẹ Gẹẹsi sọ, o tẹnumọ pataki ifarada ẹsin, eyi to yẹ kawọn eeyan to jẹ oniruuru ẹsin yẹ ko se,.
O ni o yẹ ki wọn maa gbe pọ pẹlu ara wọn ni alaafia ni.
Ọba Charles kẹta tun sọ fun aarẹ Bola Tinubu ati aya rẹ, Oluremi, nipa pataki ajọsepọ to dan mọran gẹgẹ bo se wa laarin orilẹede bii Naijiria ati UK, ti wọn si maa n duro ti ara wọn lasiko isoro, "nigba ti kurukuru b abo oju ọjọ."
Ọba Charles wa se apejuwe orilẹede Naijiria bii "Ile agbara ọrọ aje" ibudo asa nla ati ohun ibasepọ to wu ni lori"
Bakan naa, oriade ọhun tun ni salaye okun ajọsepọ to yi laarin Naijiria ati UK lo mu "ki orin Afro gba inu gbọngan naa kan, ti ere sinima lati Naijiria si wa loju iworan"
Bakan naa ni Ọba Charles tun sọrọ lori ipa ti awọn iṣẹlẹ atijọ n ni, paapaa lori iwa imunisin.
O ni oun ko sọrọ lati gbagbe awọn nnkan to ti ṣẹlẹ sẹyin nitori ko si ọrọ kankan ti oun le sọ, to le da awọn iṣẹlẹ atijọ pada.
Sugbọn o ni oun gbero pe ajọṣepọ ọjọ iwaju maa dara debi pe o maa pa awọn aṣiṣe atẹyinwa rẹ.
Gbajumọ olorin takasufee, Tiwa Savage ati olootu ijọba ilẹ Gẹẹsi, Sir Keir Starmer, wa nibi ayẹyẹ igbalejo
Lara awọn eekan ilu to peju sibi ayẹyẹ igbalejo naa ni olori elere idaraya Rugby nilẹ Gẹẹsi, Maro Itoje, elere idaraya Olympic, Christine Ohuruogu ati gbajumọ akewi, ọlọla Ben Okri, pẹlu awọn agbaagba lati idile Ọba ilẹ Gẹẹsi.
Lara wọn ni Olori Camilla ati Ọmọọba pẹlu Ọmọọbabinrin tilẹ Wales.
Lara awọn alejo to wa nibẹ ni eekan agbabọọlu tẹlẹ ri, Eni Aluko, onimọ nipa oju ofurufu, Dame Maggie Aderin.
Gbajumọ olorin takasufee, Tiwa Savage ati olootu ijọba ilẹ Gẹẹsi, Sir Keir Starmer, naa ko gbẹyin nibẹ.
Ohun mimu kan to gbajumọ laarin awọn ọmọ Naijiria, ti wọn n pe ni Zobo, naa wa nikalẹ nibi apejẹ ọhun
Oniruuru ara ni wọn da si gbọngan igbalejo naa pẹlu awọn ododo alaranbara pẹlu awọn ounjẹ ti ko ni ẹran ninu ayafi ẹyin atawọn ounjẹ to kun fun eso ati ẹfọ.
Bakan naa ni wọn seto fawọn Musulumi to wa nibi apejẹ naa nitori asiko aawẹ Ramadan ta way ii.
Se ni wọn ya yara kan sọtọ fun adura gbigba ni aafin Windsor, ti wọn ko si seto ounjẹ ọsan to saba maa n waye ti ọba ba gbalejo bii iru eyi.
Bakan naa, o jẹ asa lati seto igbalejo ohun mimu ati ipanu lasiko igbalejo bii eyi, amọ lasiko yii, awọn ohun mimu ti kii se ọti lile ni wọn pese silẹ.
Koda, ohun mimu kan to gbajumọ laarin awọn ọmọ Naijiria, ti wọn n pe ni Zobo naa wa nikalẹ nibi apejẹ ọhun.
Amọ awọn ọti lile wa fawọn alejo ni gbọngan St George to fi mọ ọti waini alawọ pupa, funfun ati Wisiki.
Ni ọjọru ni eto gbigba alejo Tinubu ati iyawo rẹ bẹrẹ pẹlu awọn ohun ẹṣọ alaranbara ni aafin Winsdor Castle, ti wọn si gbalejo wọn pẹlu ọla.
Awọn olorin to jẹ ti ọmọ ogun ni wọn fi gbe wọn wọ aafin Windsor, wọn fi yinyin ibọn soke dawọn laraya.
Tinubu ati iyawo rẹ fun Ọba Charles ati Olori Camilla ni ere ilẹ Yoruba, apo ẹṣọ eyi ti wọn ya oju awọn obinrin pataki Naijiria si
Ọpọ awọn ẹbun ni wọn fura wọn. Wọn fun Tinubu ati iyawo rẹ ni ẹbun ikoko ti wọn fi ọwọ mọ, aworan Ọba Charles ati iyawo rẹ nla ati awo nla enamel.
Bẹẹ naa ni Tinubu ati iyawo rẹ fun Ọba Charles ati Olori Camilla ni ere ilẹ Yoruba, apo ẹṣọ eyi ti wọn ya oju awọn obinrin pataki Naijiria si.
Musulumi ni Tinubu nigba ti iyawo rẹ jẹ ẹlẹsin Kristẹni ti awọn mejeeji si kopa nibi eto isin to ko gbogbo ẹsin sinu ni Windsor Castle lojuna ati ri daju pe wọn ko yọ ẹnikẹni silẹ.
Asiko yii jẹ eyi to lagbara fun Naijiria pẹlu bi iṣẹlẹ ibugbamu ṣe waye ni ọsẹ yii ni ilu Maiduguri, ipinlẹ Borno nibi ti eeyan to le ni mẹtalelogu ti padanu ẹmi wọn nigba ti awọn 108 si farapa.
Igbagbọ wa pe awọn alakatakiti ẹsin Boko Haram lo ṣe ikọlu naa.
Igba akọkọ niyi ti Naijiria n ṣe abẹwo iṣẹ si UK lẹyin ọdun mẹtadinlogoji, ti irufẹ abẹwo bayii maa n mu ibaṣepọ laaarin orilẹ ede lekun, to si maa n ṣe atiwaye awọn anfani pupọ.
Abẹwo Naijiria si UK yii ni igbagbọ wa pe o maa pọnkun okoowo, ibaṣepọ ẹbi pẹlu bo ṣe jẹ pe awọn ọmọ bibi Naijiria to le ni 270,000 lo n gbe ni UK.
"Àbẹ̀wò Naijiria yii si UK lo ṣeeṣe ko tun sọ ibaṣepọ ojọ pipẹ di ibaṣepọ eto ọrọ aje igbalode, to le ṣi ọpọ anfaani," agbẹnusọ ijọba Naijiria, Mohammed Idris sọ.
"Awọn atunto eto ọrọ aje ti Naijiria n ṣe n ṣi ọpọ anfaani fun orilẹ ede to ni onibaara to pọ julọ nilẹ Africa. United Kingdom wa lara alabaaṣiṣẹpọ ninu ohun to n bọ."
























