Owó epo àti afẹ́fẹ́ gáàsì di gọbọi ní UK àti Europe lẹ́yìn ìkọlù sí ibùdó gáàsì ní Qatar

- Author, Rachel Clun
- Author, Osmond Chia
- Author, Emer Moreau
- Role, Business reporters
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4
Owo iye ti wọn n ta epo ati gaasi ti gbe owo lori si i lẹyin ikọlu tuntun si ẹka ipese epo ni aarin gbungbun agbaye, to fi mọ ẹka to n pese gaasi ni Qatar.
Ida mẹẹdọgbọn ni owo to gun owo afẹfẹ gaasi ni awọn ọja to wa ni ilẹ UK ati Yuroopu ni, ṣaaju ki irọrun diẹ to wọle.
Iye owo gaasi ni Yuroopu ju ilọpo meji ipele ti a rii ṣaaju ki ogun US-Israeli pẹlu Iran bẹrẹ.
Epo rọọbi naa gbe owo lori, pẹlu epo Brent n fo si ida 10% , tii owo jala epo si di $ 119.
Owo gaasi ni UK lọwọlọwọ wa ni iwọn 25% si ayika 175p fun jala kan.
Fifo soke naa wa lẹyin ti ileeṣẹ Gaasi South Pars ti Iran - ọkan ninu awọn aaye gaasi adayeba ti o tobi julọ ni agbaye – n jẹ ohun ikọlu ni irọlẹ Ọjọbọ.
Iran gbẹsan nipa kikọlu ile-iṣẹ okeere gaasi olomi nla kan ni Qatar, to fa ibajẹ nla, eyi to fa bi ọwọngogo ṣe gba gbogbo agbaye.

Oríṣun àwòrán, EPA
"Ida mẹẹdọgbọn ni owo epo ati gaasi fi le si ni UK"
Awọn iroyin tuntun ti jade sita pe awọn oludokoowo ti n se iyemeji lori ipa ti ogun yii yoo ni lori ẹka eto ọrọ-aje.
Ni ilu Japan, atọka ipin Nikkei lulẹ si 3.4%, ati ni Ilu Lọndọnu FTSE 100 lọ silẹ pẹlu ida 1.7% ni owurọ Ọjọbọ.
Matthieu Favas, olootu awọn ọja ni The Economist, sọ fun eto BBC pe owo nla lo gun owo iye ti wọn ta gaasi lori.
"Eyi ko si sẹyin ikọlu ti wọn se si ile-iṣẹ gaasi ni Qatar, eyi ti ko ṣiṣẹ lọwọ bayii.
Sugbọn ireti wa pe yoo tun bẹrẹ laarin ọsẹ, ṣugbọn ninu ikọlu tuntun bayi - ọpọlọpọ awọn ado oloro misaili ni o kọlu ile-iṣẹ yii, ọkan ninu wọn kọlu taara.
"Eyi le ṣe ko tẹsiwaju fun ọpọ oṣu atipe ileeṣẹ yii lo n pese gaasi ju lagbaye, eyi si ni idi ti ọja naa ṣe lọ soke lasiko yii.
Ikọ ologun Iran ti kilọ pe oun yoo ṣe "ipinnu" ni idahun si ado oloro to kọlu ileeṣẹ gaasi rẹ.
Awọn onimọ sọ pe, awọn igbiyanju awọn olori ilu kaakiri agbaye lati mu idẹrun de ba ipa ti afikun owo gaasi yii da silẹ, lo da bi pe ko ni ipa rara tabi ka ni pe o ni ipa diẹ lori araalu.
Ni bayii, Iran tun ti mu idaduro ba bi gaasi ṣe n lọ si Iraq lati igba ti oogun ti bẹrẹ, oṣiṣẹ agba Iraq kan sọ fun Reuters.



























