''Iran ju àdó olóró sí ibùdó ológun Amẹrika àti UK ní Diego Garcia, ṣùgbọ́n kò wọle''

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Iran tun ti ju ado oloro si ibudo ologun orilẹede Amẹrika ati UK to wa ni Diego Garcia.
Iwadii BBC fidi rẹ mulẹ pe ado oloro ti Iran ju ọhun ko wọle, ikọlu ọhun si waye ṣaaju ki UK to yonda Amẹrika lati lo ibudo ologun rẹ yin ado oloro si Iran.
Ṣaaju ninu oṣu Kẹta yii ni UK fun Amẹrika ni iyọnda lati lo ibudo ologun naa ati lati lo ibudo ọkọ ijagun ofurufu RAF to wa ni Gloucestershire nilẹ UK lati fi le ma a da ado oloro Iran to ba le ṣakoba fun UK pada.
Bakan naa lanaa ọjọ Ẹti ni UK gba ki Amẹrika maa lo ibudo ologun rẹ lati le maa dawọn ado oloro ti Iran n yin si agbegbe Strait of Hormuz ninu okun to gba Iran kọja pada.
Ẹwẹ, ileeṣẹ ọmogun UK ko fidi iroyin naa mulẹ, bẹẹ ni ko si sọ pe ikọlu ọhun ko waye ni Diego Garcia.
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọmogun UK kan sọ ninu atẹjade to fi sita pe ikọlu Iran jẹ idunkokomọni fun UK.
Ileeṣẹ ologun ni awọn ọmogun yoo tẹsiwaju lati maa daabo bawọn araalu.
''Bi Iran ṣe n ṣekọlu oniruuru kaakiri ẹkun Middle-East ti ko si jẹ kawọn eeyan maa gbe ọkọ oju omi kọja gba agbegbe Strait of Hormuz buru jai.''
Iroyin to tẹ BBC lọwọ fidi rẹ mulẹ pe ado oloro meji ni Iran ju si ibudo ologun Amerika ati UK to wa ni Diego Garcia, amọ, ko si eyi to ba ibudo ologun naa.
'Ọ̀nà mẹ́rin tí ogun Iran fi lè wá sópin'

Oríṣun àwòrán, Reuters/Getty images
Lai tiẹ gba ibi kankan sunmọ agbegbe Middle East ti ogun Iran yii ti n waye, ko sẹni ti ko mọ ọn lara lọna kan tabi ikeji bayii kaakiri agbaye.
Ọwọngogo epo rọbi, gaasi ati tawọn nnkan elo gbogbo lo ti kari aye, to si n jẹ ki kaluku maa sọ pe igba wo gan-an ni ogun ti ko kan awọn lọwọ lẹsẹ yii yoo pari gan-an.
Ogun to ti le lọsẹ mẹta naa ni awọn kan tilẹ ti n ri bii ohun ti ko ṣetan to fẹẹ pari, bi ogun ọhun si ṣe n ko ba ọrọ aje naa lo n sọ ọpọ ẹmi nu lawọn ibi to ti n waye.
Ọwọja Iran naa ko kere lawọn ibi to n de, paapaa bi wọn ṣe n kọlu ẹka agbara ati awon aaye America to wa ni awọn ilu naa.
Ki ni yoo wa mu ogun ti gbogbo aye n mọ lara ti wọn si n sọ pe ko tete pari yii kasẹ nilẹ ti alaafia yoo si jọba?
Ẹka iroyin New York Times ka ọna mẹrin ti wọn gbagbọ pe o le mu ogun ọhun pari :
Ṣiṣe ayipada ijọba Iran
Igbesẹ akọkọ ti New York Times sọ pe o le mu ogun Iran pari ni ṣiṣe ayipada ijọba nilẹ Iran.
Ṣaaju ni America ti pa Ayatollah Ali Khamenei to jẹ olori wọn tẹlẹ sinu ija, pẹlu awon eekan ninu ijọba Iran.
Ọjọ diẹ lẹyin iku Ayatollah ni Iran si tun fi ọmọ rẹ, Mojtaba Khamenei, jẹ olori orilẹede naa mi-in ni ibamu pẹlu ẹsin Islam.
Eyi to fi han pe ko si kinni kan ti yoo yipada kuro bo ṣe wa tẹlẹ ninu iṣejọba wọn.
Ṣugbọn bi ifẹhonuhan agbayanu ba le waye lati ọwọ araalu, ti awọn ologun ati ọlọpaa si ti wọn lẹyin lati tako iṣejọba iru tawọn Khamenei, kia ni ogun Iran yii yoo wa sopin bi New York Times ṣe woye.
Wọn ni ifẹhonuhan naa yoo ri atilẹyin America ati Israel lati gbajọba naa.
Yiyi ilana iṣejọba Iran pada ni ibamu pẹlu ti America ati Israel
Ọna keji ti New York Times la kalẹ ni ṣiṣe ayipada ilana iṣejọba Iran, si eyi ti yoo tẹle ohun ti America ati Israel n fẹ.
Ṣugbọn eyi ṣoro pupọ lati ṣe, nitori yoo ṣoro fun ijọba Iran lati ṣe ohun ti America ati Israel n fẹ lasiko yii, paapaa bi wọn ṣe ṣẹṣẹ yan olori tuntun.
Yoo tun ṣoro lati mọ boya olori ẹsin tuntun ti wọn ṣẹṣẹ yan yii yoo ṣetan lati tẹle ilana nini nnkan ija, tẹsiwaju lati ṣe nnkan ogun lọwọ ara wọn, ati pipada lẹyin ikọ Hezbolla.
Ṣiṣe adayanri aṣeyọri ilu kọọkan
Iwoye New York Times ni pe Aarẹ Trump ti ilẹ America ati Olootu ijọba ilẹ Israeli; Benjamin Netanyahu, ko ti i ri ohun ti wọn tori rẹ bẹrẹ ogun yii.
Wọn ni loootọ ni wọn ri olori ẹsin to n dari Iran pa, eto ati bi Iran ṣe n ṣe gbogbo nnkan rẹ ko yipada.
"O ṣoro lati ro o pe ogun yii yoo pari bi America ati Israel ba tun kọlu awon ibudo nnkan ogun Iran miran."
New York Times to kede bẹẹ sọ pe ai ti i le tọka si aṣeyọri ti awọn to bẹrẹ ija yii ti ṣe nikọọkan, jẹ iṣoro kan ti ko ti I jẹ ki ogun yii wa sopin.
Gbigba akoso erekuṣu Kharg
Ọna ti wọn la kalẹ ṣikẹrin ni pe ki America gba erekuṣu Kharg ni Iran.
Erekuṣu yii ni ida aadọrun (90 percent) epo Iran n gba kọja lọ si ọja agbaye.
Bi wọn ba le ja a gba, yoo ge ọna ti owo epo n gba wọle fun Iran, bi New York Times ṣe woye.
Wọn ni eyi yoo mu ijọba Iran wo lulẹ debi ti ko ni I le ṣakoso mọ, ko si ni I le ti awọn ologun rẹ lẹyin.
Bakan naa ni Iran ko ni I le sanwo oṣu awọn oṣiṣẹ mọ bi wọn ṣe wi, eyi ti yoo mu ki iṣẹ su awon ologun ti wọn yoo si sinmi.
Lọsẹ to kọja ni America kede pe oun kọlu aaye awọn ologun Iran.
Ṣugbọn o loun ko fọwọ kan ibi ti epo wa, ki Iran le ronu piwada lori ọna epo Strait of Hormuz ti wọn ti pa.
Aarẹ Trump ninu ọrọ rẹ sọ pe bi Iran ba tẹsiwaju lati maa ti oju opo Strait of Hormuz pa, America le kọlu aaye epo ilu naa.


























