Wá wí tẹnu rẹ o! Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ránṣẹ́ pe DPO àgọ́ ọlọ́pàá táráàlú ní afurasí ajínigbé tí sálọ

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Bi wọn ba fi eeyan jẹ oye awodi, o yẹ ki tọhun le gbe adiẹ. Eyi ni Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Oyo,Femi Haruna, ṣe paṣẹ ki wọn fi Inspẹkitọ ọlọpaa kan si ahamọ lori ẹsun ti tu afurasi ajinigbe ti araalu mu wa si teṣan silẹ lai gba aṣẹ kankan.
Yatọ si ọga ọlọpaa ti wọn fi si ahamọ naa, DPO ẹkun naa ati ASP gba iwe ẹsun lati ṣalaye ara wọn lori iṣẹlẹ ọhun pẹlu.
Ijọba ibilẹ Afijio, nipinlẹ Oyo, ni iṣẹlẹ yii ti waye.
Kí ló ṣẹlẹ̀ gan-an?
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, ijinigbe ti di gbogbo igba ni ijọba ibilẹ Afijio, paapaa, agbegbe Jobele. O kere tan, meje iru rẹ lo ti waye laipẹ yii.
Gẹgẹ bi ẹnikan torukọ rẹ n jẹ Dolapo Awotunde, ti Wọọdu kẹjọ ṣe ṣalaye ninu atẹjade rẹ, ijinigbe meje lo waye laipẹ yii ni Afijio.
O fi kun un pe awọn ajinigbe ti da oju sọ agbegbe naa, wọn si tun kọlu awọn eeyan lalẹ ọjọ Satide to kọja mọju ọjọ Aiku ti i ṣe Sannde ọsẹ yii.
Lasiko ikọlu naa gẹgẹ bo ṣe wi ni wọn fẹẹ ji obinrin kan gbe, bo si tilẹ jẹ pe o dọgbọn sa mọ wọn lọwọ, sibẹ, wọn ṣa a ni ada lọwọ, eyi to jinlẹ gan-an.
Koda, ẹnikan tun wa ti wọn ṣe leṣe pupọ bi Awotunde ṣe ṣalaye.
Ileewosan apapọ ti wọn sare gbe e lọ lo dari rẹ si omiran niluu Ogbomoso, nibi ti wọn ti pada ge ọwọ ẹni naa latari bo ṣe farapa to.
Eyi lo ni o mu awon olugbe agbegbe naa gbiyanju lati gbeja ara wọn lọjọ Aje ọsẹ yii, nipa ṣiṣẹ ọdẹ oru lai sun mọju.
Lasiko tawọn araalu n ṣọde naa ni wọn kẹẹfin afurasi kan ti wọn ni wọn ba ibọn, ada ati awọn nnkan oloro mi-in lọwọ rẹ, ni nnkan bii aago kan oru.
Gẹgẹ bii araalu to n tẹle ofin, awọn araalu fa afurasi naa le wọn lọwọ ni teṣan ọlọpaa Jobele, fun iwadii kikun ati ijẹjọ.
"Ọlọpaa tu afurasi naa silẹ lai sọ fawọn to mu un wa"
Ṣugbọn ọrọ yii pada nigba ti awọn araalu de teṣan ọlọpaa naa lọwọ aarọ ọjọ keji, ti awọn ọlọpaa si fi ye wọn pe awọn ti yọnda afurasi ajinigbe ti wọn mu wa.
"Nigba tawọn araalu de teṣan ọlọpaa laarọ lati beere nipa afurasi naa, wọn ri i pe awọn ọlọpaa to fi I silẹ lai si alaye kankan, bẹẹ ni wọn ko sọ fun awọn to mu un wa ki wọn too fi I silẹ.
"Eyi lo di ariwo gidi ti araalu fi patẹ ẹhonu lọjọ Iṣẹgun."
Bẹẹ ni atẹjade Awotunde naa wi.
Tẹ o ba gbagbe, awọn eeyan Afijio titi kan awọn akẹkọọ lo gbegi dina lasiko ifẹhonuhan naa, ti wọn di oju ọna Oyo atijo si Oyo–Ibadan pa, ati ọna Ibadan- Oyo-Ogbomoso.
Wọn ni awọn fẹẹ mọ ohun to ṣẹlẹ ti wọn fi tu afurasi naa silẹ, ati ẹni to paṣẹ itusilẹ rẹ gan-an.
Iṣẹlẹ yii lo mu Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Oyo, Femi Haruna, paṣẹ pe ki DPO ẹkun naa, pẹlu Assistant Superintendent of Police waa ṣalaye ara wọn.
Bakan naa lo paṣẹ pe ki wọn fi Inspẹkitọ tọrọ naa kan si ahamọ na bi iwadii ṣe n lọ lọwọ.

























