Gbálé-n-gbáta olóṣooṣù yóò bẹ̀rẹ̀ padà l'Eko lóṣù Kẹ́rin ọdún 2026 – Ìjọba Eko

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Gbale-n-gbata to maa n waye loṣooṣu nipinlẹ Eko tẹlẹ ni eto ti pari lori rẹ lati bẹrẹ pada bayii, ti yoo si gbera sọ loṣu Kẹrin ọdun 2026 yii.
Gẹgẹ bi Amofin Tokunbo Wahab; Kọmiṣanna fun eto ayika ati omi nipinlẹ Eko ṣe kede loni ọjọ Satide, o ni ọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu Kẹrin ọdun 2026 yii ni atunṣe ayika ti ọpọ eeyan maa n pe ni 'Ẹnfaromẹnta' naa yoo bẹrẹ pada kaakiri Eko.
Kọmiṣanna naa fi kun un pe, aago mẹfa aabọ idaji si aago mẹjọ aabọ aarọ ni eto gbale-n-gbata oloṣooṣu naa yoo maa waye, ati pe Satide to ba kẹyin oṣu ni yoo maa waye pẹlu.
Lasiko ti imọtoto ayika naa ba n lọ lọwọ, ijọba rọ awọn olugbe ipinlẹ Eko lati tun ayika wọn ṣe.
Wọn ni ki wọn ko awọn koto idaminu to ba wa niwaju ile wọn, ki wọn si da idọti ti wọn ba ko jọ nu lọna to ba ofin mu.
Bakan naa ni Kọmiṣanna to gba ẹnu ijọba Eko kede naa sọ pe ajọṣe gbogbo eeyan to ba jẹ ọmọluabi Eko leyi, lati ni Eko alaafia ti omiyale yoo jinna si.
Bi ẹnikẹni ba fẹ tapa si ofin imọtoto yii, ijọba ipinlẹ Eko ni awọn ti wa nilẹ biba lati jẹwọ ijọba fun un.
Tẹ o ba gbagbe, aago meje aarọ si mẹwaa ni eto gbale-n-gbata oloṣooṣu yii maa n waye tẹlẹ nipinlẹ Eko, ni gbogbo ọjọ Satide to ba kẹyin oṣu.
Ṣugbọn wọn wọgile e loṣu Kọkanla ọdun 2016, lori ẹsun pe o n di lilọ bibọ lọwọ.
Ọdun kẹwaa lẹyin rẹ si ni eto naa tun de pada yii.

























